Ọkùnrin kan ṣekúpa ìyá ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn tí ìyá ká níbi tó ti ń ba àbúrò ìyàwó rẹ̀ sún

Oríṣun àwòrán, Twitter.com/BenHundeyin
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ ọkunrin kan, ẹni ọdun mejidinlogoji fun ẹsun pe o ṣekupa iya iyawo rẹ ati ẹlomiran to ri igba to ṣe isẹ ibi naa ni agbegbe Akodo nipinlẹ Eko.
Ọkunrin ọhun ni iya iyawo rẹ ri nibi to ti n ba aburo iyawo rẹ, ọmọ ọdun mẹrinla sun, eyi lo sokunfa idi to gba ẹmi obinrin naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo kede isẹlẹ naa lori opo ayelujara rẹ, Twitter ni Ọjọ Satide.
Gẹgẹ bii Hundeyin ṣe salaye, o ni kete ti ọkunrin naa ri pe Iya iyawo ọhun ti ri oun nibi to ti n ba aburo iyawo rẹ ni ibalopọ lo gbemi rẹ, to si tun pa ẹlomiiran to ri nigba to ṣekupa iya iyawo rẹ.
“Ni agbegbe kan ni Akodo, ọkunrin kan, ẹni ọdun mejidinlogoji ṣekupa iya iyawo rẹ, to si tun ṣekupa ẹlomiiran to ri nigba to ṣe isẹ ọhun.
“O ti wa ni ahamọ wa bayii. Iwadi ti fihan pe o gbe igbesẹ naa lẹyin to ri pe iya iyawo ti ri oun nibi to ti n ba aburo iyawo, ẹni ọdun mẹrinla sun.
“Ẹjọ naa ni a ti gbe lọ ileeṣẹ ọlọpaa to n risi iwa ọdaran lati tẹsiwaju ninu iwadii.”











