Ó ti di èèwọ̀ láti máa ta ọtí pẹlẹbẹ inú ọ̀rá ní Naijiria – Ilé aṣòfin

Oríṣun àwòrán, Others
Ile igbimọ aṣofin ti paṣẹ fun ajọ to n ri si oogun ati ounjẹ ni Naijiria, NAFDAC, atawọn ajọ mii lati ri daju pe ẹnikẹni ko ta ọti inu ọra ni Naijiria mọ bẹrẹ lati inu oṣu Kejila ọdun 2025 yii.
Awọn aṣofin naa tun fẹnuko pe wọn ko ni fun awọn to n ta ọta ni aye mii lẹyin aṣẹ ti wọn pa yii.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti aṣofin Asuquo Ekpeyong ni ijọba ko gbọdọ fun awọn to n ta ọti inu ọra naa laye mii mọ lati ko kuro nilẹ.
Ekpeyong ninu awijare rẹ sọ pe NAFDAC ti kọkọ gbẹsẹle le pipo ọti naa ni Naijiia ati kiko wọle rẹ lati ilẹ okere.
O ni ọdun 2018 ni oniruru ajọ bii NAFDAC, Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC), Association of Food, Beverage & Tobacco Employers (AFBTE) ati Distillers and Blenders Association of Nigeria (DIBAN) tọwọ bọwe adehun ọlọdun maun un lori kiko ọti ọhun kuro nilẹ.
Adehun naa ni lati maa ko awọn ọti ọhun kuro nilẹ diẹdiẹ latari ewu to wa ninu mimu rẹ faraalu ati bo ṣe rọun fun awọn eeyan lati ra, paapaa awọn ọdọmọde.
Aṣofin ọhun tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe ijọba ti gbẹsẹle awọn ọti naa, o fun awọn to n ta a laaye lọdun 2024 ki wọn le ta awọn eyii to wa loi igba wọn tan, ninu eyii to fi fun wọn ni aye titi di ipari ọdun 2025.
O ni o ṣeni lanu pe bo tilẹ jẹ gbedeke ọjọ ti ijọba fun wọn ti n wọle de, awọn ileeṣẹ kan to n po awọn ọti naa n da ọgbọn ti ijọba yoo fi ṣe afikun iye gbedeke ọjọ to fun wọn, eyii to lewu fun araalu.
Ekpeyong jiyan pe titẹsiwaju lati maa po ọti inu ọra ni Naijiria yoo mu ki awọn ọdọ di ọmuti, yoo mu alekun ba ijamba oju popo, bi awọn tọkọtaya ṣe n na ara wọn ninu ile atawọn iwa ibajẹ mi.
Lẹyin ariyanjiyan awọn aṣofin naa, wọn fẹnuko pe ki ileeṣẹ eto ilera mu gbogbo idiwọ ti ko ni jẹ ki NAFDAC ṣe iṣẹ wọn kuro niwaju wọn.
Iwọnyin lawọn igba ti ijọba ti gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria
Oṣu kejila ọdun 2018 - Ọdun naa ni igba akọkọ ti ijọba atawọn oniruru ajọ buwọlu adehun latin fopin si pipo ọti ninu ọra, paapaa awọn ọti ti iwọn rẹ ko ju 200ml.
Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2024 – NAFDAC bẹrẹ si n ko awọn ọti naa lori igba lati le mu aṣẹ iwe adehun naa ṣe.
Oṣu keji si oṣu Kẹfa ọdun 2024 – Ile igbimọ aṣofin da si ọrọ naa wọn si rọ NAFDAC lati dawọ kiko rẹ kuro lori igba duro latari awọn ti yoo padanu owo ati iṣẹ wọn, paapaa ipa ti igbesẹ naa yoo ni lori ọrọ aje araalu to n ta a.
Oṣu Karun un, ọdun 2024 – NAFDAC gbẹsẹ kuro lori aṣẹ naa fun igba diẹ titi di ipari ọdun 2025 ki wọn le ṣe ipade pẹlu gbogbo awọn ti rọrọ naa kan.
Oṣu Kọkanla, ọdun 2025 – ile igbimọ aṣofin kan an nipa fun NAFDAC ko bẹrẹ aṣẹ naa ko si gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria lai fun awọn to n po o atawọn to n ta a n afikun gbendeke mii mọ.















