Wo ìlànà tuntun tí ìjọba là kalẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ jàǹfàní ètò ẹ̀yáwó-kẹ́kọ̀ọ́ fún 2025/2026

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu
Ajọ to n ri si eto ẹyawo awọn akẹkọọ ni Naijiria, NELFUND, ti ṣi oju opo ti awọn akẹkọọ ti le ya owo fun saa ekọ ọdun 2025/2026.
Ninu atẹjade kan loju opo ajọ naa, o ni bẹrẹ lati Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 yii titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2026 ni oju opo naa yoo wa ni ṣiṣi.
NELFUND sọ fun awọn akẹkọọ lati fi nọmba igbaniwọle wọn sile ẹkọ tabi nọmba iforukọsilẹ JAMB wọn lati fi orukọ silẹ loju opo rẹ.

Oríṣun àwòrán, NELFUND
O tun rọ awọn ile ẹkọ giga ki wọn fun awọn akẹkọọ to ba fẹ ya owo lanfani gbọọrọ titi ti owo naa yoo fi tẹ wọn lọwọ.
NELFUND ni "Awọn ile ẹkọ ti ko ba tii bẹrẹ eto igbaniwọle wọn f'ọdun 2025/2026 gbọdọ kọ lẹta si NELFUND pẹlu alakalẹ eto wọn fun saa ẹkọ naa ki ohun gbogbo le lọ bo ṣe yẹ."
Ajọ ọhun rọ awọn ile ẹkọ lati fi akọsilẹ nipa gbogbo awọn akẹkọọ wọn – awọn to ti wa nilẹ ẹkọ tẹlẹ atawọn ti wọn ṣẹṣẹ fẹ wọle - ṣọwọ si oun fun anfani gbogbo awọn ti anfani eto naa tọ si.
Ninu atẹjade ọhun, ti agbẹnusọ rẹ, Oseyemi Oluwatuyi fi lede, ajọ naa dupẹ lọwọ awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria fun atilẹyin wọn lati akoko ti eto ẹyawo awọn akẹkọọ naa ti bẹrẹ, o si fi akoko naa bere ifọwọsowọpọ wọn siwaji si.
Ajọ wo ni NELFUND?
Ajọ NELFUND jẹ ajọ ti ijọba Bola Ahmed Tinubu gbe kalẹ lati maa ya awọn ọmọ ile ẹkọ giga ni Naijiria lowo lọna ati san owo ẹkọ wọn.
Labẹ eto naa, awọn akẹkọọ yoo san owo ti wọn ba ya lọwọ ijọba pada amọ wọn ko ni san ele kankan lori rẹ.
Afojusun ajọ naa ni lati ri pe gbogbo araalu lanfani lati kawe nile ẹkọ giga ni Naijiri lai si idiwọ fun wọn latari airi owo san.
Lọ soju opo NELFUND ni https://nelf.gov.ng lati forukọsilẹ fun eto ẹyawo akẹkọọ tirẹ.
Amọ ṣa, ri daju pe o ka awọn nnkan to yẹ ki o mọ loju opo naa nipa eto ẹyawo ọhun ki o to dawọle.















