Paul Biya ṣèlérí láti gbógun tìwà ìbàjẹ́ lẹ́yìn ìbúrawọlé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ orílẹ́èdè Cameroon fún sáà kẹ́jọ

Aarẹ Paul Biya nawọ mejeeji soke pẹlu idunnu nibi ayẹyẹ iburawọle gẹgẹ bii aarẹ Cameroon fun saa kẹjọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Paul Biya ti ṣeleri lati gbogun ti iwa ibajẹ ati lati ri i pe alaafia jọba pada kaakiri orilẹede Cameroon lẹyin iburawọle rẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede naa fun saa kẹjọ.

Rogbodiyan bẹ silẹ kaakiri orilẹede Cameroon lẹyin ti ajọ eleto idibo kede Biya ẹni ọdun mejilelaadọrun un gẹgẹ bii oludije to jawe olubori ninu eto idibo ọhun.

Ninu ọrọ to sọ lẹyin iburawọle rẹ, Aarẹ Biya ranṣẹ ibanikẹdun sawọn to fara kaasa ninu rogbodiyan to bẹ silẹ naa.

O ni awọn oloṣelu kan ni wọn wa nidi ifẹhonuhan tawọn araalu ṣe lẹyin idibo aarẹ to waye.

Nigba to n sọrọ lori ẹsun jibiti ati eeru tawọn kan fi kan ajọ eleto idibo lori eto idibo to waye, Biya ni eto idibo naa tẹ oun lọrun, o si gboriyin fun ajọ eleto idibo Elecam.

Ọpọ eeyan lo fẹsun kan ajọ eleto idibo Elecam fun kudiẹ-kudiẹ ti wọn lo wa ninu eto idibo aarẹ naa.

Eyi lo si jẹ kawọn eeyan bẹrẹ iwọde kaakiri orilẹede Cameroon lati fẹhonu han nibi ti eeyan mẹrinla ti padanu ẹmi wọn.

Eeyan to le ni 1,200 lawọn agbofinro fọwọ ṣinkun ofin mu gẹgẹ bii ajọ NHRC to n ja fun ẹtọ ọmọniyan ṣe ṣalaye.

Aarẹ Biya tun lu awọn ẹṣọ eleto abo lọgọ ẹnu fun bi wọn ṣe dẹkun fẹhonuhan to waye kaakiri orilẹede naa.

Amọ, aarẹ ko sọrọ lori ipa tawọn ẹṣọ eleto abo lo lori awọn olufẹhonuhan.

Biya sọ pe ni bayii ti eto idibo ti kọja lọ, asiko ti to fawọn araalu lati ṣiṣẹ pọ fun ilọsiwaju ati idagbasoke orilẹede Cameroon.

Aarẹ ṣeleri lati wa ojutuu si iṣoro to n koju awọn ọdọ atawọn obinrin.

Bakan naa ni o ṣeleri wi pe oun yoo gbogun ti iwa ajẹbanu ati eto abo to mẹhẹ

Biya di aarẹ Cameroon loṣu Kọkanla ọdun 1982 lẹyin ti Aarẹ Ahmadou Ahidjo kọwe fipo silẹ.

Awọn alatako ijọba rẹ sọ pe lati ọdun 1982 yii ni Biya ti n fi ọwọ lile ṣejọba orilẹede Cameroon.