Ìdìbò tó ń bọ̀ kìí ṣé "Ìdìbò Èmi ló kán", ìdìbò àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Naijiria ní - Peter Obi

Aworan Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Kadaria Ahmed

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ti rọ awọn ọmọ orilẹede lati ma ṣe ri idibo to n bọ gẹgẹ bii idibo "emi lokan" nitori asiko awọn ọmọ orilẹeede Naijiria lokan lati yan aarẹ ti yoo wu wọn ninu gbogbo laasigbo ti wọn wa.

Obi sọ eleyi nigba ti oun pẹlu igbakeji rẹ, Sẹnẹtọ Datti Baba-Ahmed n kopa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu Kadaria Ahmed lana.

O sẹ ọpọlọpọ ileri fun awọn ọmọ Naijiria pe ti wọn ba fun oun ni aye lati ṣejọba, ayipada lai ni ẹgbẹ ni yoo de ba orilẹede naa.

Obi ni ki awọn ọmọ Naijiria ma ṣe ri idibo to n bọ ọhun gẹgẹ bii ti ẹlẹyamẹya tabi ẹsin.

Ki ni ileri ti Peter Obi ati Datti Baba-Ahmed ṣe fawọn ọmọ Naijiria?

 “Awa mejeeji, emi ati igbakeji mii ti rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria pe eto idibo to n bọ ko gbọdọ da le ẹlẹyamẹya, ko gbọdọ da le lori ẹsin, ko gbọdọ da lori pe emi lo kan nitori pe asiko awọn ọmọ Naijiria lo kan lati gba iṣejọba orilẹede yii.

“Mo n ṣe ileri pe maa yọ Naijiria kuro ninu oko ẹru, ti awa yoo si bẹrẹ lati pese awọn nnkan ti a fẹ fun ara wa.

“Isẹ yoo dikun patapata lorilẹede Naijira. A maa rii pe ko si ẹnikẹni to kọja ibawi labẹ ofin.

“A fi n daa yin loju pe iwa ibajẹ eyi to gbalẹ lorilẹede Naijria yoo di ohun igbagbe. A oo rii pe a pese Naijiria fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Peter Obi, ẹni to jẹ igbakeji aarẹ fun olujide sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar lọdun 2019, kuro ninu ẹgbẹ ọhun lati lọ dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour fun eto idibo lọdun 2023.