'Àwọn ọmọdé pọ̀ tó kú, iye èèyàn tí ilẹ̀ rírì Ìndonesia pa tún ti gòkè síi'

Ilẹ riri ni Indonesia

Iṣẹlẹ ilẹ riri to waye ni Indonesia ti mu ẹmi ọpọlọpọ eeyan lọ bayii ti ẹnikẹni ko si lee sọ pato iye eeyan to ti gba ibẹ ku.

Ọpọlọpọ awọn to ku ti awọn mii si tun farapa nibẹ lo jẹ ọmọde ti wọn wa nile ẹkọ lasiko ti ikọlu naa waye, adoola lo sọ eyi.

Aprizal Mulyadi to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla sọ pe oun ha inu ilẹ riri naa “lẹyin ti yara ti mo wa ninu rẹ wo lulẹ ti ẹsẹ mi si ri sabẹ ilẹ naa”.

O ni ọrẹ oun kan lo fa oun jade sibi abo amọ ti oun funrarẹ pada ku lẹyin ti oun naa tun ri sinu ilẹ ọhun.

Awọn adoola ti n wa ilẹ kiri lati wa awọn to ye lẹyin ti o le ni eniyan ọgọrun ti ku ti ẹgbẹgbẹrun si ti di alainile lori mọ.

Ilẹ riri

Lasiko ti ilẹ naa n ri, wọn gbe ọpọlọpọ eeyan digba digba lọ ileewosan ti wọn si n tọju ọpọlọpọ wọn ni ita gbangba.

Titi di alẹ ni awọn adoola n ṣa akitiyan lati ran awọn eeyan ti wọn n lero pe wọn ha si abẹ awọn ile to wo lulẹ.

Titi di asiko yii, iye eeyan to ri sinu ilẹ ko tii yeamọ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri sọ pe mejilelọgọta ni ti oludari ẹkun naa, Ridwan Kamil ni tirẹ sọ pe eeyan mejilelọgọjọ lo ti padanu ẹmi wọn.

Ilẹ̀ rírí náà pa èèyàn 162, 700 farapa

Ọkunrin kan duro nitosi ile to wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Iṣẹlẹ ilẹ riri kan to waye ni erekusu Java Island ni orilẹ-ede Indonesia ti pa eeyan ti ko din ni mejilegọjọ, ti ogunlọgọ si farapa.

Awọn alaṣẹ sọ pe ilẹ riri naa waye milu Cianjur, ni Gusu Java, to si rin jina to kilomita mẹwaa.

Toru-toru ni awọn oṣiṣẹ adoola fi ṣiṣẹ lati fa awọn eeyan ti igbagbọ wa pe o ha si abẹ awọn ile to wó lulẹ.

Awọn agbegbe ti ilẹ riri naa ti waye jẹ eyi to kun fun eero pupọ, to si wa ninu ewu ilẹ riri ni gbogbo igba.

Gomina ipinlẹ Gusu Java, Ridwan Kamil sọ fun awọn ileeṣẹ iroyin abẹle pe eeyan mẹrindinlọgọta lo ku, ti awọn to le ni ẹẹdẹgbẹrin, 00, si farapa.

O sọ pe iye awọn to kú ati awọn to farapa ṣe e ṣe ko pọ si nitori pe ọpọlọpọ eeyan lo ṣi ha si abẹ awọn ile to wo lulẹ.

Bakan naa lo ni awọn agbegbe kan wa ti ilẹ riri ti ge oju ọna wọn danu.

Ile ẹkọ kan to wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ṣaaju ni olori agbegbe Cianjur, Herman Suherman sọ pe pupọ ninu awọn to farapa ni egungun wọn kán nitori ile to wo le wọn lori.

Iwaju ita ileewosan si ni pupọ ninu wọn ti n gba itọju nitori pe ko si ina ẹlẹtiriiki fun ọpọlọpọ wakati lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ile to pọ ni iji lile naa wo lulẹ, gẹgẹ bi nkan ti ajọ to n mojuto ijamba ni orilẹ-ede naa sọ.

Lara awọn ile naa ni ileewosan kan ati ile ẹkọ Keu kan ti awọn akẹkọọ n gbe.

Koda, ipa rẹ de olu ilu Indonesia, Jakarta, to wa ni bi ọgọrun kilomita si ibi to ti ṣẹlẹ.

Eyi mu ki wọn ko awọn eeyan kuro ni awọn ile alájà pupọ.

Iwaju ita ileewosan si ni pupọ ninu wọn ti n gba itọju

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ilẹ riri wọpọ ni orilẹ-ede Indonesia, pẹlu bo sẹ sunmọ abala to lewu julọ nitosi ogun Pacific.

O si le ni ẹgbẹrun meji eeyan to ku ninu iru iṣẹlẹ yii to waye ni ọdun 2018.