N kò nílo ẹ̀sìn Mùsùlùmí, Krìstẹ́nì tàbí ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àmọ́ ... - Wole Soyinka

Aworan

Oríṣun àwòrán, www.facebook.com/jude.idada

Ọjọgbọn ati onkowe, Wole Soyinka ti kede pe oun ko ki n ṣe Musulumi, Kristẹni tabi ẹlẹsin ibilẹ rara.

O sọ eleyi nigba to n ṣe afihan iwe rẹ to pe orukọ rẹ ni ‘Of Power and Freedom’, eyi to waye ni Mike Adenuga Center to wa ni Ikoyi, nipinlẹ Eko, lọjọ Aiku ọsẹ yii.

Soyinka, nigba to n dahun si ibeere, akọroyin, Kunle Ajibade bii pe o kọ sinu iwe rẹ pe oun ko ki n ṣe Musulumi, Kristẹni tabi ẹlẹsin ibilẹ sugbọn o maa n lo awọn ẹsin naa lati ṣe apẹẹrẹ ninu awọn iwe rẹ.

Iru ẹsin wo gan lo wa n ṣe?

Nigba to n fesi, Soyinka ni oun ko ki n ṣe ẹlẹsin kankan pato ati pe oun ko nilo wọn fun idi kan tabi omiran.

O ṣalaye pe otitọ nipe oun ko ba wọn kopa ninu siṣe ẹsin wọn sugbọn oun ri awọn oriṣa gẹgẹ bii pe wọn wa lootọ ati pe oun maa n lo wọn ninu awọn iwe oun.

“N jẹ mo ni igbagbọ ninu ẹsin kankan? N ko ro pe mo nilo ẹyọkan.

“Awọn eeyan ni ẹtọ wọn ati pe awọn eeyan kan maa n ṣe dida oriṣa.

“Ko si nnkan to buru pe mo n lo awọn oriṣa yii ninu awọn iwe mi.

“Sugbọn ki n kopa ninu ẹsin? Rara, n ko ṣe ẹsin kankan, n ko si nilo wọn”.