'Ilẹ̀ Owo ti di ibi àìgbọdọ̀ wọ̀ fún Alága káńsù tó tàbùkù Ọlọ́wọ̀', ìgbìmọ̀ Ọlọ́wọ̀ fárígá

Olowo Ajibade Gbadegesin ati Onarebu Tope Omolayo, alaga ti won ni ko lọ rọọkun nile

Oríṣun àwòrán, Olowo Gbadegesin Ogunoye/ Tope Omolayo/Facebook

Àkọlé àwòrán, Olowo Ajibade Gbadegesin ati Onarebu Tope Omolayo, alaga ti won ni ko lọ rọọkun nile
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Alaga ijọba ibilẹ Owo, nipinlẹ Ondo, Ọnarebu Tope Omolayo, ni ipo naa ti bọ lọwọ rẹ bayii, wọn ni ko maa rele na.

Igbimọ Olowo, fun Kabiyesi Oba (Dr.) Ajibade Gbadegesin Ogunoye III, Olowo tilu Owo, kede eyi nibi ipade oniroyin to waye lọjọ Ẹti, ọjọ keje, oṣu Kọkanla ọdun 2025.

Yatọ si pe wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Alaga tẹlẹ naa, igbimọ ti a mọ si Olowo-In-Council tun sọ pe awọn eeyan ilu Owo paapaa ko fẹ ri Omolayo nipo alaga mọ.

Igbimọ naa fi kun un pe awọn alaga ijọba ibilẹ onidagbasoke ilu Owo paapaa koro oju si Omolayo.

Wọn ni wọn si ti takete si i pẹlu iwa abuku to hu si ori ade ati apeere ilu Owo to ti wa lati ọdun gbọọrọ pẹlu agbara.

Igbimọ ẹka to n ri si ofin, nijọba ibilẹ Owo ni a gbọ pe o da alaga tẹlẹ naa duro, fun iwa aitọ ati titabuku ipo iṣẹmbaye.

Ọrọ abuku wo ni Omolayo sọ si Olowo?

Gẹgẹ bi iroyin ṣe wi, ọrọ ori foonu kan ni a gbọ pe Ọnarebu Tope Omolayo sọ pẹlu ibinu, si Olowo tilu Owo, Oba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta.

Ohun ẹnu alaga tẹlẹ naa ti wọn ka silẹ lo si di ohun to pada di wahala si i lọrun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Asiko ti alaga naa n sọrọ pẹlu obinrin kan ni wọn ka ohun rẹ silẹ.

Ninu ohun naa ti wọn ka silẹ ti BBC Yoruba gbọ, ni Omolayo ti n sọrọ ipade kan ti Olowo pe oun atawọn mi-ni si, amọ to ni oun ko ni I lọ.

Bo tilẹ jẹ pe Omolayo kọ lati fidi rẹ mulẹ pe oun lo n sọrọ ninu ohun naa ti wọn ka silẹ naa, lara awọn nnkan to sọ nibẹ ni pe wọn ko bun oun gbọ ki wọn to pe ipade ọhun, ati pe oun ti lọ siluu Akure lati lọ fi ẹjọ Kabiesi sun.

O sọ pe ana ni oun ati kabiesi jẹ si ara, amọ o ṣeni laanu pe Olowo maa n ri oun fin ni gbogbo igba, eyi ti oun ko ni tẹwọgba mọ.

O ni "Wọn pe ipade lai kọkọ bun mi gbọ gẹgẹ bii alaga… mo ti lọ si Akure lana lati lọ fi ẹjọ rẹ sun.

"Arifin yii ti to, to ba ri mi fin emi naa yoo ri fin to bẹẹ ti ẹru maa ba a… o to gẹẹ.

"Mo ti sọ fun awọn eeyan ki wọn lọ kilọ fun un, ki i ṣe igba akọkọ ti yoo ṣe bẹẹ ree, o ti ṣe bẹẹ ni igba kinni, igba keji, igba kẹta…."

Alaga naa ni o dabii pe ori ade naa fẹ gbẹsan lara oun nitori oun maa n fi ẹgba na Kabiesi lasiko ti awọn mejeji wa nile ẹkọ.

Ọrọ naa lo tan kalẹ to si di ohun ti ọpọ eeyan ka si tita abuku ori ade ati ipo ọba ilu Owo.

Bakan naa ni awọn miran sọ pe abuku to kan ọba ki i ṣe fun Kabiyesi naa nikan, bi ko ṣe pe gbogbo ilẹ Yoruba ati awọn eeyan ibẹ lo kan.

Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye III, ni olori ọba ilẹ Owo, oun naa si tun ni Alaga igbimọ awọn ọba nipinlẹ Ondo.

Bi ọrọ to di ariwo, aafin Olowo ko kọkọ sọ nnkan kan.

Bo tilẹ jẹ pe a gbọ pe Omolayo ti tọrọ aforiji lori ọrọ naa loju gbogbo eeyan nibi eto kan niluu Akure, aforiji to beere fun naa ko da nnkan kan.

Ìgbìmọ́ Olowo gbé ìgbésẹ̀

Ọjọ Ẹti ana ti i ṣe ọjọ keje, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni ipade awọn oniroyin waye ni Aafin Olowo tilu Owo, Oba Ajibade Gbadesin.

Nibi ipade naa ni Ogwadogbon ti ilu Owo, Agba oye , Ọmọwe Ademola Obanonyen, ti ka a si etigbọ awọn akọroyin pe:

"Igbimọ yii fi gbogbo ara kọ abuku ita gbangba ti ẹni to huwa eewọ yii hu si Kabiyesi.

"Lẹyin ijiroro kikun, igbimọ Olowo fi ohun kan sọrọ, lati fi ọ̀wọ̀ to yẹ fun itẹ Olowo, a si fẹnuko pe:

"Ẹni to sọ ọrọ abuku yii ti sọ ara rẹ di ẹni ti a ko fẹ niluu Owo.

"A fẹnuko pe awọn eeyan Owo ati awọn Olori ilu owo ko fẹ ẹ nipo Alaga ijọba ibilẹ Owo mọ.

"Pe iwa rẹ tako igbekẹle ti a ni ninu rẹ.

"Pe ki igbimọ Olowo ati ijọba ipinlẹ Ondo gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ, fun alaafia ilu."

Igbimọ naa wa rọ awọn ọmọ Owo lọkunrin-lobinrin, nile ati lẹyin odi, lati ma ṣe fa wahala tabi ṣe idojukọ kankan to le di rogbodiyan.

Wọn fi kun un pe awọn fẹ ki awọn eeyan to di ipo agbara mu lọ mọ, pe awọn ọba ki i ṣe ẹni yẹpẹrẹ, ati pe ori itẹ ki i ṣe ohun abuku fun ẹnikẹni.

"Olowo ilu Owo, gẹgẹ bi awọn ọba yoku nilẹẹ Yoruba, jẹ aṣoju awọn alalẹ ati iṣẹmbaye awọn eeyan wa. Bi eeyan ba fi abuku kan Olowo, bi ẹni fi abuku kan gbogbo ilana iṣẹmabaye Yoruba ni.

Wọn fi kun un pe ko si awujọ ti yoo la bo ṣe tọ, nigba ti awọn to duro fun ba n ti oju rẹ di atẹmẹrẹ.

Kí ló fa gbas-gbos láàárín Olowo ìlu Owo àti alága káńsù tí alága fi ń fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Kábíyèsí?

Olowo ilu Owo, Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta. ati alaga ijọba ibilẹ ilu Owo Tope Omolayo, ti a\wonmejeji wọ aṣọ funfun ati fila

Oríṣun àwòrán, Olowo ilu Owo/Tope Omolayo

Ọpọ ọmọ ilu Owo, ni ipinlẹ Ondo lo ti n bu ẹnu atẹ lu alaga ijọba ibilẹ naa, Alagba Omolayo Tope Moses lori ẹsun pe o sọrọ abuku si Olowo, Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, asiko ti alaga naa n ba ẹnikan sọrọ lori ẹrọ ilewọ lo kabuku Kabiesi, eyii ti ko dun mọ awọn ọmọ ilu naa ninu.

Asiko gbọnmisi-omi-o-to yii naa ni awọn kan lara awọn kanṣelọ ijọba ibilẹ ọhun fi ibo wọn da alaga naa duro amọ Omolayo ti sọ pe iṣẹ ara wọn ni wọn n jẹ.

Bi gbas-gbos naa ṣe bẹrẹ

Tope Omolayo pẹlu awọn oṣiṣẹ NULGE lasiko iwọde wọn

Oríṣun àwòrán, Tope Omolayo

Ọjọ karindunlogun, oṣu Kẹwaa ti a wa yii ni iroyin mi igboro titi pe awọn kanṣelọ meje kan ti da alaga naa duro.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Omolayo ni pe o n na owo ijọba ibilẹ naa ni inakuna ati pe o ri awọn ọba alade ijọba ọhun fin, to fi mọ awọn ẹsun mii.

Iroyin ni nnkan bii aago mẹsan an aarọn ọjọ naa ni ọkan lara awọn kansẹlọ ọhun, Adedoyin Adeyefa, ko awọn mẹfa mii sọdi lati fi ibo da Omolayo duro gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ Owo lori awọn ẹsun naa.

Lẹyin igbesẹ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ọhun, NULGE, bẹrẹ ifẹhonuhan lati sọ pe awọn ko faramọ igbeṣe awọn kansẹlọ naa.

Awọn olufẹhonuhan ọhun sọ pe ohun ti awọn kansẹlọ naa ṣe ko tẹ awọn lọrun, bẹẹ ni ọna ti wọn gba lati yọ Omolayo lori oye ko ba ofin mu.

Ọrọ abuku wo ni Omolayo sọ si Olowo?

Asiko ti alaga naa n sọrọ pẹlu obinrin kan ni wọn ka ohun rẹ silẹ.

Ninu ohun naa ti wọn ka silẹ ti BBC Yoruba gbọ ni Omolayo ti n sọrọ ipade kan ti Olowo pe oun atawọn mii si amọ to ni oun ko ni lọ.

Bo tilẹ jẹ pe Omolayo kọ lati fidi rẹ mulẹ pe oun lo n sọrọ ninu ohun naa ti wọn ka silẹ, lara awọn nnkan to sọ nibẹ ni pe wọn ko bun oun gbọ ki wọn to pe ipade ọhun ati pe oun ti lọ siluu Akure lati lọ fi ẹjọ Kabiesi sun.

O sọ pe ana ni oun ati kabiesi jẹ si ara amọ o ṣeni laanu pe Olowo maa n ri oun fin ni gbogbo igba, eyii ti oun ko ni tẹwọgba mọ.

Tope Omolayo ati Olowo lasiko ere idaraya kan niluu Owo

Oríṣun àwòrán, Tope Omolayo

O ni "Wọn pe ipade lai kọkọ bun mi gbọgbọ gẹgẹ bii alaga… mo ti lọ si Akure lana lati lọ fi ẹjọ rẹ sun.

"Arifin yii ti to, to ba ri mi fin emi naa yoo ri fin to bẹ ti ẹru maa ba a… o to gẹ.

"Mo ti sọ fun awọn eeyan ki wọn lọ kilọ fun, kii ṣe igba akọkọ ti yoo ṣe bẹẹ ree, o ti ṣe bẹẹ ni igba kinni, igba keji, igba kẹta…."

Alaga naa ni o dabii pe ori ade naa fẹ gbẹsan lara oun nitori oun maa n fi ẹgba na Kabiesi lasiko ti awọn mejeji wa nile ẹkọ.

Ẹwẹ, awọn kan tun n sọ ni igboro pe ọrọ arifin naa jẹyọ latari pe Olowo n bere miliọnu kan naira lọwọ alaga Tope Omolayo loṣoṣu.

Ki ni aafin Olowo n sọ?

Olowo ilu Owo Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta lasiko ọdun Igogo pẹlu awọn oloye rẹ

Oríṣun àwòrán, Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta.

Titi di asiko ti n ko iroyin yii jọ, aafin Olowo ko tii sọ nnkankan lori ọrọ naa.

Amọ nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ Olowo, iyẹn ọgbẹni Samuel Adewale, o fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ti gbọ nipa ọrọ ti Omolayo sọ si Olowo amọ alaafia ilu Owo ni Olowo n fẹ, kii ṣe idarudapọ.

Adewale ni "Lojiji ni a ṣadede gbọ ọrọ to sọ amọ a ko mọ eredi to fi sọrọ naa.

"Irọ ni ohun ti awọn kan n sọ pe Olowo n bere miliọnu kan naira lọwọ rẹ, ṣe Olowo wa jẹ oloṣelu ti a maa bere owo lọwọ ẹnikẹni? Ohun ti ijọba n fun Olowo ti tẹ lọrun.

"Olowo kawe, o si mọ ofin, orukọ rẹ ko si ninu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nitori naa ko le maa bere owo lọwọ alaga ijọba ibilẹ."

Adewala fidi rẹ mulẹ pe alaga ọhun ko tii yọju si aafin Olowo, yala lati tuba tabi lati sọ pe ọrọ naa ko ri bẹẹ titi di asiko to n ba wa sọrọ.

Ki ni Omolayo sọ?

Tope Omolayọ wọ aṣọ Yoruba pẹlu fila

Oríṣun àwòrán, Topẹ Ọmọlayọ/facebook

Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati kan si Omolayo lori ọrọ naa lo ja si pabo latari bo ṣe kọ lati fesi si gbogbo atẹjiṣẹ wa.

Amọ ninu atẹjade to fi lede loju opo Facebook rẹ, o ni iṣẹ ti ko ba ofin mu lawọn kanṣelọ to da oun duro ṣe latari pe wọn ko gbe gba ọna to yẹ.

O tun fẹsun kan awọn kanṣẹlọ to n fẹ ko kuro lori oye pe wọn n fẹ ki oun fun wọn ni owo ti iye rẹ to miliọnu mejila naira amọ ti oun kọ jalẹ lo jẹ ki wọn ditẹ mọ oun.

Ni bayii, alaga naa ti pada si ọọfisi rẹ ninu ọgba ijọba ibilẹ ọhun.

Amọ ṣa, ninu gbogbo ọrọ to sọ, ko mẹnuba ọrọ ti wọn ni o sọ nipa Olowo.