Disability; Arabinrin Temidayo ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ní òògùn ni wọ́n fún òun nítorí òun yan ẹni tí kò ríran láàyò gẹ́gẹ́ bí ọkọ

Àkọlé fídíò, Arabinrin Temidayo ni ọpọ eniyan ni oogun ni wọn lo fun oun bi o ṣe yan ẹni ti ko riran.

Arabinrin Temidayo Arabinrin Temidayo ni ọpọ eniyan ni oogun ni wọn lo fun oun bi o ṣe yan ẹni ti ko riran laayo gẹgẹ bi ọkọ oun.

Obinrin naa to sọ iriri rẹ ni ori ẹrọ ayelujara Facebook ni awọn ti pade to si jẹ pe oun lo kọkọ beere lati jẹ ọrẹ rẹ lori Facebook.

Temidayo ni ki oun to fi oju mejeeji ri arakunrin naa ni oun ti fẹran rẹ, ti ifẹ wọn si tun pọsi lẹyin ti awọn ri ara wọn si oju.

Ninu ọrọ tirẹ, Arakunrin Ademola Adeleke ni ọpọlọpọ igba ni oun ti fẹ kọnu si obinrin amọ oun ko fẹ ki wọn tabuku oun nitori oun ko riran.

Amọ o ni oun ri iyawo oun gẹgẹ bi alaanu to si ṣee fi ọkan tan.

Eleyii to julọ ni pe, ọkọ rẹ sọ fun un ni ọjọ mẹta si igbeyawo wọn pe awọn n lọ si Ilẹ Gẹẹsi lọ kawe , awọn si jọ n lọ ni.

Ẹkunrẹrẹ wa ninu fidio yii...