Mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi, àmọ́ ọ̀lẹ ni lórí bẹ́ẹ́dì ni mo ṣe bá ẹ̀gbọ́n rẹ lòpọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Niṣe ni irọnu dori agba kodo nigba ti Japhet Aba, ẹni to sẹsẹ darapọ mọ ikọ ọlọpaa orilẹede Naijiria, to si lọ ipinlẹ Bauchi lati lọ kọ si ipa imọ isẹ ọhun, sugbọn nigba to ma padade si ilu abinibi rẹ ni ipinlẹ Nasarawa, oyun oloyun ni iyawo rẹ fi ki kaabọ, koda oyun ẹgbọn rẹ ni.

Japhet, ọdọmọkunrin lati ijọba ibilẹ Doma nipinlẹ Nasarawa, to si jẹ ọmọ kan soso fun iya rẹ, ni o gbera lọ si ipinlẹ Bauchi kete ti o gba isẹ ọlọpaa lẹyin oṣu mẹta to ṣe igbeyawo.

Kete ti Japhet jade ni ile ẹkọ gbogbo niṣe Nasarawa lo darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin oṣu mẹta to ṣe igbeyawo pẹlu afẹsọna rẹ, Angela Onuh, ẹni to kawe jade ni ile ẹkọ gbogbo niṣe ni Lafia.

Igbagbọ wa pe awọn ololufẹ mejeeji bẹrẹ ifẹ wọn ni ọdun kan ṣaaju ki wọn to ṣe igbeyawo, ti wọn si jọ pinnu lati ma ba arawọn lopọ, eyi ti wọn sun di ẹyin igbeyawo wọn.

Bawo ni ọrọ oyun ṣe waye?

Ibalopo ti awọn mejeeji jọ ṣe lẹyin igbeyawo ko kun to lati di oyun nitori kete ti wọn ṣe ayẹyẹ igbeyawo ọhun ni ọkọ mo rile ipinlẹ Bauchi fun ileeṣẹ ọlọpaa.

Ki Japhet to morile ipinlẹ Bauchi, o gba ile gbigbe fun iyawo rẹ ni Lafia ni agbala kan na ti ọkan lara awọn ọmọ baba rẹ to jẹ ọkunrin, Samuel Aba, gba ile si, pẹlu igbagbọ pe yoo ma a mojuto iyawo oun titi ti oun yoo fi pada de.

Sugbọn nigba ti Japhet pada de lẹyin oṣu mẹsan an, nnkan to ka laya lo ba pade.

Iyawo rẹ ti loyun.

Lẹyin ọpọlọpọ ibeere, Angela to jẹ iyawo ni Samuel lo fi ọgbọn mu oun wọle to si ba oun lopọ titi to fi di oyun.

Nigba ti Japhet Aba ba ileeṣẹ iroyin The Nation Newspaper sọrọ, o ni:

“Nigba ti a ṣe igbeyawo ni bẹrẹ si ni ma ba arawa lopọ sugbọn ko si apeere oyun lara iyawo mii titi mo fi gba isẹ ọlọpaa. Ki n to lọ, a sọ ọpọlọpọ ọrọ nipa ọjọ ọla wa.

“Gẹgẹ bii ọkunrin kan soso fun iya mi, o fẹ ki n ṣe kia pẹlu igbeyawo, ki n si bimọ sugbọn emi ati iyawo mi ni ki a duro di igba ti mo pada de lati ipinlẹ Bauchi.

“N ko le ro pe nnkan bayi le ṣelẹ nitori ọpọ igba ni emi ati iyawo mi ma sọrọ ni lori ibanisọrọ, to si ma wa ba mi ni Bauchi ni awọn igba kan.

“Ohun iyalẹnu lo jẹ fun nigba ti mo ri oyun ninu iyawo mi, oyun ti n ko mọ nipa. Nigba ti a bẹrẹ iwadi, iyawo mi darukọ orukọ ẹgbọn mi, ẹni ti mo ni ko ma ba mi tọju iyawo mi.

“A ṣe esu ti lo ẹgbọn mii lati da igbeyawo mi ru. Nigba ti mo bẹrẹ lọwọ rẹ, o ni iyawo mi lo fi ipa ba oun lopọ.

Ọgbẹni Japhet ni iyawo sọ fun oun pe oun o le ṣe to lori bẹẹdi, ti oun ko si le tẹlọrun pẹlu.

"Koda oṣu meta ti a jọ ti gbe pọ ti fihan pe n ko le tẹlọrun rara, ti o si nilo ọkunrin to gbe oun de bẹ."

Bakan naa lo sọ pe Samuel, to jẹ ẹgbọn oun sọ pe nigba ti ẹjọ iyawo pọju, ti oun ko si fẹ ko wo ita ni oun ni ki oun ṣe iranlọwọ fun.

“N ko fẹ sọ ẹgbọn lẹnu sugbọn mo binu si iyawo mi pe o gbe ẹjọ wa bọ sita. Iya mi ni ki n sọrọ sugbọn mo kọ nitori a sẹsẹ padanu baba wa nibi oṣu diẹ sẹyin ni.

O ni oun ko fẹ iyawo oun mọ, ṣugbọn oun sọ iriri oun lati le jẹ ki araye mọ nkan to ṣẹlẹ si oun.

Japhet ni Samuel to jẹ ẹgbọn ti padanu ẹmi lẹyin ti awọn agbebọn ṣekọlu si ni ori oko re ni abule Doma sugbọn o fi oju kan ọmọ ti iyawo oun bii ko to ku.

“O ṣeni lanu pe Samuel ti jade laye lẹyin ti awọn agbebọn kan ṣe ikọlu si lori oko rẹ. N ko le lọ sibi eto isinku rẹ nitori emi naa wa ni ilewosan."

Mo nifẹ oko mii sugbọn ọlẹ ni lori bẹẹdi- Angela

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iyawo ọhun pẹlu omije loju tori aforijin lọwọ ọkọ rẹ to si ni ko wa aye diẹ lọkan rẹ lati forijin ohun nitori oun ti sẹ ẹlẹda rẹ.

O ni otitọ ni ọkọ sọ ati pe esu lo ti oun si bi oun ṣe ohun to n ṣe lati ba ẹgbọn ọkọ oun sun. Ti oun si tun loyun pẹlu.

Angele ni Samuel ri ifa, o to si mọ iwulo rẹ to jẹ pe oun ko fi igba kankan fi silẹ rara.

“Nkan ti mo lara kọja bayi lo kọja oye mi. N ko ni erongba lati yan ọkọ mi jẹ nigba ti a ṣe igbeyawo lẹyin ti a ti jọ pinnu lati ma jẹ ni ibaṣepọ nigba ti a n fẹ ara wa.

“N ko sọrọ sugbọn nigba to ara mi ti ko gba mọ lo sun mi de bẹ, isẹ eṣu nio

Angela ni awọn obi oun lo ni oun ko gbọdọ sẹ oyun nitori pe oun yoo ku to ba gbinyanju lati sẹ oyun ọhun

O ni, “Nigba ti emi ati ọkọ mi fẹra, ti a bẹrẹ si ni ma ni ibalopọ. Mo ri pe ko le ṣe to nkan ti mo fẹ, ti ko si fẹran lati ma bami ni ibalopọ.

“A ko ni ibalopọ kankan nigba ti a fẹra sugbọn nigba ti fẹra, o si n saa lati ṣew oju ṣe rẹ.

“Ọpọ igba ni o jẹ pe emi ni mo maa fa mọra sugbọn pẹlu iyan naa ko tẹmilọrun. Otitọ bẹ nipe mo fẹ ọkunrin ti yoo tẹmilọrun sugbọn ọkọ ya ọlẹ. Nigba ti mo fun ẹgbọn rẹ ni anfani, o jẹri ara rẹ. Eni ni mi, mo ṣe asisẹ.

“Oko mi ko sẹ mi, koda emi gan ni mo sẹ ọkọ mii. Mo nifẹ ọkọ mii sugbọn ko tẹmilọrun pẹlu ibalopọ.

“Ipade mii pẹlu Smauel lo fun ni anfaniu lati gbadun nkan ti wọn pe ni ere ifẹ pẹlu ibalopọ to dara.