'Ńṣe ni gbogbo àwọ́ ara mi ń bó' - Obìnrin Africa tí wọ́n fẹ̀tàn mù láti máa ṣe àdó olóró

Àwòrán àsíá Russia, South Sudan, àdó olóró drone àti obìnrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images / BBC

    • Author, Mayeni Jones
    • Role, Africa correspondent
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ níbi iṣẹ́, Adau ri pé òun ti ṣe àṣìṣe ńlá.

"A gba aṣọ iṣẹ́ wa, láì mọ ohun tí a fẹ́ ṣe pàtó. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí a wọ iṣẹ́ ni wọ́n kó wa lọ sí iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe 'drone'. Bí a ṣe wọlé ni a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdó olóró drone àtàwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn náà ni wọ́n pín wa sí ààyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀."

Adau, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè South Sudan sọ pé ọdún tó kọjá ni wọ́n tan òun lọ sí Alabuga Special Economic Zone ní Republic of Tatarstan ní Russia pẹ̀lú àdéhùn pé wọ́n máa bá òun wá iṣẹ́.

Ó ní òun fi orúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ Alabuga, ètò ìgbanisíṣẹ́ tí wọ́n ń gba awọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí méjìlélógún tí wọ́n wá láti ẹkùn Africa, Latin America àti South-East Asia. Wọ́n máa ń ṣe ìlérí láti fún àwọn tó bá jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ètò ìrìnnà àti iná dídá.

Àmọ́ wọ́n ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń lo ètò náà láti fi tan àwọn èèyàn àti pé wọ́n ń lo àwọn èèyàn láti fi máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó léwu, tí owó tí wọ́n sì ń san fún wọn kéré jọjọ sí iye tí wọ́n fi ìkéde rẹ̀ síta.

Wọ́n jiyàn àwọn ẹ̀sùn náà àmọ́ wọn kò jiyàn pé wọ́n ń lo àwọn èèyàn náà láti fi ṣe iṣẹ́ drone.

Ètò ìgbanisíṣẹ́ Alabuga di ohun tí wọ́n pòkìkí rẹ̀ ní South African lẹ́nu ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí àwọn èèkàn ìlú kan ń polongo ètò náà, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń polongo fífi èèyàn ṣe ìrìnàjò lọ́nà àìtọ́.

BBC kàn sí àwọn èèkàn ìlú náà àtàwọn tó ń ṣe atọ́nà wọn sí ètò náà ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó fèsì sí wa nínú gbogbo wọn.

Pẹ̀lú àkọ́ọ́lẹ̀ tó wà, àwọn obìnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan káàkiri Africa ni wọ́n ti gbà láti máa ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ ìpèsè nǹkan ìjà ogun Alabuga. Ní oṣù Kẹjọ, ìjọba South Africa bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn ẹ̀sùn náà, tí wọ́n sì ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn wọn láti má kópa níbẹ̀.

Adau sọ fún BBC láti má lo orúkọ àti àwòrán òun nítorí òun kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ètò náà. Ó ní ọdún 2023 ni òun kọ́kọ́ gbọ́ nípa rẹ̀.

"Ọ̀rẹ́ mi kan ló kọ́kọ́ fi ìpolongo ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní Russia síta lórí ìkànnì Facebook rẹ̀. Iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ South Sudan ló ṣe agbátẹrù ìpolongo náà.

Ìwé tí wọ́n fi kéde ìpolongo iṣẹ́ ní South Sudan

Oríṣun àwòrán, Supplied to the BBC

Àkọlé àwòrán, Adau signed up after seeing this official advert sponsored by Russia

Orí ìkànnì WhatsApp ló ti kàn sí àwọn agbátẹrù ètò náà.

"Wọ́n ní kí n kọ orúkọ mi, ọjọ́ orí mi àti ìdí tí mo fi fẹ́ darapọ̀ mọ́ Alabuga sílẹ̀. Wọ́n tún ní kí ń ọ̀nà mẹ́ta tó wù mí láti ṣiṣẹ́."

Adau sọ pé òun mú ṣíṣe tower-crane gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àkọ́kọ́. Ó ti máa ń ṣiṣẹ́ lẹ́ka ìmọ̀ ẹ̀rọ tẹ́lẹ̀, tó sì ti ṣe ìrìnàjò lọ sílẹ̀ òkèèrè tẹ́lẹ̀ láti lọ kópa níbi ìdíje síṣe àwọn ẹ̀rọ robot.

"Mo fẹ́ ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka tí àwọn obìnrin kò pọ̀ sí. Ó máa ń pẹ́ láti rí àwọn obìnrin ní ẹ̀ka tower-crane pàápàá ní orílẹ̀ èdè tí mo ti wá."

Ètò ìgbanisíṣẹ́ gbà tó ọdún kan nítorí bí ètò gbígba físà náà ṣe gùn.

Àwòrán tíkẹ́ẹ̀tì láti Instabul sí Juba

Oríṣun àwòrán, Supplied to the BBC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní oṣù Kẹta ọdún tó kọjá ló dé ìlú Russia.

"Òtútù pọ̀ nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Russia, mo kórira rẹ̀ púpọ̀. Lásìkò tí òtútù ń tán lọ ni a dé Russia."

Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ dùn nígbà tí wọ́n dé ẹkùn Alabuga.

"Gbogbo àwọn nǹkan tí mo rí wú mi lórí. Gbogbo nǹkan tí mo rò ló rí. Mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́, àwọn ọkọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ ètò ọ̀gbìn.

Oṣù mẹ́ta ni Adau fi kọ́kọ́ ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èdè Russia kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oṣù Keje. Ìgbà yẹn ni àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí ní yípadà fún-un.

Ó ní wọn kò fún òun àtàwọn míì táwọn jọ wà níbẹ̀ láti sọ pé kò wu àwọn láti ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ drone. Wọ́n ti tọwọ́ bọ àdéhùn pé àwọn kò le sọ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, tí wọn kò sì le bá ẹbí wọn kankan sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀.

"Gbogbo wa la ní a fẹ́ ṣiṣẹ́ ní àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè nǹkan bíi tower-crane ṣùgbọ́n tí a bára wan í iléeṣẹ́ ìpèsè drone."

Alabuga jiyàn fífi ẹ̀tàn gba àwọn èèyàn síṣẹ́. "Gbogbo àwọn ẹ̀ka tí a fẹ́ gba àwọn èèyàn sí ni a fi sórí ìtàkùn ayélujára," ó fèsì sí ìbéèrè BBC.

Wọ́n kìí gba àwọn òṣìṣẹ́ láàyè láti yàwòrán ní iléeṣẹ́ náà àmọ́ BBC ṣàfihàn fídíò tí Adau tó fihàn lórí ìkànnì iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán abẹ́lé RT TV pé ibi tí òun ti ṣiṣẹ́ nìyẹn.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti ń ṣe drone Iran Shahed 136.

Spencer Faragasso ti ilé ẹ̀kọ́ Institute For Science and International Security sọ pé iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè àwọn ohun ìjà ogun ni Alabuga.

"Russia ti sọ pé àwọn ń pèsè drone Shahed 136 nínú fídíò tí wọ́n fi léde. Wọ́n ṣe àfihàn iléeṣẹ́ náà àtàwọn ohun tí wọ́n ti gbéṣe níbẹ̀.

Spencer sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé àwọn kò mọ̀ pé àwọn yóò máa pèsè ohun ìjà ogun níbẹ̀.

"Léréfèé, ọ̀nà fáwọn obìnrin láti ṣàfihàn ara wọn fún arayé ni ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá dé Alabuga tán, ọ̀pọ̀ ìlérí tí wọ́n ṣe fún wọn ni wọn kìí múṣẹ, tí iṣẹ́ tí wọ́n yóò ma ṣe yàtọ̀ sí ìlérí tí wọ́n ṣe fún wọn."

Adau ní kété tí òun débẹ̀ ni òun ms pé òun kò lè tẹ̀síwájú láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Ó ní òun kọ̀wé láti fi iṣẹ́ sílẹ̀ àmọ́ wọ́n ní lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì ni òun tó le fi iṣẹ́ sílẹ̀ tó sì ń ṣiṣẹ́ lo tí ọ̀sẹ̀ méjì náà fi pé.

Ó ní òun lo àwọn kẹ́míkà kan láti fi ṣe iṣẹ́ èyí tó bá ara òun jẹ́.

"Nígbà tí mo délé, níṣe ni àwọ̀ ara mi ń ṣí. A máa ń wọ aṣọ láti dá ààbò bo ara wa, aṣọ funfun tó máa bo gbogbo ara wa ṣùgbọ́n àwọn kẹ́míkà yìí ṣì máa ń wọnú ara wa.

Alabuga sọ pé àwọn máa ń pèsè àwọn ohun èlò ààbò fáwọn òṣìṣẹ́.

Apá èèyàn tó ṣàfihàn àbàwọ́n

Oríṣun àwòrán, Supplied to the BBC

Èyí sì nìkan kọ́ ni ewu tó wà níbẹ̀. Ní ọjọ́ Kejì,oṣù Kẹrin, 2024, ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí Adau balẹ̀ sí Russia, Ukraine ju àdó olóró sí iléeṣẹ́ Alabuga Special Economic Zone.

"Àláàmù iná ló jí mi, tí èyí sì yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Gbogbo gíláàsì tó wà lójú fèrèsé wa ti fọ́ sílẹ̀, ìbúgbàmù ni ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin náà jí sí."

Ó ní bí àwọn ṣe ń rìn kúrò níbi ilé ìgbé àwọn ni àwọn míì ń sáré.

"Mo ri tí àwọn kan ń nawọ́ sí òkè, nígbà tí mo wo ojú sánmọ̀, mo ri tí àdó olóró drone ó bọ̀ láti òkè, ìgbà yẹn ni èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí ní sáré."

BBC ṣe àyẹ̀wò fídíò tí Adau fi ránṣẹ́ lọ́jọ́ náà, tó sì jẹ́ ọjọ́ kan náà àti ibìkan náà tí Ukraine ṣe ìkọlù tó lágbára sí nígbà náà.

]Awọn èèyàn tí wọ́n wà nínú yìnyín, tí èéfí sì wà lẹ́yìn wọn

Oríṣun àwòrán, Supplied to the BBC

Àkọlé àwòrán, Àwọn àwòrán tí Adau yà lọ́jọ́ tí Ukraine ṣe ìkọlù sí ilé ìgbé wọn

"Ilé ìgbé tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ wa ni àdó olóró náà balẹ̀ sí. Gbogbo ilé náà ló dàwó, tó sì ṣe àkóbá fún ilé ti wa náà."

Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ ló padà mọ̀ pé iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe àdó olóró drone ni òun ti ń ṣiṣẹ́, tó sì wòye pé ìdí tí wọ́n ṣe ṣe ìkọlù sáwọn nìyẹn.

"Ukraine mọ̀ pé àwọn obìnrin ilẹ̀ Africa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ náà ń gbé ibi ilé tí wọ́n 'se ìkọlù sí. Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn Ukraine pé wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn aráàlú, wọ́n ní àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè àdó olóró nibẹ̀."

Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló kúrò níbi iṣẹ́ náà láì sọ pé àwọn fẹ́ kúrò lẹ́yìn ìkọlù náà èyí tó mú káwọn agbátẹrù iṣẹ́ náà gba ìwé ìrìnnà àwọn òṣìṣẹ́ fún ìgbà kan ná.

"Ọ̀pọ̀ àwọn ìròyìn òfégè nípa Russia láti mú kí Russia dàbí ìlú tí kò dára ló gbòde. Special Economic Zone ní àwọn òṣìṣẹ́ láti Europe àti America tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí gbogbo wọn fi iṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ogun Russia àti Ukraine bẹ̀rẹ̀.

Fún ìdí èyí, nígbà tí Russia bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àwọn èèyàn láti Africa láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó dàbí pé wọ́n ń lò ó láti fi ààyè táwọn ara Europe náà fi sílẹ̀."

Lẹ́yìn tí Adau kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀, àwọn ẹbí rẹ̀ ra tíkẹ́ẹ̀tì fun láti padà sílé ṣùgbọ́n tó ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni kò ní owó láti padà sílé pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé owó tí wọ́n ń gbà kéré jọjọ sí iye tí wọ́n polongo pé wọ́n máa gbà.

$600 ló yẹ kí Adau máa gbà ṣùgbọ́n $100 ni wọ́n ń fún – un.

"Wọ́n ń yọ owó ilé, owó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èdè Russia, Wi-Fi tí à ń lò, owó ọkọ̀ tí à ń wọ̀ lọ síbi iṣẹ́ àti owó orí. Bákan náà wọ́n ní tí a bá pa ibiṣẹ́ jẹ fún ọjọ́ kan, wọ́n máa yọ $50."

Alabuga sọ fún BBC pé owó oṣù àwọn èèyàn dá lórí bí wan bá ṣe ṣiṣẹ́ sí.

A bá obìnrin míì sọ̀rọ̀ lórí iléeṣẹ́ náà ṣùgbọ́n kò fẹ́ kí a dárúkọ òun, ó ní ìrírí òun ní iléeṣẹ́ Alabuga dára.

"Gbogbo iṣẹ́ ló ní òfin àti ìlànà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Báwo ni wọ́n ṣe máa san owó oṣù pípé fún èèyàn tí kò wá ibiṣẹ́ tàbí tí kò ṣiṣẹ́ dada?

"Gbogbo àwọn obìnrin tó ń fi iṣẹ́ sílẹ̀ ló jẹ́ pé wọn kò tẹ̀lé òfin iṣẹ́ tó dè wọ́n. Alabuga kìí de èèyàn mọ́lẹ̀, èèyàn lè kúrò nígbà tó bá wù wọ́n," obìnrin náà sọ fún BBC.

Àmọ́ Adau sọ pẹ ṣíṣe iṣẹ́ fún iléeṣẹ́ náà jẹ́ ohun tó burú jọjọ.

"Ó burú gidi. Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé tí mob á padà sí ibùgbé mi, mo máa ń sunkún ni. Mo rò ó pé mi ò gbàgbọ́ pé nǹkan tí mò ń ṣe nìyí. Ó jẹ́ ohun tó burú láti mọ̀ pé mo lọ́wọ́ nínú nǹkan tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn."