Ṣé lóòòtọ́ọ́ ni ìjìyà wà fún ẹnikẹ́ni tó bá fún obìnrin lóyún láì ṣètọ́jú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, getty/lasg
Iroyin kan to ti tan kaakiri ori ayelujara bayii lo sọ ipinlẹ Eko ti ṣe agbekalẹ ofin kan eyi ti yoo maa fiya jẹ ẹnikẹni to ba fun obinrin loyun lai ṣe itọju rẹ.
Iroyin naa sọ pe ofin yii ri iru iwa bẹẹ gẹgẹ bii iwa ọdaran.
Gẹgẹ bi iroyin ọhun ti ṣalaye, ofin naa ti mu un ni dandan fun ẹnikẹni to ba fun obinrin loyun bayii nipinlẹ Eko lati ṣe itọju iru obinrin bẹẹ.
Iroyin naa ni ẹni to ba fun obinrin ti ki i ṣe iyawo rẹ loyun ti iru ọkunrin bẹẹ ba si kọ lati tọju ẹni to fun loyun, o ti di dandan labẹ ofin nipinlẹ Eko fun un lati pese ounjẹ, ileegbe to fi mọ sisan owo lilọ sile iwosan ti obinrin naa yoo fi bimọ.
Iroyin ọhun fidi rẹ mulẹ pe abala 277 ofin ọdaran ipinlẹ Eko sọ pe ẹnikẹni to ba kọ lati tọju obinrin to ba fun loyun ti huwa ọdaran.
Ijiya fun iru ẹni bẹẹ si ni wi pe yoo san faini ẹgbẹrun marundinlaadọta naira, yoo si tun sanwo itọju oloyun naa nile iwosan.
Iroyin ọhun tun sọ pe ijọba ipinlẹ Eko ṣe agbekalẹ ofin yii latari bi ọpọ ọkunrin ṣe fawọn obinrin loyun lai ṣe itọju wọn.
Ọpọ awọn ẹgbẹ obinrin lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu iru iwa yii ti ọpọ ọdọkunrin n hu.
Ẹnikẹni to ba ru ofin yii yoo sanwo itọju obinrin naa to ba tun bimọ tan ati ọmọ to bi pẹlu.
Ile ẹjọ lagbara lati mu ni dandan fun ẹnikẹni to ba ru ofin lati ṣe itọju obinrin to ba fun loyun titi yoo fi bi ọmọ inu rẹ.
Ile ẹjọ tun le kede ijiya mii fun iru ẹni bẹ to ba kọ lati pa aṣẹ ile ẹjọ mọ.
O tun wa ninu iroyin naa wi pe ẹnikẹni to ba fẹ sọ nnkankan fun ijọba lori ọrọ yii le kan si ileeṣẹ ijọba to n ri ọrọ eto idajọ nipasẹ ọọfiisi ajọ ajafẹtọọ araalu, OPD pẹlu adirẹsi imeeli yii - [email protected].
Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn eeyan le pe sori ẹrọ ibanisọrọ pẹlu nọmba yii -07080601080
Koda, iroyin naa tun sọ pe ipinlẹ Eko nikan ni ofin yii wa lọwọ yii lorilẹede Naijiria.
''Iroyin ofege lo ni ijọba ti fofin de awọn to n fun obinrin loyun lai ṣe itọju wọn''
Ewẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe iroyin ofege lo ni ìjọba ti ṣe agbekalẹ ofin ti yoo maa fiya jẹ ẹnikẹni to ba fun obinrin loyun lai ṣe itọju rẹ.
Iléeṣẹ́ ijọba to n ri si eto ìdájọ lo fi ọrọ naa sori ikanni agbọrọkaye wọn pe irọ to jina si ootọ ni iroyin ọhun.
"Awọn eeyan ti pe akiyesi wa si iroyin kan to n tan kalẹ lori ayelujara wi pe ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ṣofin kan ti yoo maa da ṣeria fun ẹnikẹni to ba fun obinrin ti kii ṣe iyawo loyun lai tọju.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko nipasẹ ẹka eto ìdájọ n fi asiko sọ pe a o mọ nkankan nipa iroyin yii.
Nitori naa, a fẹ ki ẹ mọ pe ayederu iroyin to le ṣi araalu lọna ni," ẹka eto idajọ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot














