Wòlíì bá ọmọ ìyá méjì sùn nínú ìjọ rẹ̀, ọ̀kan níńú wọn ti lóyún

Oríṣun àwòrán, Nigeria police, Ogun state
Wolii ijọ Kerubu ati Serafu kan, Joseph Ogundeji ti wọ gbaga ọlọpaa nipinlẹ Ogun fun biba awọn ọmọ iya meji kan lo pọ.
Awọn ọlọpaa sọ pe, ọkan lara awọn ọmọbinrin naa loyun nipasẹ aṣemaṣe naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye ninu atẹjade kan pe ọmọ ijọ Wolii Ogundeji ni awọn ọmọ iya mejeeji naa jẹ ati pe awọn ọlọpaa lọ fi panpẹ ofin mu wolii naa lẹyin ti wọn fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Ajuwọn.
O ni wolii naa jẹwọ nigba ti wọn fi ọrọ waa lẹnu wo pe lootọ loun ṣe aṣemaṣe naa.
Iwadii ọlọpaa fihan pe ọkan lara awọn ọmọbinrin naa jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti ikeji si jẹ ọmọ ọdun mẹtala
“Awọn ọmọbinrin mejeeji yii fi to ọlọpaa leti pe pe nigbakugba ti wọn ba ti ni iṣọ oru ni ile ijọsin, wolii naa ti ile rẹ ko jina si ile ijọsin naa yoo ni ki awọn lọ sun si ile oun nigbakugba ti iṣọ oru naa baa pari ni nnkan bi agogo mẹta.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun sọ pe awọn ọmọbinrin naa tun sọ pe nigba kugba ti awọn ba ti wa ni ile wolii na yoo fun awọn ni nnkankan lati la, eleyi ti yoo mu wọn sun lọ ti awọn yoo si taji nigba to ba ya lati rii pe wolii ti ba awọn ni ibalopọ.
“Nigba ti a bi wọn pe ki lo de ti wọn ko fi ọrọ naa to awọn obi wọn leti, wọn ni wolii naa leri lati pa awọn bi awọn ba sọ ọrọ naa fun ẹda alaye kankan.”












