Ikú ṣọṣẹ́! Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga KWASU jáde láyé

Mustapha Akanbi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọga agba ile ẹkọ giga Fasiti ti ipinlẹ Kwara (KWASU), Ọjọgbọn Mustapha Akanbi ti dagbere faye.

Ọkan lara awọn alakoso ile ẹkọ naa, Arabinrin Kikelomo Salle lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

Atẹjade naa ṣafihan pe lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ ni Ọjọgbọn Akanbi fi aye silẹ.

“A rọ gbogbo eniyan lati ranti idile oloogbe ati Fasiti to fi silẹ ninu adura lasiko yii”.

Salle sọ pe wọn yoo ṣagbejade gbogbo bi eto isinku yoo ṣe lọ.

Ta ni Ọjọgbọn Mustapha Akanbi?

  • A bi oloogbe Ọjọgbọn Mustapha Akanbi si idile Adajọ agba Muhammed Mustapha Adebayo Ajao Akanbi ati Alhaja Munfaatu Aduke Akanbi.
  • Ile Magaji Kemberi, Awodi lagbegbe Gambari ni Ilorin lo ti wa. Akanbi kawe akọbẹrẹ ati girama kaakiri awọn ipinlẹ Naijria bii Kano, Porthacourt, Ibadan ati Imo.
  • Fasiti Obafemi Awolowo ni Akanbi ti kawe gboye ninu imọ ofin lọdun 1993.
  • Ọpọlọ afikun iwe ati oye ni Mustapha Akanbi ti gba to si ṣiṣẹ kaakiri fasiti titi to fi gba ipo Ọga agba Fasiti ipinlẹ Ilorin, KWASU nibi to wa titi ti ọlọjọ fi de.