Nkan mẹ́fà nípa Olubunmi Adelugba, obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ olórí ilé aṣòfin Ekiti

Oríṣun àwòrán, Olubunmi Adelugba/Facebook
Ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni wọn dibo yan Aṣofin Olubunmi Adelugba gẹgẹ bi olori ile aṣofin tuntun fun ipinlẹ Ekiti.
Eyi waye lẹyin ti awọn ọmọ ile aṣofin naa yọ olori wọn tẹlẹ, Gboyega Aribisogan lai pe ọsẹ kan nipo.
- Aṣofin Olubunmi Adelugba ni obinrin akọkọ to jẹ olori ile aṣofin nipinlẹ Ekiti lati ọdun 1996 ti wọn da ipinlẹ naa silẹ
- Ọdun 2019 lo darapọ mọ awọn aṣofin lẹyin to jawe olubori ninu idibo to waye ni ẹkun idibo Emure constituency 1
- Arabinrin Adelugba, gẹgẹ bi akọsilẹ to wa nipa rẹ lori ayelujara Linkedin rẹ, ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluyẹwe owo wo fun awọn ileeṣẹ, to si tun jẹ olugbani nimọran lori eto ẹnawo fun bi ogun ọdun.
- Bakan naa lo ti fi igba kan jẹ oluyẹwo fun eto owo ori fun ijọba ipinlẹ Rivers.
- Oun ni kọmisanna akọkọ fun ọrọ oṣiṣẹ ati idagbasoke awọn oṣiṣẹ, fun ipinlẹ Ekiti
- O tun jẹ oludamọran pataki lori ọrọ owo ori ati bi ijọba Ekiti ṣe n pa owo wọle laarin ọdun 2011 si 2014.
Wọ́n yọ olórí ilé aṣòfin Ekiti láì pé ọ̀sẹ̀ kan tó dé ipò

Oríṣun àwòrán, Others
Ile aṣofin ipinlẹ Ekiti ti yọ olori wọn, Gboyega Aribisogan, wọn si tun da a duro gẹgẹ bi aṣofin titi di igba ti ẹnikan ko mọ.
Ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 ni iyọnipo naa waye lẹyin ọsẹ kan pere ti wọn dibo yan-an.
Ọjọru ọsẹ to kọja, ni wọn yan Aṣofin Aribisogan lẹyin ti olori ile tẹlẹ, Funminiyi Afuye, ku ninu oṣu Kẹwaa.
Aṣofin mẹtadinlogun ninu mẹẹdọgbọn lo pawọ pọ yọ, ti wọn si yan Aṣofin Olubunmi Adelugba si ipo naa.
Adelugba ati Aribisogan lo jọ dije fun ipo naa ni ọsẹ to kọja.
Ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa ti kọkọ ti ile aṣofin naa pa ni ọjọru, lẹyin ti wọn dibo yan Aṣofin Aribisogan ni olori ile tuntun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti sọ nigba naa pe awọn gbe igbesẹ naa nitori pe awọn fura pe awọn janduku kan n gbero lati da wahala silẹ.
Aṣofin Gboyega Aribisogan sọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Channels lọjọ Aiku pe gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Kayode Fayemi, n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọmọ ile aṣofin naa lati yọ oun nipo.
Yatọ si oun, aṣofin mẹfaa mii ni awọn aṣofin yooku tun ni ko lọ joko sile naa.
Ṣugbọn ṣa, Ọgbẹni Aribisogan sọ pe òfo ni yiyọ oun nipo yoo ja si.
Ninu ọrọ akọsọ rẹ gẹgẹ bi olori ile, o ni oun ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu igbimọ oluṣakoso ipinlẹ Ekiti, lati mu ki igbeaye rọrun fun awọn araalu.
Bakan naa lo ni oun ṣetan lati lati mu ki ibaṣepọ to dara wà laarin ẹka ijọba mejeeji.












