Ekiti, Kano, Ondo, Eko àti àwọn ìpínlẹ̀ mìí tí tálákà pọ̀ sí jùlọ ní Naijiria

Obinrin kan ti n ṣa idọti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba apapọ ti fi akọsilẹ nipa awọn ipinlẹ ti awọn akuṣẹ pọ si ni Naijiria.

Gẹgẹ bi akọilẹ naa ti ajọ to n ri si onka ni Naijiria, Nigeria Bureau of Statistics, fi sita, aadoje miliọnu ọmọ Naijiria lo jẹ talaka. Eyi tumọ si pe ida mẹtalelọgọta eeyan to n gbe ni Naijiria ni eyi kan.

Yatọ si ajọ NBS, awọn ajọ mii to tun kopa ninu iwadii naa ni National Social Safety-Nets Coordinating Office (NASSCO), United Nations Development Programme (UNDP), United Nations Children Fund (UNICEF), ati di Oxford Poverty and Human Development Initiative (OPHI).

Iwadii naa tun fihan pe ida aadọta ninu ọgọrun ọmọde ni Naijiria lo n gbe ninu ìṣẹ́ ati òṣì.

Botilẹ jẹ pe igba miliọnu eeyan to n gbe ni Naijiria ni wọn gbe iwadii naa le lori, ẹgbẹrun lọna aadọta idile ni wọn ṣe ayẹwo si.

Gẹgẹ bi abajade iwadii naa, ilaji awọn to jẹ talaka lo n dan a pẹlu awọn nkan bii igi tabi eedu, dipo ina ti ko lewu fun ilera.

Yatọ si eyi, wọn ko tun ni anfaani si eto ilera to peye, ounjẹ ati ile gbigbe.

O tun fihan pe ida marundinlaadọrin awọn to jẹ talaka ọhun (80 milliọnu) lo n gbe ni Ariwa, ti ida marundinlogoji (47 miliọnu) si n gbe ni Gusu.

Wọn yii ni awọn ipinlẹ ti awọn talaka pọ si julọ ni Naijiria

Kano – Ipinlẹ Kano ni awọn eeyan to talaka pọ si julọ ni Naijiria. O le ni miliọnu mẹwaa eeyan.

Kaduna – Ipinlẹ yii lo wa ni ipo keji ninu awọn ipinlẹ ti talaka pọ ju si ni Naijiria. Awọn eeyan to le ni miliọnu mẹjọ lo wa ni ipinlẹ Kaduna nikan ṣoṣo.

Katsina – O le ni miliọnu mẹfaa eeyan to jẹ akuṣẹ ni ipinlẹ Katsina.

Sokoto – Sokoto ni ipinlẹ to wa ni ipo kẹrin lara awọn orilẹ-ede ti awọn talaka pọ ju si ni orilẹ-ede Naijiria. Eeyan to to miliọnu mẹfaa (5.8 miliọnu) ni wọn ni ni ipo yii.

Jigawa – Eeyan bi 5.76 miliọnu lo jẹ talaka ni ipinlẹ Jigawa. Ipinlẹ naa si lo wa ni ipo karun-un.

Bauchi – Ipinlẹ Bauchi lo tẹle Jigawa, pẹlu eeyan

Awọn ipinlẹ to ni iye talaka to kere julọ ni:

Abia – 1.1 miliọnu

Ondo – 1.30 miliọnu

Ekti – 1.31 milinu

Nasarawa – 1.36 milinu

Ipinlẹ Eko ni ti ẹ ni miliọnu mẹrin eeyan to jẹ talaka.