Ọlọ́pàà yin tajútajú sáwọn olùwọ́de tó ń pè fún ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu l'Abuja, ẹni orí yọ ó dilé

Awọn oluwọde to n beere fun utusilẹ Nnamdi Kanu atawọn ọlọpaa to n yin tajutaju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, lo ṣaaju awọn oluwọde naa bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ikilọ sita ṣaaju ifẹhonuhan ọhun.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ di boo lọ ya n mi nigba tawọn ẹṣọ eleto abo yin tajutaju sawọn oluwode to n pe fun itusilẹ ajijagbara fun ominira orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu, l'Abuja laaarọ oni ọjọ Aje.

Ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, lo ṣaaju awọn oluwọde naa bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ikilọ sita ṣaaju ifẹhonuhan ọhun.

''Ẹ fi Nnamdi Kanu silẹ,'' ''ẹtọ wa ni lati ṣe ifẹhonuhan,'' ''ẹ ma yin tajutaju si wa,'' lawọn oluwọde naa n sọ kawọn ọlọpaa to yin tajutaju lati tu wọn ka.

Bawọn ọlọpaa ṣe yin tajutaju ọhun lawọn oluwọde kan n sọ pe ''tajutaju ko le da wa duro'' bi wọn ti n salọ.

Iwọde #FreeNnamdiKanuNow bẹrẹ lẹgbẹẹ ile itura Transcorp Hilton, o si ran lọ de awọn agbegbe mii niluu Abuja.

Awọn ọlọpaa tete de sawọn ibi tawọn olufẹhonuhan ti ko ara wọn jọ, wọn si tu wọn ka pẹlu tajutaju.

Wamu wamu lawọn ẹṣọ eleto abo duro sawọn opopona to lọ si ileeṣẹ ijọba ni Aso Rock.

Bakan naa lawọn ẹṣọ eleto abo duro wamu wamu si gbagede Eagle Square, Unity Fountain ati Three Arms Zone tawọn oluwọde le kora jọ pọ si niluu Abuja.

Ẹwẹ, ṣaaju ni Sowore ti sọ lori eto ''The Morning Brief'' lori Channels TV pe awọn to ṣagbatẹru iwọde naa ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Sowore ni awọn ọlọpaa ti mu awọn olufẹhonuhan kan, wọn si ti fi ipa ko wọn sinu ọkọ.

O bu ẹnu ẹtẹ lu bi ijọba ti fi Kanu si atimọle fun ọjọ pipẹ, Sowore ni ijọba apapọ n mọọ mọ tako idajọ ododo lori ọrọ naa ni.

Ifẹhonuhan #FreeNnamdiKanuNow tako aṣẹ adajọ Mohammed Umar ti ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja to ni wọn o gbọdọ ṣe ifẹhonuhan lagbegbe ileeṣẹ ijọba ni Aso Rock, ile igbimọ aṣofin agba, olu ileeṣẹ ọlọpaa l'Abuja atawọn agbegbe mii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ kilọ fawọn olufẹhonuhan lati bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ, bi bẹẹ kọọ, wọn o foju wina ofin.

Amọ, Sowore ni ki lo de ti ileeṣẹ ọlọpaa ko fi mu awọn olufẹhonuhan tako itusilẹ Kanu nigba ti ko si bi ọbọ ti ṣe ori ti inaki o ṣe.

Sowore ni agbẹjọro 115 lo ti wa nilẹ lati tako aṣẹ ti ile ẹjọ pa ọhun.