Eré ìtàgé kọ́ là ń ṣe ní "Justice Court" ní Eko, báyìí ni mo ṣe ń parí ìjà tí wọ́n bá gbé wá - Funmi Asaolu

Àkọlé fídíò, Lagos Justice Court: Eré ìtàgé kọ́ là ń ṣe ní "Justice Court" ní Eko, báyìí ni mo ṣe ń par

"Gbogbo nnkan ti mo n ṣe ni ile ẹjọ "Justice Court" bẹrẹ nitoripe a fẹ fi ran awọn araalu lọwọ paapaa awọn ti ko ni owo lati lọ gba agbẹjọro".

Bi ẹ ba ti n gbọ nipa ile ẹjọ kan tabi ti ẹ n rii wo lori ayelujara ati ẹrọ amohunmaworan to dabii sinima loju yin pe wọn n da ẹjọ awọn ara adugbo, kii ṣe fiimu o.

Adajọ Asaolu

BBC Yoruba wa ile ẹjọ naa kan a si fi ọrọ wa agbẹjọro Funmi Asaolu ati awọn eeyan to ti gbe ẹjọ lọ sibẹ ri ti wọn n kan sara si bi adajọ Funmi ṣe nu omije awọn nu plu iru ọna ti o gba da ẹjọ ti wọn gbe wa.

"Iwa ipa n wa latọdọ iyawo si ọkọ o si n wa latọdọ ọkọ si iyawo, eleyi si lo maa n pọ ju ti wọn maa n gbe wa si ọdọ wa".

Ile ẹjọ

Oniruuru ni ẹjọ ti awọn araalu maa n gbe wa siwaju adajọ yii ti yoo ya eeyan lẹnu gidi gan pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ.

Igba miiran, ẹjọ iwa ipa ninu ile laarin lọkọ laya lẹ o maa wo ti ẹkun yoo maa bọ loju yin. Ẹjọ katakara, owo ile sisan, itọju ọmọ, ibagbepọ laarin awọn ara adugbo kan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ile ẹjọ

Adajọ Funmi tun mẹnu ba alaye ati alakalẹ ofin lorii oniruuru ẹjọ ti awọn mii ti ja tabi lu ara wọn le lori fun apẹrẹ bi ọkunrin ba dede fun obinrin loyun ti wọn ko tii ṣe igbeyawo, gbogbo ẹtọ ti obinrin ati ọmọ inu yoo gba lọwọ ọkunrin naa ni adajọ yii ṣe lalaye.

Funmi Asaolu jẹ ko di mimọ pe gbogbo ẹjọ ni awọn maa n ṣe yatọ fun ẹjọ to jẹ ti iwa ọdaran nikan ti awọn kii da si ti awọn yoo si gbe lọ si ibi ti o yẹ ki wọn ti daa

"Gbogbo ẹjọ ti a n da pata lo fẹsẹ mulẹ labẹ ofin Naijiria to si jẹ pe bi ẹnikẹni ba rufin, ao muu ko jẹ ijiya to tọ".