Onídìrí ọmọ Naijiria di irun fún wákàtí 24, gba àmì ẹ̀yẹ Guinness World Records

Aworan Mary Chinonso

Oríṣun àwòrán, Guinness Book of Records.

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Onidiri ọmọ orilẹede Naijiria kan, Mary Chinonso ti gba ami ẹyẹ Guinness World Record fun bi o ṣe dirun fun wakati mẹrinlelogun.

Ninu atẹjade ti GWR gbe sita, Chinonso bẹrẹ igbeṣe yii ni oṣu kẹta ọdun 2024 ninu Eko.

Gẹgẹ bii GWR se sọ, Mary ti fẹran lati ma dirun lati igba to ti wa ni kekere, to si lero lati fi erongba rẹ fi ṣe aṣeyọri ni ọjọ Iwaju.

Mary gbe igbesẹ yii ni agbegbe Lekki niluu Eko.

"Erongba mi lati fi ohun ti mo le ṣe han si agbaye," o sọ loju opo Instagram ṣaaju ko to bẹrẹ idije naa."

Kete to bẹrẹ idije naa, GWR ni Mary ko fi gbagba dawọ duro fun wakati mẹrinlelogun, to si ri daju pe oun fi ọwọ rẹ di irun awọn eeyan to gbe ori wọn kalẹ lati ṣe irun.

"Ni wakati mẹrin mẹrin, o n sin mi fun ogun isẹju, ti yoo si fi asiko naa jẹ ounjẹ diẹ, ko to di pe yoo pada si ẹnu iṣẹ, lati ba awọn eeyan se irun wọn.

"Ti awọn eeyan ba tig be irun wọle, Mary yoo kọkọ ba wọn fọ irun naa pẹlu ọsẹ ṣaaju ki wọn to bẹrẹ irun ni ṣiṣe

"Inu wa dun gan," Mary sọ loju ọpọ ayelujara lẹyin to gba ami ẹyẹ naa.

Ọpọ awọn ọrẹ, mọlẹbi ati awọn ololufẹ Mary ni wọn tu sori opo ayelujara lati ki ku orire naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post