Aláwàdà làwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà, bí wọ́n bá fẹ́ kí n tún físà wọn gbà, kí wọ́n mú u wá sílé mi fúnra wọn - Soyinka

Àkọlé fídíò, Aláwàdà làwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà, bí wọ́n bá fẹ́ kí n tún físà wọn gbà, kí wọ́n mú u wá sílé mi fúnra wọn - Soyinka
Aláwàdà làwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà, bí wọ́n bá fẹ́ kí n tún físà wọn gbà, kí wọ́n mú u wá sílé mi fúnra wọn - Soyinka

Gbajumọ onkọwe ati ajafẹtọ, Ọjọgbọn Wọle Soyinka ti ṣalaye pe oun ko ni fisa kankan lati bere fun mọ lọwọ ijọba orilẹede Amẹrika o.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ọjọgbọn Soyinka ṣalaye pe bi awọn alaṣẹ Amẹrika ba woye pe awọn ṣe aṣiṣe nipa fisa oun ti wọn wọgile laipẹ yii awọn funrawọn ni ki wọn wa si ile oun lati w agba iwe irinna pasipọọti oun lati lọ fi ountẹ wọn lu u fun fisa ki wọn si tun da a pada wa fun oun.

Bi ẹ ko ba gbagbe laipẹ yii ni iroyin gbode pe ijọba Amẹrika ti wọgile fisa ountẹ aṣẹ irinna silẹ Amẹrika ti wọn fun ogbontarigi onkọwe naa gẹgẹbi Ọjọgbọn Soyinka funrarẹ ṣe sọ ninu ọrọ kan lọjọ diẹ sẹyin. Amọṣa nigba ti BBC News Yoruba bii pe ṣe o n gbe igbesẹ lati gba fisa tuntun, O ni 'alawada' lawọn alaṣẹ orilẹede naa.

Amẹrika ni lati gba fisa wa sile temi gan lati wa fun mi ni fisa ti wọn ba fẹ fun mi ni fisa pada – Soyinka

Nigba to n sọrọ lori ohun ti wọn kọ sinu lẹta ti wọn fi ṣọwọ sii pe to ba fẹ lati tun gba fisa naa, ko funrarẹ mu iwe irinna silẹ okeere rẹ wa ki wọn le fountẹ lu u, Ọjọgbọn Soyinka ni bi kii ba ṣe pe awada Amẹrika pọ ju, ṣe o yẹ ki wọn gbero pe iru oun yoo dide kuro nile oun wa maa mu iwe irinna kiri fun ontẹ fisa Amẹrika.

"Mo ni ki wọn wa si ile mi ki wọn w agba iwe irinna pasipọọti mi funra wọn, ki wọn mu u lọ si ọfiisi wọn , ki wọn lọ lu u lontẹ."

Agba onkọwe naa ni ko si ọrọ lori pe boya oun fẹ fisa wọn mọ. o ni amọ bi o b awa wu Amẹrika o lati se fisa oun funrawọn lẹyin ti wọn ba ti gba pe awọn ṣe aṣiṣe o, a jẹ wi pe awọn alaṣẹ ọrọ fisa nibẹ yoo ni lati wa sile oun w agba iwe irinna oun funrawọn lati lọ fontẹ lu u ki wọn si da a pada, 'ki ẹ to dẹ le wa si ile mi, ẹ maa gba fisa ki ẹ to wọle'.