Kókó tó wà nínú èsì Tinubu sọ́rọ̀ tí Trump sọ nípa Naijiria lórí ẹ̀sùn ìṣekúpani àwọn Kristẹni

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Aarẹ Bola Tinubu ti fesi sọrọ ti Donald Trump sọ wi pe Amẹrika yoo kogun ja awọn agbesunmọmi ''ti wọn n ṣeku pa awọn kristẹni'' ni Naijiria ti ijọba ko ba wa ojutuu si iṣoro naa.
Ninu ọrọ apilẹkọ to fi soju opo Facebook rẹ, Tinubu ni ''a ti n koju ipenija wa nipa biba awọn orilẹede to n ba Naijiria ṣiṣẹ pọ lagbaaye sọrọ lori ọna ti wọn yoo gba ran wa lọwọ.
A ko ni fi ibẹru ṣe ohun kan, pẹlu ipinnu gidi ni a fi n bawọn orilẹede agbaaye sọrọ lori a ti wa ojutuu si iṣoro igbesunmọmi to n koju wa.''
Tinubu ni ẹbi kan ni orilẹedee Naijiria jẹ, ''a jọ n goke papọ ni, a jọ n ni ilọsiwaju ni, a si tun jọ n bori iṣoro to ba koju wa ni.
Ọjọ iwaju wa dara, o si lagbara ju awọn nnkan to n dẹru bawa lọ.''
Tinubu sọ pe iṣẹ to si wa niwaju pọ ni tootọ, amọ, aarẹ ni Naijiria ṣetan lati ṣe iṣẹ naa.
Aarẹ ni ijọba oun ko ni kaarẹ lati fopin sawọn ọdaran to n da omi alaafia orilẹede Naijiria ru.
''A rọ awọn alabaṣiṣẹpọ wa kaakiri agbaaye lati ṣe atilẹyin fun wa bi a ti n gbogun ti awọn agbesunmọmi.
A ti ṣe awọn aṣeyọri kan ninu igbogun ti awọn agbesunmọmi, a o si tẹsewaju lati ri pe a ṣegun wọn patapata.
Ààrẹ Tinubu bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti béèrè fún ààbò àgbáyé
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, ti ni iṣejọba oun yoo mu ajọsepọ pẹlu awọn orilẹede agbaaye damọran si i ati fọwọ sowọ pọ si i lati koju awọn agbesunmọmi ati awọn iṣoro aabo mii ti orilẹede Naijiria n koju lọwọ yii.
Nigba to n sọrọ pẹlu awọn minisita rẹ niluu Abuja l'Ọjọbọ, Tinubu ni iṣejọba oun ko ni dẹyin ninu mimu alaafia jọba ati mimu idagbasoke bae to ọrọ aje.
O loootọ ni awọn iṣoro kan n kohu orilẹede Naijiria, o fikun pe, "A nilo lati gbe igbesẹ nla," ṣugbọn a ni lati tẹsiwaju pẹlu ifọwosowọpọ ati idi, lati gbe bori igbesunami ati lati le mu atunṣe nla ba orilẹede Naijiria.
Igba akọkọ ree ti Aarẹ Tinubu yoo sọrọ lẹyin ti Aarẹ Amẹrika, Donald Trump dunkoko lati ko ogun wọ orilẹede Naijiria, lori ẹsun pe Kristẹni nikan ni awọn agbebọn n ṣekupa.
Ọrọ yii ti Aarẹ Trump sọ ni Washington ti fa ọpọ rogbodiyan ninu Abuja. Ti awọn iroyin kan si sọ pe awọn ileeṣẹ ologun Amẹrika ti bẹrẹ si ni gbaradi fun ikọlu si orilẹede Naiiria.
Gẹgẹ bii The New York Times, Ẹka ileeṣẹ ologun Amẹrika to n risi Afrika, AFRICOM, ti gbe ọpọ ilana sita lori bi wọn yoo se kọlu agbegbe ti awọn agbebọn w ani orilẹede Naijiria, lẹyin ti Aarẹ Trump palaṣẹ fun wọn pe ki wọn mura ogun lati daabo bo awọn Kristẹni to n koju awọn ikọlu yii
Igbesẹ ni wọn kọkọ gbe sita lẹyin ti akọwe ẹka to n risi ogun, Pete Hagseth ni ki awọn ologun bẹrẹ iṣẹ lori aṣẹ ti Aarẹ Trump pa.
Orilẹede Naijiria ti n koju ọpọ iṣoro eto aabo fun igba pipẹ bayii, to fi mọ ikọlu lati ọdọ awọn alakatikti ẹṣin ni apa ariwa orilẹede naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ awọn orilẹede agbaye lo ti ṣe atilẹyin fun orilẹede Naijiria, Ajọ ECOWAS to n ri si eto ọrọaje lẹkun iwọ oorun Afirika ti sọ pe awọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ lẹkun ko fi ti ẹsin kankan ṣe.
Ajọ ECOWAS ni awọn ẹlẹsin musulumi atawọn ọmọlẹyin Kristi to fi mawọn ẹlẹsin mii lawọn agbesunmọmi n ṣeku pa lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika.















