Bí Trump ṣe ń tún ilé ìjọba Amẹ́ríkà, White House ṣe sí àwòrán ohun tó fẹ́

Aarẹ kan n lọ omiran n de ṣugbọn ile ijọba ko rebi kan. O duro digbi bii agbara America ati ìṣe wọn-Ṣebi bẹẹ ni?
Loṣu to kọja, wọn wo apa kan ile iṣẹmbaye to ti wa nibẹ lati ọgọfa ọdun sẹyin naa, nigba ti Donald Trump pinnu lati kọ ile ijo tuntun to si ti bẹrẹ rẹ.
Bi wọn ṣe n wo o palẹ ni awọn ami to farahan nile naa tẹle, lapa Ila-Oorun rẹ n ba a lọ. O ṣafihan bi Trump ṣe n gbiyanju lati yi ile funfun naa pada ni aworan ara rẹ, bo ṣe n ku diẹ ko pe ọdun kan ti wọn dibo yan an sipo aarẹ.
Lara awọn to ti fi ero ọkan wọn han lori rẹ ni olori ẹka to n ri si itọju awọn nnkan iṣẹmbaye, National Trust for Historic Preservation, ajọ kan ti ki i ṣe ti ijọba, to wa fun aabo awọn ibudo itan l'America. Wọn kọwe si awọn alaṣẹ ile funfun ti i ṣe ile ijọba America, wọn ni ki wọn sinmi bi wọn ṣe n wo ile naa titi ti wọn yoo fi jẹ ki araalu da si i.
Dokita Carol Quillen, sọ pe ọrọ naa n kọ oun lominu gan-an. pe ile tuntun yii yoo gbe White House min, o si tun le ṣe bẹẹ ba awọn abala Ila ati Iwọ-Oorun ti wọn mọ ile naa fun jẹ titi lae.
Ṣugbọn lẹyin ọjọ diẹ ti Dokita Quillen fi iwe ero ọkan rẹ ranṣẹ , wọn wo apa Ila-Oorun ile naa.

Wọn ti ko awọn nnkan iṣẹmbaye ile naa lọ fun itọju ni White House Historical Association. ẹgbẹ kan to da duro, to si wa fun itọju itan ile ijọba
Ẹgbẹ naa sọ pe oun ṣe ayẹwo to yẹ, oun si ya awọn aworan to yẹ lorii wọn ki wọn too bẹrẹ si i wo ile naa.
Ṣugbọn awon aworan ibi ti wọn ti n fi irinṣẹ nla-nla wo ile ti wọn ti kọ lati 1902 naa n ya ọpọ ọmo America lẹnu, awọn mi-in paapaa n binu, nigba to jẹ Trump sọ fun wọn pe oun ko ni i yi ohun to wa nibẹ tẹlẹ pada ni.
Nigba to n kede abala ile ijo naa loṣu Keje

Lẹyin ti wọn bẹrẹ si i wo o, Trump sọ pe abala naa gbọdọ di wiwo, kawọn le ṣe e daadaa. O ni ipinnu naa waye lẹyin ikansi awọn agba abanikọle to daa ju lagbaaye''
Trump ni abala ile ijo yii naa jẹ kinni kan ti gbogbo aarẹ n fojusun lati ọdun 150 sẹyin, oun ni yoo si rẹwa ju ninu ile ijo lagbaaye.
Ijọba yii ṣo pe kikọ ile ijo naa yoo ṣegun kawọn maa ta atibaba nla bawọn ba ni ayẹyẹ bii apeje ọwọ alẹ , Ati pe olopo ile ijọba kan to jẹ agba ọjẹ ti sọ pe o maa n ṣoro gan-an fun awọn oṣiṣẹ
'Ko sẹni to fẹẹ sọ nipa abala yẹn, afi ti eeyan naa ba koju ẹrẹ funra rẹ''Martin Mongiellp, to n jẹ onpitan nile ijọba bayii lo sọ bẹẹ fun BBC." O le lagbara gan-an."

Afojusun Trump ni pe ile kikọ yii yoo na wọn to $300m, o si lero lati pari rẹ ki saa rẹ too pari. Wọn n kowo le e, bi Trump ṣe wi, o ni aarẹ funra rẹ pẹlu awọn ileeṣẹ rẹpẹtẹ ni wọn n kọ ile naa . Awọn bii Amazon, Google ati Meta, ati awọn olowo biliọnu olokoowo rẹpẹtẹ.
Bi wọn ṣe n kowo le e yii ni awọn onimọ nipa ofin kan ti koro oju si, wọn ni o le pada di ohun ti awọn eeyan yoo maa sanwo fun ki wọn too le lo o. Ṣugbọn ariwo tiwọn yẹn ko jọ pe o di Trump lọwọ, o kọju mọ bi yoo ṣe fi ipa rẹ lelẹ nile ijọba ni.
‘Akitan nla'
Ajọṣepọ Trump pẹlu 1,600 Pennysylvania Avenue naa ṣi n ruju. Ni saa akọkọ rẹ, wọn ni o pe ibẹ ni akitan gidi. O si maa n saba lọ si Mar-a-Lago, ile nla to kọ si etikun Palm, ni Florida.
Ni saa keji rẹ yii, iṣẹ nipa bi yoo ṣe sọ ibugbe awọn aarẹ yii di alaworan ara rẹ lo mu ni koko
Apẹẹrẹ akọkọ to fi han ni ti ọfiisi to ni ki wọn tunṣe si ko ṣe rogodo bii ẹyin. O yi i pada si gbagede goolu ati atunṣe awodami ẹnui
Ayipada ti ko ṣee fi we ara wọn lo wa ninu ohun to ba nilẹ lati ọwọ aarẹ iṣaaju, ati nigba toun naa ṣe saa akọkọ rẹ si asiko yii.





Trump ni awọn aworan ti wọn fi ṣe ẹwa yii jẹ goolu olowo iyebiye to ga ju, 24 -carat. O fi eyi yangan loju opo rẹ, ''Awọn olori ilẹ okeere ati gbogbo eeyan lo mọ nigba ti wọn ri ẹwa ati bo ṣe daa to. Eyi lo daa ju ninu ọfiisi ti a ba n sọ nipa aṣeyọri ati irisi.
Ṣugbọn gbogbo eeyan kọ lo jọ loju ṣaa. Tommy Landen Hueter, to n ṣiṣẹ mimu ile rẹwa ni New York, gbagbọ pe awọn otẹẹli ti olootu ile yii ti kọ tẹlẹ lo n dọgbọn sọ ile ijọba da.
'Gbogbo didan ati ọṣo ti wọn ko jọ yii ko yẹ ko wa nibẹ, wọn kan ko won sibi ti ko yẹ ki wọn wa ni". Ọgbẹni Hueter lo sọ bẹẹ fun BBC,o fi kun un pe wọn mọ-ọn-mọ yọ bi wọn ṣe n kọ ile ijọba America silẹ ni, lati fi han pe America ki i ṣe ilana ti ọlọba

Aworan to lọ lẹsẹẹsẹ lapa Iwọ-Oorun aarin ilẹ funfun, awọn aarẹ to ti jẹ ri ni wọn to aworan wọn lẹsẹẹsẹ bẹẹ, afi ti Joe Biden .
Kaka ki wọn gbe aworan alatako Trump sibẹ, gege ikọwe kan to le buwọlu nnkan funra rẹ ni wọn ṣe sinu atẹ aworan-wọn buwọ lu orukọ Biden sibẹ. Ṣaaju ni Trump ti fẹsun kan Biden pe o maa n lo gege to n kọ nnkan funra rẹ lati buwọ lu awọn iwe to ṣe pataki lasiko iṣejọba rẹ, o ni nitori Biden ko le da kọwọ bọwe funra rẹ ni, bo tilẹ jẹ pe Trump ko ri ẹri kankan fidi ẹsun rẹ yii mulẹ.

Irisi aaye naa labi ọgba Rose, eyi ti atunṣe to laami-laaka ti ba pẹlu ni nnkan bii oṣu meloo sẹyin. Tẹlẹ, ọgba kan to wa bẹẹ ni, o si ti le ni ọgọrun-un ọdun tawọn eeyan ti mọ si Ọgba Rose, lasiko ijọba aarẹ Hohn F Kennedy ni wọn tun un kọ fun ayẹyẹ ṣiṣe.
Wọn ti ṣe ipade awọn oniroyin nibẹ daadaa fun ọpọlọpọ ọdun, ti aarẹ yoo duro nibi pepele sọrọ, ti wọn yoo si to ọpọ aga jọ sorii koriko- ṣugbọn Trump ko fẹ iru eyi, o ni ''ohun to le mu awọn eeyan ṣubu sinu ẹrẹ̀ ni.''
Fun idi eyi, ko too di asiko ẹẹrun, wọn gbẹ ọgba naa, wọn si fi okuta funfun to ''rẹwa paarọ rẹ''


Asia ilẹ US kan to han daadaa ree ni ọgba Rose tuntun- Ọkan ninu awọn opo asia naa ti wọn ri loṣu Kẹfa, to ga ni iwọn ọgọrun-un kan (100ft (30.5m), aarẹ lo sanwo fun rírì wọn.
Ọpọ awọn oluwadii lori ayelujara ni wọn ti tọka si i pe ọgba tuntun yii jọ odo to wa ni Mar-a-Lago, wọn ni bi wọn ṣe kọ ọ latilẹ lo ti jọ ọ, ki i ṣe pe o ṣèṣì ri bẹẹ.
Atibaba alawọ pupa rẹsurẹṣu ati funfun to wa nibe, awọn ileeṣẹ to ṣe ti ile igbafẹ Trump ni Florida, pẹlu ile ijọba naa ni wọn ṣe e, wọn si ti sọ orukọ ibẹ ni ibi igbafẹ ọgba Rose.
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya inu rẹ dun si atunṣe yii, Trump sọ pe agbeyẹwo gidi lo ti waye lorii rẹ, lai sọ ọdọ ẹni to ti waye.

Njẹ Trump tun ni i lọkan lati ṣe awọn atunṣe si i nile ijọba?" Mi o ro bẹẹ" Akọwe iroyin, Karoline Leavitt lo sọ bẹẹ fun BBC. "Ṣugbọn olukọle ni Trump ninu ọkan rẹ. Fun idi eyi, ọkan ati ero rẹ maa n ṣiṣẹ lorii bi nnkan yoo ṣe daa si i ni''
‘Arc de Trump’
Bi ile atunkọ ile ijọba yii ba pari lẹyin ti wọn ba kọ ile ijo tan, Trump ti fi awọn òye kan lelẹ pe oun yoo ṣi maa kọ ilapa oun lọ nibomiran ni Washington DC.
Loṣu to kọja, o kede ipinnu rẹ lati kọ pepele kan kọja odo Potomac, lati ibi iranti Lincoln, ni Aarin-gbungbun olu ilu America, lati ṣe ayajọ iranti ọọdunrun-din -laadọta ọdun (250 years) ti ilẹ naa ti gba ominira lọdun to n bọ.


Ninu ọrọ to sọ nibi apejẹ kan pẹlu awọn ẹlẹyinju aanu ti yoo dawo fun iṣẹ akanṣe naa, Trump ni ipele mẹta ni wọn n gbe yẹwo - kekere, eyi to mọ niwọn ati eyi to tobi - amọṣa pe eyi to fẹ gbayawu loun fẹran julọ.
Ileeṣẹ Aarẹ Amẹrika ko tii gbe iroyin kankan jade lori igba ti atunkọ naa yoo bẹrẹ, tabi iye owo ti yoo na wọn, amọṣa Trump sọ pe awọn aladani ni yoo da owo fun kikọ rẹ.
Ko tii daju boya wọn yoo ti pari rẹ lasiko ayẹyẹ orikadun ti wọn fẹ ṣe lọdun 2026. Ohun to han gbangba ni pe bi o ti jẹ pe ọpọ awọn aarẹ Amẹrika lo ti gbiyanju lati ni ogun rere lẹyin ti wọn ba kuro nipo, ọna ti Trump n gba ni tirẹ ree
Iṣẹ ọna 3D model ti Matt Faraci, ṣe. Ẹkunrẹrẹ alaye nipa bi wọn yoo ṣe ṣe ile ijo naa ko ti i di mimọ lati ile ijọba bayii na. Awọn modẹli ti wọn ṣe yii naa, wọn lo awọn aworan ati alaye lori rẹ ni.
Katkıda bulunanlar:
Ile ijọba/ McCrery Architects, Eric Lee/Getty Images, AI Drago/Getty images, Aaron Sachwartz/CNP/Bloomberg, Mandel Ngan/AFP, Saul Loeb/AFP, Guido Bergmann/Bundesregierung, Ken Cedeno/Reuters, Stefani Reynolds/EPA/Shutterstock, Alex Wong/Getty images, Anna Moneymaker/ Getty Images, Alex Brandon/AP Photo/Bloomberg,Davidoff Studios/Getty Images, Jim Lo Scalzo/EPA/Bloomberg.




