Orí kó Wole Soyinka yọ lọ́wọ́ ìjínigbé àti ìdigunjalè

Aworan Ọjọgbọn Wole Soyinka
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agba onkọwe lorilẹede Naijiria, Wole Soyinka ti ṣalaye bi ori ṣe ko yọ lọwọ iṣẹlẹ ijinigbe ati idigunjale nilu Bucharest, lorilẹede Romania.

Soyinka sọ eyi nigba to n ba ileeṣẹ iroyin PM News sọrọ lọjọ Kesan an, Oṣu kẹsan an ọdun 2025 niluu Eko.

O ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye pe oun ko ro pe ẹru le ba oun bo se balẹ si ilu Bucharest ni ooru ọganjọ.

Soyinka ni oun pẹ de si ilu naa, ti oun ko si de ba ayẹyẹ ti wọn gbe kalẹ lati ki oun kaabọ ni papakọ ofurufu.

"Aago kan oru ku isẹju diẹ, awakọ taxi to gbe mi mu ẹrọ POS jade, to si ni ki tẹ piini akanti mi sinu POS naa, lati pọ owo jade fun"

Ọjọgbọn Wole Soyinka tẹsiwaju pẹlu alaye rẹ pe "Mo gbe ọkọ, ti mo si morile ile itura Novotel, to jẹ ibi ti mo ma duro si ṣugbọn awakọ to gbe mi ya si ọna miiran, ti ọna yii si da, ko si ẹnikẹni nibẹ.

"Ni o ku isẹju diẹ si aago kan loru, awakọ yii mu ẹrọ POS jade , to si ni ki tẹ piini mi sinu POS naa," Soyinka ṣalaye.

"Mo ni lati tẹ si lai wo ibi ti mo n tẹ si nitori o fi pamọ.

Fun bii isẹju mẹẹdọgbọn si ọgbọn, mo mọ-mọ n tẹ piini to jẹ ayederu, pẹlu erongba pe ẹnikan yoo wa gba mi silẹ ṣugbọn ko si ẹnikẹni nibi ti awakọ naa gbe mi lọ."

Soyinka ṣapejuwe iṣẹlẹ gẹgẹ bii eyi to fa ariyanjiyan laarin rẹ ati awakọ ọhun, to si n tẹnumọ pe, ki oun fi piini oun sinu ẹrọ POS naa.

O ni o pada fi oun silẹ, to si lọ ja oun si ile itura.

Soyinka ni awakọ naa pada ri owo yọ ninu apo asunwọn owo oun ṣugbọn oun ko tiẹ yẹ wo boya wọn da owo naa pada si akanti rẹ.

"Ko ki n ṣe pe mo fẹran lati padanu owo. Ṣugbọn si emi, o kere. Ko ki n ṣe ikọlu si mi lasan ṣugbọn si agbegbe naa,"

Pẹlu ibẹrubojo yii, Soyinka ni won pada wa gbe oun lọ sibi ayẹyẹ ti oun wa fun lorilẹede naa, to waye nilu Sibiu.

Ta ni Wole Soyinka?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igi araba ni Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka nile ati lẹyin odi gẹgẹ bi ọmọ kaaro o jiire ati ọmọ Naijiria.

Sugbọn Wole Soyinka ni awọn eeyan mọ ọ si.

Ọmọ bibi ilu Isara-Remo ni Ọjọgbọn Wole Soyinka, jẹ to si jẹ ẹlẹkeji ninu ọmọ mẹfa ti iya rẹ bi ni ilu Abeokuta ipinlẹ Ogun.

Wọn bi i lọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun 1934.

Baba Wole, Samuel Ayodele Soyinka jẹ olufọkansin alufa ijọ Anglican ati adari ile iwe alakọbẹrẹ.

Iya rẹ, Grace Eniola Soyinka si jẹ ontaja, to tun jẹ ajafẹtọẹni nipa oṣelu laarin awọn obinrin.

Nitori naa, ọgba inu ile ijọsin Anglican ni Wole Soyinka gbe ni kekere, to si n kọ ẹkọ nipa ẹsin Kristẹni lọdọ awọn obi rẹ.

Amọ, bo ṣe n kọ eyi naa lo tun n kọ imọ nipa aṣa ati ẹsin Yoruba lọdọ baba baba rẹ.

Wole Soyinka ni ọmọ ilẹ Afirika akọkọ to kọkọ gba ami ẹyẹ Nobel Prize ninu imọ Litiresọ lọdun 1986.

O ka iwe nilẹ yii bii ile iwe alakọbẹrẹ niluu Abeokuta ati Girama ni Abeokuta ko to lọ si Government College, Ibadan ko to mori le oke okun fun ile iwe giga fasiti University College and University of Leeds, England.

Loke okun, o mu ajo iṣẹ pọn pẹlu Royal Court Theatre, London nibi ti o ti kọ ọpọlọpọ iwe to si ṣe agbejade rẹ ni Naijiria ati loke okun.