Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo sọ̀rọ̀ lórí lẹ́tà DSS nípa ìkọlù tí ISWAP fẹ́ ṣe sí Owo àti Akoko

Oríṣun àwòrán, Ebenezer Adeniyan
Ijoba ipinlẹ Ondo ti sọrọ lori lẹta ti ajọ DSS kọ sileeṣẹ ọmọ ogun nibi to ti kilọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP n mura lati kọlu ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin, Idowu Ajanaku fi lede, o ni ijọba ti mọ nipa ikilọ naa, o si ti n gbe igbese lati daabo awọn araalu.
Ijọba ni lẹta ọhun, bo tilẹ jẹ pe ko yẹ ko lu sita si araalu, jẹ ọkan lara awọn iwe ti awọn eleto abo maa n kọ laarin ara wọn ati ijọba.
O ni ninu irufẹ lẹta yii ni wọn ti maa n ṣi ara wọn ni gbẹrẹ ipakọ lọna ati pese abo to peye faraalu.
Kọmiṣọna naa ni "A fẹ ki gbogbo araalu mọ pe ijọba atawọn ileeṣẹ agbofinro n ṣiṣẹ lori iroyin yii lati daabo bo araalu.
"Ohun to ṣe pataki ni ajọṣepọ to dan mọran laarin awọn agbofinro ati ijọba lati tete fesi si kudiẹ-kudiẹ eto abo wa."
Lẹyin naa lo rọ araalu ki wọn ki wọn maṣẹ paya amọ ki wọn tete maa ṣi awọn agbofinro ni gbẹrẹ ipakọ ni gbogbo igba ti wọn ba fura si ohun ajeji kankan layika wọn.
O pari ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Ondo ko kawọ gbera, o si n ṣe ohun gbogbo yẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu nitori naa ki wọn lọ fi ọkan wọn balẹ.
DSS kọ̀wé ìkìlọ̀ nípa ìkọlù ẹgbẹ́ agbébọn ISWAP ní Owo, àtàwọn ìlúù míràn l'Ondo, aráàlú ń sá kíjikíjo

Oríṣun àwòrán, @eonsintelligence
Ibẹrubojo ti gba ọkan ọpọ eeyan niluu Ọwọ ati agbegbe Akoko nipinlẹ Ondo bayii lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijira, DSS, kilọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State of West Africa Province (ISWAP), ti n mura lati kọlu awọn agbegbe naa laipẹ.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu lẹta kan ti ajọ naa fi ṣọwọ si ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ondo, iyẹn 32 Artilery Brigade, nilu Akure.
Gẹgẹ bii ohun to wa ninu lẹta naa ti DSS kọ logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ti a wa yii, awọn agbesunmọmi naa yoo kọlu ọpọlọpọ agbegbe nipinlẹ Kogi ati Ondo.
Lara awọn agbegbe ti DSS tọka si pe awọn agbesunmọmi naa n gbero lati kọlu ni Ondo ni Eriti Akoko ati Oyin Akoko lagbegbe Akoko, nigba ti wọn tun n mura lati kọlu ilu Ọwọ, ni ijọba ibilẹ Ọwọ.
DSS ni awọn ọdaran naa ti bẹrẹ itọpinpin awọn agbegbe ti wọn yoo kọlu lawọn ilu ọhun, o si rọ ileeṣẹ ọmọ ogun lati bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.
Lẹta naa sọ pe "iwadii idankọnkọ wa fi han pe awọn ọmọ egbẹ ISWAP fẹ kọlu awọn ilu kan nipinlẹ Ondo ati Kogi laipẹ.
"A fẹ ki ẹ mu eto abo lọkunkundun lawọn agbegbe wọnyii lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu."
Ni bayii, ọpọ araalu ni wọn ti wa ninu ibẹrubojo fun ẹmi wọn nipinlẹ Ondo bayii, paapaa niluu Owo ati lagbegbe Akoko.

Oríṣun àwòrán, DSS
Kii ṣe igba akọkọ ree ti agbesunmọmi yoo kọlu ilu Owo

Oríṣun àwòrán, Ondo State Police Command
Ti ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti agbesunmọmi yoo kọlu ilu Owo, ipinlẹ Ondo ti wọn yoo si gbẹmi ọpọ eeyan.
Lọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, awọn agbebọn kan yabo ile ijọsin St. Francis Catholic Church, Owo, nibi ti wọn ti gbẹmi eeyan to le ni ogoji, ti ọpọ awọn mii si farapa yanayana.
Awọn marun un ti ọwọ tẹ lori ikọlu ọhun ṣi n jẹjọ lọwọ bayii niluu Abuja amọ wọn sọ fun adajọ pe awọn ko jẹbi ẹsun igbesunmọmi ti ajọ DSS fi kan awọn.
Ẹwẹ, BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, SP Ayanlade Olayinka sọ pe awọn naa ti ri lẹta ọhun.
Ṣaaju ki lẹta DSS yii to gba ori ayelujara kan ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti ṣabẹwo si agbege akoko nibi ti kọmiṣọna ọlọpaa, Adebowale Lawal ti ṣe ipade eto abo pẹlu awọn eeyan Ikare ati Iwaro-Oka Akoko.
Gẹgẹ bii atẹjade ọlọpaa, eredi ipade naa ko ṣẹyin bi ibaṣẹpe to dan mọran yoo ṣe waye laarin ọlọpaa ati araalu fun eto abo to peye nipinlẹ Ondo.















