Ọkọ̀ rélùwéè kọlu kẹ̀kẹ́ Maruwa, òkú sùn

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Railway Corporation
Iṣẹlẹ ijamba kan waye ni agbegbe Dogon Karfe ni orita ti oju opo reluwe ati ọkọ ti pade arawọn niluu Jos.
Gẹgẹbi a ṣe gbọ, nigba ti ọkọ reluwe kan n pada bọ lati ilu Bukuru, lo kọlu kẹkẹ maruwa naa, ti eeyan meji si padanu ẹmi wọn lẹsẹkẹsẹ.
Bakan naa ni eeyan meji mi tun farapa yanayana lasiko ijamba naa.
Agbẹnusọ ajọ to n risi ọkọ reluwe lorilẹede Naijiria, ẹka ti Jos, Adamu Abdullahi, ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ Isẹgun nigba awakọ kẹkẹ maruwa n gbiyanju lati sa ere kọja ọkọ reluwe lẹyin ti wọn ki ni ọpọ ikilọ pe ko ma dan wo.
"Ọkọ reluwe wa n bọ lati ibukọ Bukuru, nigba to de si Dogon Karfe, ti yoo ti sọda, Kẹkẹ Maruwa kan ni ko ni suuru ki ọkọ reluwe naa kọja, to fi gbiyanju lati kọlu, ti ọkọ reluwe si gba danu," Abdullahi ṣalaye.
"Eeyan meji ku lẹsẹkẹsẹ, nigba ti eeyan meji si farapa yanayana, ti wọn si n gba itọju lọwọ ni ile iwosan bayii," o fikun.
O fikun pe awọn oṣiṣẹ ajọ NRC ma n wa ibudọ lati sọda yii lorekore lati ba awọn awakọ sọrọ ati lati dẹkun ijamba to ba fẹ waye.
Ẹwẹ, o ni awakọ to fa ijamba yii ni o lati gbọ imoran, to si tun kọ lati ni suuru fun ọkọ reluwe.
Awakọ kẹkẹ maruwa ati ọkunrin mii lo padanu ẹmi wọn,
Obinrin meji farapa yanayana, ti wọn si ti wa ni ile iwosan fun itọju.
Awọn alaṣẹ ti kesi awọn awakọ pe ki wọn ma ni suuru lasiko ti wọn ba ri ọkọ reluwe.















