Mi ò ní ìbọn o! 'Banger' ló kéré jù mi ò lè yìn, Mo f'ẹnu gb'ara mi kalẹ̀ ni - Ero Arike tó halẹ̀ ìbọn mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ PDP lọ́ṣun ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Falilat Yusuf Arike
Arabinrin Falilat Yusuf, ẹni ti ọpọ mọ si Ero Arike, ti yi ohun pada lori ọrọ to sọ lati fi dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Osun pe oun ni ibọn ni, ti oun si ṣetan lati yin fun ẹnikẹni to ba ta felefele de ayika oun.
Ọrọ Erọ Arike yii lo da ọpọ rogbodiyan silẹ nipinlẹ Osun, ti ọpọ eeyan si ti beere ọpọ ibeere lori boya ṣe loootọ ni Ero Arike ni ibọn ile to n fi dunkoko.
Ero Arike ninu ọrọ to gbe sita loju opo Facebook ni oun fi ẹnu gba ara oun silẹ lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun nitori awọn ti kọlu oun ati iya oun ṣaaju.
"Ọrọ ko ri bẹẹ, koda ohun ti n jẹ banger, mi o le ba wọn yin, mo fi ẹnu gba ara mi kalẹ ni, nitori nnkan to ṣe eeyan ṣaaju ni, ko tun gbọdọ se eeyan ni ẹẹkeji, koda mo le pe ni ẹlẹkẹa gan an.
"O yẹ ki ẹyin ọrọ mi lori Facebook mọ nipa ohun to sẹlẹ nigba ti wọn ko ibọn lọ ka iya mi, pe wọn fẹ pa iya mi, ti wọn fi ibọn fọ gbogbo ile mi, ile ti mọ kọ fun iya mi ni agbegbe Olorunda ni Iragbijin."
Ero Arike ni eyi waye lẹyin ti awọn ajinigbe gbe oun papọ.
O tẹsiwaju pe oun sọ ọrọ naa sita nitori iro ibọn ti oun n gbọ niwaju sọọbu rẹ pe ki oun fi ẹnu gba ara oun kalẹ pe oun ni ibọn ni ile.
O tun fidi rẹ mulẹ pe awọn agbofinro ti wa si ile oun lati wa ṣe iwadii boya loootọ ni oun ni Ibọn sile.
"Awọn agbofinro gbiyanju gan an, wọn bere gbogbo ohun to yẹ ki wọn bere.
"Ile mẹrin ni mo kọ si Iragbijin, ti mo si ni ki wọn lọ wo mẹrẹrin, pe ti wọn ba ri nnkan ti ko da, ara to ba wu wọn ki wọn fi mi da.
Mi o mọ pe ọmọ ti mo gba tọ ti tan kamẹra lasiko ti mo n sọrọ
Ero Arike ni oun ko mọ pe, ọmọ ti oun gba tọ, to jẹ ọmọ ọdun mẹtala ti tan kamẹra lasiko ti oun sọrọ, to si ju sori ayelujara, ki se pe oun mọmọ gbe ọrọ naa sita.
O fikun pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ni ki oun mu ọmọ wa si agọ wọn fun itẹsiwaju iwadii.
"Wọn ti ni ki a mu ọmọ wa lonii, pe awọn fẹ ri ọmọ naa"
O wa fi asiko naa dupẹ lọwọ agbofinro se suure gba lasiko ti oun ni iṣoro nipinlẹ Osun
Ki lo sẹlẹ saaju?
Agbaọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Osun, Falilat Oyetunji, ẹni ti ọpọ mọ si Ero Arike, ni o dunkoko ita gbangba mọ awọn ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Osun, to si jẹ ko di mimọ pe oun ni ibọn, ti oun si le yin mọ ẹnikẹni to ba tafelefele wa ba.
Ero Arike sọ ọrọ yii ninu fọnran kan to tan kiri oju opo Facebook, to si tun fẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe wọn ko mọ pe oun ko ka iwe nigba ti wọn n gba ẹbun lọwọ oun.
Tibinu-tibinu ninu fọnran naa, Ero Arike ni oun ko ni faye gba ki eeyan kan tabuku oun, to si kilọ fun awọn ẹgbẹ oṣelu PDP lati jina si oun.
"O sọ pe n ko ka iwe, sibẹsibẹ o gba maalu meji ati apo elubọ lọwọ mi," o sọ ninu fidio naa.
"Ẹ ma sun mọ mi, ẹru rẹ ko ba mi rara. Ipo ti ẹ wa lonii, o ko ṣiṣẹ fun rara.















