Adeleke fọ̀rọ̀ ìdágbére ńlá ránṣẹ́ sí Oyetola tó ń kó ẹrù rẹ̀ kúrò nílé ìjọba Osun

Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti rọ Gomina to ti fẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola pe ko gba kamu pe o ti lulẹ ninu eto idibo gomina to waye ni oṣu Keje, pe ko si simi ariwo ni pipa.
Agbẹnusọ Adeleke, Olawale Rasheed ninu atẹjade to fi ransẹ si Oyetola lẹyin to kede pe oun yoo gba ẹtọ oun, ni pe ko si ẹtọ kankan to fẹ gba lọwọ Adeleke nitori gbogbo ọna ni o fi fi idi rẹ janlẹ ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Osun.
O ni erongba buburu ni Oyetola ni si awọn eeyan ipinlẹ Osun latari bi o ṣe n fi irọ ati ailotọ ṣe ijọba rẹ.
Adeleke ni kete ti Oyetola ri pe oun ti lulẹ ni o ti bẹrẹ si ni maa ṣe owo ipinlẹ naa basubasu sugbọn ti ile ẹjọ si ti tu ọpọlọpọ irọ ti Oyetola pa fun awọn eeyan.
“O mọ pe o ti n lọ, o wa bẹrẹ si ni maa ṣe owo ilu basubasu, o n dẹ pakute fun eeyan ipinlẹ Osun ni.
“O le gun akaso lati maa tan awọn alatilẹyin rẹ ti ẹ jọ ṣe ijọba basubasu
“Nnkan ti a ni lati ba iwọ ati awọn ẹmẹwa rẹ sọ ree. Ọsẹ yii loku fun ẹ ninu ile ijọba. Ko gbogbo nnkan too ba fẹ.
“Sugbọn a fẹ koo mọ pe gbogbo awọn too yan, ti ẹ jọ sisẹ pọ lati ṣe owo ilu basubasu ni yoo fi oju ba ofin.”
Kò sí àní-àní, èmi ni mo borí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Osun – Oyetola

Oríṣun àwòrán, others
Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola, ti fi ogun re gbari pe oun yoo gba ẹtọ oun lọwọ gomina tuntun, Ademola Adeleke, nile ẹjọ.
Oyetola sọ eleyi nigba darapọ mọ awọn araalu nibi ayẹyẹ Iragbiji ni ijọba ibilẹ Boripe, o ni o da oun loju pe oun bori eto idibo gomina to waye ninu oṣu keje ọdun yii.
O tẹsiwaju pe oun yoo tun pada wa ba awọn eeyan ijọba ibilẹ Boripe ṣe ajọyọ gẹgẹ bii gomina lọdun to n bọ.
“Ni agbara Ọlọrun, Insha Allah, ma tun wa bayin ṣe ajọyọ yii lọdun to n bọ gẹgẹ bii gomina.
“O da mi loju, ko si aniani pe ma gba ẹtọ mi lọwọ wọn.”
Ajọ eleto idibo nilẹ wa kede esi idibo gomina nipinlẹ Osun to waye lọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun osu Keje ọdun 2022.
Ajọ INEC ni Sẹnatọ Ademola Adeleke tii se oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP lo bori idibo ọhun.
Adeleke lo ni apapọ ibo 403,371 eyi to mu ko fi ẹyin gomina to wa lori aleefa janlẹ, eyiun Adegboyega Oyetola.















