Taa ni Sanae Takaichi, olóṣèlú obìnrin bíi ọkunrin Japan?

Adari ẹgbẹ Liberal Democratic Party (LDP) ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Sanae Takaichi lọdun2025 nTokyo, Japan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Tinshui Yeung
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Sanae Takaichi ti bori ibo lọjọ Iṣẹgun lati di olootu ijọba obinrin akọkọ ni Japan.

Ṣaaju akoko yii lo ti kọkọ ṣiṣẹ gẹgẹ bii minisita, sọrọsọrọ ori ẹrọ amohunmaworan, o tun ti fi akoko igba kan jẹ ẹni to n lu ilu lẹyin olorin metal ri.

Lara iṣọro ti Takaichi yoo koju ni ẹpọn agbo ọrọ aje orilẹede naa to n mi titi atawọn nnkan mii.

Ijọba rẹ yoo tun bojuto ibaṣepọ ijọba Japan ati Amẹrica, yoo si gbiyanju lati yanju aawọ owo ori tuntun ti Trump ati ijọba ana fẹnuko le lori.

Nara Prefecture ni wọn bi obinrin naa si lọdun 1961, baba rẹ jẹ oṣiṣẹ ijọba nigba ti iya rẹ jẹ ọlọpaa.

Kii ṣe ẹni to gbọnju ba oṣelu lati kekere.

O gbajumọ lasiko to n lu ilu lẹyin olori metal latari bo ṣe maa n kan igi lasiko to ba n lu ilu kikankikan.

O jẹ ẹni to fẹran ati maa wẹ lọ si isalẹ okun ati ololufẹ ọkọ, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Supra rẹ nigba kan ri ti wa ninu musiọmu ilu Nara bayii.

Sanae Takaichi ninu ọọfisi ẹgbẹ oṣelu LDP lasiko ibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ko to darapọ mọ oṣelu, Takaichi ṣiṣẹ fun akoko diẹ gẹgẹ bii sọrọsọrọ ori ẹrọ amohunmaworan.

Laarin ọdun 1980 lo bẹrẹ oṣelu, iyẹn lasiko ariyanjiyan eto ọrọ aje aarin orilẹede Japan ati Amẹrika.

Ninu igbiyanju rẹ lati mọ oju ti awọn eeyan Amẹrika fi n wo awọn eeyan Japan, o ṣiṣẹ ni ọọfisi Patricia Schroeder, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat to n maa tako orilẹede Japan.

Nibẹ lo ti ri pe awọn eeyan Amẹrika ko mọ iyatọ laarin ọmọ Japan, China ati South Korea.

Nibẹ lo ti pinnu pe ọwọ Japan ni atunṣe Japan wa, bi bẹẹ kọ, oju mii ni Amẹrika yoo ma fi wo o.

O dije sipo aṣofin lọdun 1992 gẹgẹ bii oludije ti ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kankan amọ o lulẹ.

Amọ ko sọ ireti nu, lọdun to tẹle o dije, o si bori ko to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu LDP lọdun 1996.

Lẹyin naa, igba mẹwaa ọtọtọ ni wọn ti dibo yan an sipo aṣofin bo tilẹ jẹ pe o lulẹ lẹẹkan ṣoṣo.

O ti di oniruru ipo oṣelu mu bii ipo minisita fun ọrọ aje ati abo, minisita abẹle fun ọrọ aje to fi mọ minisita fun ọrọ abele ati ibaraẹnisọrọ.

Lọdun 2021, o dije du ipo adari ẹgbẹ LDP amọ Fumio Kishida fidi rẹ janlẹ. O tun gbiyanju si lọdun 2024 ṣugbọn o padanu ipo naa sọwọ Shigeru Ishiba.

Ọdun yii lo gbiyanju nigba kẹta ko to bori.

O sọ nibi ipade pẹlu awọn ọmọ kan pe "afojusun mi ni lati di obinrin bii ọkunrin."

Shinzo Abe pẹlu awọn minisita mii niluu Tokyo

Oríṣun àwòrán, Bloomberg via Getty Images

Gẹgẹ bii ẹni to n wo awokọṣe Shinzo Abe, Takaichi ti ṣeleri pe ijọba ko ni ya owo ti ele rẹ pọju.

Lara awọn nnkan to gbagbọ ninu rẹ ni pe obinrin to ba ti lọ sile ọkọ gbọdọ maa jẹ orukọ ọkọ rẹ dipo orukọ baba rẹ.

O tun lodi si igbeyao ati ibaṣepọ laarin akọ si akọ ati abo si abo.

O maa n pe ara rẹ ni Margaret Thatcher orilẹede Japan.

Amọ ṣa, ọjọgbọn Jeff Kingston, ni Temple University ilu Tokyo sọ fun BBC pe ẹnu lasan lo n le nitori pe oun ko tii ri ironilagbara kankan to ṣe fun awọn obinrin Japan.

Awọn oloṣelu Japan lasiko abẹwo wọn si ojubọ Yasukuni

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin ọhun n gbiyanju lati ṣe awọn eto ironilagbara kan fun awọn obinrin, paapaa nipa eto ilera ati iṣẹ oojọ wọn.

Awọn to mu ọmu lara rẹ julọ ni awọn to n tọju ọmọde.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iriri oun funra oun lo tunbọ jẹ ki ọrọ wọn jẹ oun logun.

O ni "igba mẹta ọtọtọ ni mo ti tọju ọmọ laye mi…. nitori naa ni mo ṣe pinnu lati ṣatilẹyin fun awọn eeyan ki wọn ma baa fi iṣẹ wọn silẹ nitori itọju ọmọ.

Lọpọ igba lo maa n ṣabẹwo si ojubọ Yasukuni, nibi ti wọn ti n bu iyi fun awọn to ku lasiko ogun Japan, atawọn mii ti wọn gba idajọ ẹwọn lasiko ogun.