Ọmọ orílẹ̀èdè Mexico joyè Gbáwoníyì ní Ekiti, ó ní àṣà Yoruba kò gbọdọ̀ parun

Gomez, awọn mọlẹbi rẹ ati , Oore ilu Otun Ekiti, Oba Adekunle Adeagbo

Oríṣun àwòrán, Roundof News

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kabiesi, Oore ilu Otun Ekiti, Oba Adekunle Adeagbo, ti fi ọmọ orilẹede Mexico kan, Omowale Ifamosun Gomez jẹ oye Gbawoniyi ti Moba, niluu Otun Ekiti.

Gomez jẹ ọmọ orilẹede Mexixo to fẹran aṣa ilẹ Yoruba to tun jẹ Babalawo.

Ayẹyẹ iwuye naa lo waye nibi ọdun Ifa Aba ti ọdun 2025 to waye nillu Otun Ekiti.

Ọpọ awọn ọrẹ ati mọlẹbi lo tẹle Gomez lati ilu Miami, ipinlẹ Florida, nilẹ Amẹrika fun ayẹyẹ iwuye naa.

Ki ni idi ti wọn fi fun Gomez ni oye Gbawoniyi?

Gomez, awọn mọlẹbi rẹ ati , Oore ilu Otun Ekiti, Oba Adekunle Adeagbo

Oríṣun àwòrán, Roundoff News

Gẹgẹ bii ohun ti ori ade ti ilu Otun Ekiti sọ, wọn fi Gomez joye naa latari akitiyan rẹ lati gbe aṣa ilẹ Youba ga ati ki aṣa naa ma baa parun.

Nigba to n sọrọ, Ọba Adeagbo sọ pe gbigbe aṣa ẹni larugẹ ṣe pataki.

Lẹyin naa lo ke pe ijọba ipinlẹ Ekiti ati ijọba apapọ pe ki wọn gbe obitibiti owo kalẹ fun igbelarugẹ aṣa kaakiri Naijiria ki aṣa ma baa parun ati pe ṣiṣe bẹẹ tun le pa owo wọle fun ijọba.

Nigba ti Gomez n sọrọ, o dupẹ lọwọ Kabiesi naa fun bo ṣe ka oun yẹ fun oye ọhun.

Lẹyin naa lo ṣeleri lati tẹsiwaju lati maa gbe aṣa ilu Otun Ekiti larugẹ.

O pari ọrọ rẹ pe aṣa to dara ni aṣa Yoruba, awọn ọmọ Yoruba si gbọdọ ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri daju pe aṣa naa ko parẹ titi lai.