Kí ló dé tí ẹnu ń kun Obasa olórí ilé aṣòfin Eko lórí ọmọ rẹ̀, Abdul-Ganiyu tó di Alága ìjọba ìbílẹ̀ Agege

Aworan Abdul Ganiyu Vinod Obasa

Oríṣun àwòrán, Linkedin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alaga ijọba ibilẹ Agege, Hon Tunde Azeez, ẹni ti ọpọ mọ si Disco, ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ alaga ijọba ibilẹ naa, nitori kudiẹkudiẹ ilera rẹ ti ko gba laye lati ṣe iṣẹ rẹ daada, ti wọn si ti kede Abdul Ganiyu Vinod Obasa gẹgẹ bii alaga tuntun.

Ninu lẹta to kọ si ile igbimọ aṣofin ijọba ibilẹ Agege, Azeez ṣalaye pe ipo ti ilera ara rẹ wa bayii n mu kudiẹkudiẹ ba iṣẹ rẹ, ti ko si le siṣẹ daada ni ilana to fẹ.

Lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ijọba ibilẹ Agege tẹwọgba ikọwefipo silẹ Azeez, igbimọ naa yan Hon AbdulGaniyu Vinod Obasa gẹgẹ bii ẹni ti yoo rọpọ Azeez gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ naa.

Igbesẹ naa, gẹgẹ bii ile igbimọ aṣofin ṣe ṣalaye yoo faye gba itẹsiwaju ijọba ati idari.

"Loootọ ni Disco ti kọwe fipo silẹ. Ẹ mọ pe o ṣe aisan fun igba pipẹ, Fun ọpọ oṣu ni ko ti wa si ile iwosan, ko to di pe o kọwe fipo silẹ. Awọn amofin ti n se ipade lẹyin to kọwe fiposilẹ.

"Vinod Obasa ti bọ ipo alaga bayii."

Ninu ọrọ itẹwọgba rẹ, Abdul Ganiyu Obasa se ileri lati mu itẹsiwaju ba iṣejọba ijọba ibilẹ Agege ati ipinlẹ Eko ni apapọ.

Oṣu keje ọdun yii ni eto ijọba waye nipinlẹ Eko, ti Disco si bori eto idibo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress pẹlu apapọ ibo 32,503.

O le ni milọnu meje oludibo to forukọsilẹ kaakiri ipinlẹ Eko lati le ni anfani lati yan awọn alaga ijọba ibilẹ ogun ati ijọba ibilẹ LCDA mẹtadinlogoji, to fi mọ awọn kanṣelọ.

Ta ni Vinod Obasa?

Abdul Ganiyu Vinod Obasa jẹ onimọ nipa eto isuna, oniṣẹ ọwọ ati ojulowo ọmọ ilu Agege.

O jẹ ọmọ bibi olori ile igbimọ aṣofin ile Eko, Rt Hon Mudashiru Obasa.

O bẹrẹ iṣẹ pẹlu ileeṣẹ Price Waterhouse Coopers (PWC) ni ọdun 2017, ko to di pe o gbera lọ sile ile ifowopamọ Providus Bank ni ọdun 2022, ko to kuro lati da iṣẹ ara rẹ silẹ.