Ṣé àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú lè ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, àti wí pé kí ló lè ṣokùnfà rẹ̀?
Ṣé àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú lè ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, àti wí pé kí ló lè ṣokùnfà rẹ̀?
Ẹjẹ rirujẹ aisan ti o gbajumọ pupọ kaakakiri agbaye nitori pe iye awọn to n ran lọ sọrun ko kere rara. Amọṣa bi aisan yii ṣe gbajumọ to yii ohun ti ọpọ mọ ni pe awọn agbalagba nikan lo n ṣe, paapaajulọ awọn ti ọjọ ori wọn ba ti wa ni ogoji ọdun tabi ju bẹẹ lọ.
Nibayii iwadi ijinlẹ ti fidi rẹ mulẹ pe rara o, aisan yii a tun maa ṣe awọn ọdọ naa pẹlu.
Koda aifura nipa ọṣẹ to n ṣe laarin awọn ọdọ ti mu ko ran ọpọ lọ sọrun laipeọjọ, eleyii to mu ki awọn kan bẹrẹ si ni fun un lorikọ 'apani jẹẹjẹ'.





