INEC kéde Charles Soludo bíi gómìnà tuntun tí ìlú dìbò yàn ní Anambra

Oríṣun àwòrán, Charles Soludo/Facebook
Gomina Charles Soludo to ń soju ẹgbẹ́ òṣèlú APGA lọ gbé igbá oroke nínú àwọn èsì ìbò gómìnà ni ìpínlẹ̀ Anambra.
Bi ẹ kò ba gbagbe, ana ọjọ́ Satide ni ajọ elétò ìdìbò nílẹ̀ wa ṣètò ìdìbò gómìnà nipinlẹ Anambra laarin awọn olùdíje mejidinlogun.
Lara awọn olùdíje gómìnà náà ni Gomina to ń darí ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ lọ́wọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Soludo, to ń soju ẹgbẹ́ òṣèlú APGA.
Soludo fi ẹ̀yìn àwọn olùdíje yókù janlẹ̀ - INEC
Ninu esi ibo gomina tí àjọ elétò ìdìbò, INEC, kede rẹ, gomina Soludo sì lo ń gbé igbá oroke.
INEC kéde pé apapọ èsì ìbò tí Soludo, lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ní idà èsì ibo 72.4%.
Oludije fẹ́gbẹ́ òṣèlú APC, Nicholas Ukachukwu ni ìdá èsì ìbò 17%.
Oludije fún ẹgbẹ́ òṣèlú YPP, George Moghalu ni ìdá èsì ìbò 1.8%.
Oludije fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, LP, Jude Ezenwafor ni ida Esi ibo 0.2%.
Bi ajọ elétò ìdìbò sì ṣe ń ka èsì ìbò náà, ní wọ́n ń kéde rẹ fún aráyé.
Ibo gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra náà sì ni ìdìbò àkọ́kọ́ tí àjọ INEC, lábẹ́ adari alaga tuntun, Ọjọgbọn Charles Amupitan yóò ṣètò rẹ.

Oríṣun àwòrán, SOLUDO/UKACHUKWU/EZENWAFOR/MOGHALU/FACEBOOK
Ṣáájú là tí mú ìròyìn wá fún yín pé ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹjọ oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni idibo si ipo gomina n waye nipinlẹ Anambra, ni Guusu-Ila-Oorun Naijiria.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Gomina Chukwuma Soludo lo n dari ipinlẹ Anambra lọwọlọwọ.
Lapapọ, eeyan mejidinlogun lo n du ipo gomina naa bayii, titi kan Gomina Soludo funra rẹ, ẹni to n fẹẹ lọ fun saa keji.
Nitori ibo naa, awọn agbofinro ti balẹ biba si Anambra, lati ri i pe ko si rogbodiyan ṣiwaju, lasiko ibo ati lẹyin ti wọn ba dibo naa tan.
Wọnyi lawọn ohun to yẹ ki o mọ nipa awọn oludije ibo naa ati ẹgbẹ oṣelu wọn ati bi ohun gbogbo ṣe n lọ l'Anambra.
Charles Soludo (APGA)

Oríṣun àwòrán, Gov. Chukwuma Soludo/ Facebook
Gomina Chukwuma Charles Soludo ni gomina adiboyan karun-un ti wọn yan nipinlẹ Anambra, saa keji rẹ lo n lọ fun bayii.
Soludo ni oludije ti ẹgbẹ oṣelu APGA fa kalẹ lasiko idibo abẹle ẹgbẹ naa, ko ni alatako kankan.
Ko too wọnu oṣelu, Chukwuma Soludo jẹ onimọ nipa ọrọ aje ati oṣiṣẹ banki, o si di gomina banki agba ilẹ wa.
Bakan naa lo ti di ipo alaga igbimọ banki apapọ ilẹ wa mu ri.
Ọdun 1960 ni wọn ni Chukwuma Soludo, ni Isuofia nijọba ibilẹ Aguata, ipinlẹ Anambra.
Nonye Soludo ni iyawo rẹ n jẹ, wọn si bi ọmọ mẹfa.
Lọwọlọwọ yii, Soludo nikan ni gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APGA.
Dr Nicholas Ukachukwu (APC)

Oríṣun àwòrán, Nicholas Ukachukwu/Facebook
Nicholas Ukachukwu ni ondije ti yoo ṣoju APC lonii nipinlẹ Anambra.
Ogunjọ oṣu Kẹta ọdun 1967 ni wọn bi I ni Osumenyi, nijọba Guusu ijọba ibilẹ Nnewi.
Oniṣowo pataki nipa epo rọbi ati afẹfẹ idana ni Nicholas Ukachukwu, o tun n ṣowo abanikọle ati ọgbin, o si tun ni awọn ẹka okoowo miran pẹlu.
Ukachukwu gboye ninu imọ okoowo ni University of Calabar, o si tun kawe ni Tensian University, l'Anambra .
O ti ṣe alaga ijọba ibilẹ l'Abuja ri.
Jude Ezenwafor (PDP)

Oríṣun àwòrán, Jude Ezenwafor/ Facebook
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP l'Anambra ni Jude Ezenwafo.
Ọkunrin yii lo da nikan ra fọọmu ologoji miliọnu naira to fi dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP.
Ilu Abuja ni Ezenwafo fi ṣebugbe, nibi to ti n ṣowo abanikọle.
Nipa oṣelu, o ti di ipo Igbakeji aarẹ mu ri ninu ẹgbẹ Nigerian Youth Congress.
Ẹni ọdun marundinlaadọta (45) ni.
Ni 2007, Jude dupo gomina Anambra ninu ẹgbẹ Labour, o si ti dupo senetọ naa ri ninu PDP.
Ilu Nnobi, nijọba ibilẹ Guusu Idemili, l'Anambra ni wọn ti bi Jude Ezenwafo.
Àwọn olùdíje yókù ni:
Onyeeze Chidi Charles – Accord Party (A)
Nweke Ezechukwu Japhet – Action Alliance (AA)
Ifemeludike Chioma Grace – Africa Action Congress (AAC)
Nwosu Chima John – African Democratic Congress (ADC)
Otti Cyprain Echezona – Allied Peoples Movement (APM)
Nweke Chrispopher Chukwudubem – Action Peoples Party (APP)
Okeke Chika Jerry – Boot Party (BP)
Moghalu George Nnadubem Labour Party (LP)
Onyejegbu Geoffrey – New Nigeria Peoples Party (NNPP)
Ndidi Christy Olieh – National Rescue Movement (NRM)
Chukwurah Vincent – Social Democratuc Party (SDP)
Chukwuma Paul Chukwuka – Young Progressives Party (YPP)
Ugwoji Uchenna Martin – Zenith Labour Party (ZLP)
Ko din ni eeyan 2.8m ti ireti wa pe yoo dibo lonii
Bi akọsilẹ ati iforukọ silẹ awọn oludibo nipinlẹ Anambra ṣe fi han, ko din ni oludibo 2,802,790 to fi orukọ silẹ kaakiri ijọba ibilẹ mọkanlelogun to wa nibẹ.
Ti ireti si wa pe wọn yoo dibo kaakiri Anambra.
Nipa lilọ bibọ ọkọ, awọn ọlọpaa sọ pe ko ni i si lilọ bibọ laaarin aago mẹfa aarọ si mẹfa irọlẹ ti idibo naa yoo fi waye.
Aago mẹjọ aabọ aarọ ni ireti wa pe yiyẹ orukọ wo ati ibo didi yoo bẹrẹ, yoo si pari ni aago meji aabọ ọsan.
Leyin eyi ni kika esi ibo yoo bẹrẹ.
Bakan naa ni ajọ INEC ti sọ pe gbogbo eelo to nilo fun idibo naa yoo de ibudo idibo bo ṣe yẹ
Alaga INEC, Joash Amupitan, fi awọn eeyan Anambra lọkan balẹ, o ni ajọ naa yoo ṣeto idibo to ṣee gbagbọ, to si kun fun otitọ.
Tẹ o ba gbagbe, Joash Amupitan ni Alaga INEC tuntun ti Aarẹ Tinubu yan loṣu Kẹwaa ọdun 2025, eyi si ni akọkọ iṣẹ rẹ ti yoo ṣe nipo naa.














