Púpọ̀ nínú ọọ́físì ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo ló ti dagẹgẹ, Makinde gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe si – Àwọn àṣofin

Seyi Makinde nibi eto ijọba kan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti ke si gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde lati ṣatunṣe si awọn ọọfisi ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ ọhun latari pe wọn ti dagẹgẹ.

Wọn ni ki Makinde ṣe atunṣe awọn ọọfisi naa ki iṣẹ awọn oṣiṣẹ rẹ le maa lọ dede.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu aba kan ti Akintunde Olajide to n ṣoju ẹkun Lagelu da ninu ile ọhun.

Olajide sọ pe o yẹ ki ijọba tete da si atunṣe awọn ọọfisi naa ko to pẹ ju ki ijamba ma baa waye si awọn to n ṣiṣẹ ninu rẹ.

Aṣofin naa, to jẹ alaga igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ sọ pe pupọ ninu awọn ọọfisi to wa lawọn ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Oyo ni ko ṣe e lo mọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ipo ti awọn ọọfisi ijọba ibilẹ ọhun wa ti mu ko ṣoro lati maa ṣisẹ nibẹ.

O ni "Awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ ninu awọn ọọfisi yii ni ẹmi wọn wa ninu ewu nigba ti awọn araalu to n yọju sibẹ n farada ọpọ inira latari bi awọn ọọfisi ọhun ṣe ri."

Olajide tẹsiwaju pe ṣiṣe atunṣẹ awọn ọọfisi naa yoo mu ki ijọba tunbọ sunmọ awọn araalu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ṣiṣẹ atunṣe awọn ọọfisi ọhun yoo mu ki iṣẹ lọ dede nibẹ.

Lẹyin naa lo rọ ijọba ipinlẹ ọhun ko bẹrẹ iwadii lori awọn ọọfisi naa pẹlu ajọṣepọ igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ.

O sọ siwaju si pe awọn ileeṣẹ aladani gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ibilẹ naa ki iṣẹ ọhun le ṣeeṣe.

Wọn tun fi akoko naa rọ ijọba lati gbe owo gọbọi silẹ fun iṣẹ naa ninu eto iṣuna ipinlẹ ọhun.