"Ẹbí mi mẹ́jọ ló kú níbi ìjàmbá tánkà to gbiná ní Niger," ariwo sọ nibi ìsìnkú èèyàn 42 tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Tanka agbepo to n jona loju lẹgbẹ oju popo

Oríṣun àwòrán, @NEMANigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ibanujẹ dori agba kodo nibi isinku awọn eeyan to ba ijamba tanka epo to gbina nipinlẹ Niger lọ.

Mallam Surajo Muhammad Shehu ṣalaye fun iwe iroyin Daily Trust pe ẹbi oun mẹjọ lo ku ninu ijamba ọkọ epo tanka naa lọjọ Iṣẹgun lopopona Agaie si Bida ni ijọba ibilẹ Katch nipinlẹ Niger.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe o ti le logoji eeyan ti obinrin atawọn ọmọde pọ ninu wọn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ bayii.

Ni nnkan bi ago meji ọsan lọjọ Iṣẹgun ni tanka ọhun ṣubu latari ọna to ti bajẹ.

Oṣojumi-koro kan ṣalaye pe obinrin kan pẹlu ọmọ lẹyin rẹ wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Wọn ni obinrin naa doju bolẹ pẹlu ọmọ lẹyin rẹ nibi tawọn majeeji jona si.

Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye, wọn ni iya ati ọmọ naa n kigbe oro ki wọn to pada ku ninu ijamba ina ọhun.

A gbọ wi pe awọn mii sare kuro pẹlu lara wọn ki wọn to pada ṣubu.

Mallam Shehu pẹlu omije loju sọ fun Daily Trust wi pe iṣẹlẹ manigbagbe ni ijamba tanka epo to gbina ọhun jẹ ni ilu awọn.

Shehu ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn araalu ti ko gbọ ikilọ lo ba iṣẹlẹ naa lọ, tori olori ilu kilọ ṣaaju wi pe ẹnikẹni ko gbọdọ lọ gbọn epo nibi ti tanka naa ṣubu si.

''Ọpọ eeyan lo bẹrẹ si ni gbọn epo ki wọn le maa ta a lati ri owo ni kiakia, lai na-an ni ewu to wa nibẹ.

Ẹbi mi mẹjọ lo ku ninu ijamba naa, nigba ti awọn mẹwaa mii wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ ọrun nile iwosan bayii.

A ti sinku ẹgbọn mi obinrin, Hawawu Dauda, to wa lara awọn to ku, nigba tawọn ọmọbinrin rẹ mẹta n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Awọn obinrin lo pọju ninu awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ tori ọpọ awọn ọkunrin ti lọ soko nigba ti tanka naa ṣubu.

Awọn obinrin lo lọ sibẹ lati lọ gbọn epo,'' Shehu ṣalaye.

Shehu ni iyalẹnu lo jẹ foun wi pe awọn eeyan kọ eti ikun si ikilọ wi pe ki wọn ma gbọn epo to n jo danu lati inu tanka to ṣubu tori ewu to wa nibẹ.

Iru ijamba yii naa ṣẹlẹ ni abule kan ti ko jina sibi ti tanka ti ṣubu yii lọjọ Iṣẹgun lọdun 2024 nibi ti eeyan mọkanlelọgọta ti padanu ẹmi wọn.

Ijọba ipinlẹ Niger ti sin awọn to ku nibi iṣẹ tanka epo to gbina papọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Niger ti sin oku awọn eeyan to ba ijamba tanka to ṣubu lopopona Bida si Agaie papọ.

Ijọba tun kede wi pe oun yoo san owo itọju awọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa nile iwosan.

Bologi Ibrahim to jẹ akọwe iroyin gomina ipinlẹ Niger lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Ni Katcha ni wọn ti sin awọn eeyan to ku nibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si gbadura wi pe ki Eledua tẹ wọn si afẹfẹ arere.

Ijọba ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe eeyan bii aadọta to farapa nibi iṣẹlẹ naa lo n gba itọju lọwọ nile iwosan FMC, Bida tabi ile iwosan ijọba General Hospital niluu Bida.

Bakan naa ni a gbọ pe wọn ti gbe awọn to farapa pupọ lọ si ile iwosan National Hospital l'Abuja fun itọju to peye.

Ijọba tun sọ pe oogun towo rẹ to N10,000,000 loun ti ra fawọn ile iwosan to n tọju awọn eeyan naa.

Ijọba fikun ọrọ rẹ pe oun tun ti ṣe iranwọ owo fun ẹbi awọn eeyan to n gba itọju nile iwosan.

Ijọba ipinlẹ Niger wa rọ araalu wi pe ki wọn ye gbọn epon mọ nigba kugba ti tanka agbepo ba ṣubu tori ewu to pọ to rọ mọ iru iṣẹlẹ yii.

Èèyàn tó lé ní 30 jóná kú níbi tí wọ́n ti ń gbọ́n epo níbi táńkà tó gbiná
Aworan tanka epo to n jona

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Tanka epo to n jona

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti i sẹni to le fidi iye eeyan to ti dagbare faye ninu ijamba tanka epo to gbina lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii nipinlẹ Niger, mulẹ.

Yatọ si awọn to di oloogbe, ti wọn jona kọja idanimọ, o tun le ni ogoji eeyan ti ina ọhun jo gidi ti wọn si ti farapa yanna-yanna, gẹgẹ bi awọn to ṣọju wọn ṣe sọ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, nnkan bii aago mọkanla alẹ ni ijamba ina yii ṣẹlẹ, lagbegbe Essan ati Badeggi, eyi to wa loju ọna Bida-Agaie, ijọba ibilẹ Katcha,ipinlẹ Niger.

Oju ọna ti ko daa lo jẹ ki tanka epo naa ṣubu to si fi ẹgbẹ le lẹ, ti epo inu rẹ si bẹrẹ si i danu.

Ṣugbọn ki i ṣe ẹsẹkẹsẹ naa ni ina sọ bi awọn o ṣoju mi koro ṣe wi.

Kí ló fa iná ajónirun?

Alaye awọn eeyan ti ijamba naa ṣoju wọn ni pe bi tanka agbepo ọhun ṣe ṣubu ni awọn eeyan kan bẹrẹ si i gbọn epo to n danu.

Nibi ti wọn ti n gbọn epo naa ni ina nla ti ṣẹyọ, ina naa lo si jo eeyan ti a gbọ pe o to ogoji run bayii, ti awọn mi-in si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alaga ẹgbẹ awakọ tanka epo ati gaasi nipinlẹ Niger, Kọmureedi Farouk Kawo, ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bii eyi to buru jai to si ṣee dena.

Gẹgẹ bo ṣe wi, epo bẹntiroolu ni tanka to danu yii n gbe bọ lati ilu Eko, o n lọ si Oke Ọya.

Kọmureedi Kawo sọ pe ijamba tanka epo to ti le ni ọgbọn (30) lo ti waye loju ọna Bida–Agaie loṣu Kẹwaa nikan, ọna ti ko daa lo si n fa ijamba naa bo ṣe sọ.

Bakan naa lo koro oju si awọn ọdọ to maa n sare lọ gbọn epo bi tanka ba ti ṣubu.

Kawo ṣalaye bi tanka to gbe ororo ẹpa ṣe ṣubu loju ọna yii kan naa ni ọjọ Aiku to kọja, awọn ara agbegbe naa si tu jade, wọn n gbọn ororo naa.

O ni gbogbo eyi ko tọna, ohun to si n fa iku rẹpẹtẹ lọpọ igba niyẹn.

Àwọn ìjàmbá táńkà epo tó ti mu ẹ̀mí lọ ní Naijiria

Ki tanka epo danu, ki araalu maa sare lọ gbọn epo ko ṣẹṣẹ bẹrẹ lorilẹede Naijiria.

Ọpọ igba to ba si ti ṣẹlẹ bẹẹ naa ni ọpọ ẹmi maa n ba a lọ, ṣugbọn iku naa ki i kọ awọn mi-in lọgbọn, wọn yoo tun gbọn epo bi tanka ba ti ṣubu ni.

Wọ̀nyí ni àwọn ijamba tanka epo to ṣẹlẹ laipẹ ní Naijiria

  • Niger: Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2025

Tanka epo kan to gbe bẹntiroolu to to ẹgbẹrun lọna ọgọta (60,000) ṣubu ni ikorita Suleja, ipinlẹ Niger, awọn eeyan si bẹrẹ si i gbọn epo.

O kere tan, eeyan ọgọrun-un (100) jona ku, awọn mọkandinlaadọrin (69) si farapa gidi.

  • Enugu: Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdún 2025:

Ko din ni eeyan mọkanla to padanu ẹmi lọjọ yii, nigba ti tanka to n gbe epo loji ọna Ugwu-Onyeama, marosẹ Enugu-Onitsha si Onitsha gbina lori ìrìn lẹyin to padanu ijanu rẹ.

  • Niger: Ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, 2025:

Eeyan merinla jona ku nigba ti tanka agbepo fori sọ bọọsi akero lagbegbe Kusobogi, Aarin-Gbungbun ipinlẹ Niger.

  • Abuja: Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta 2025:

Ko si onka pato to fidi iye eeyan to ku nibi iṣẹlẹ yii han, idi si ni pe awọn ọkọ ti ina ti ara wọn ran mọ mọto miran pọ gan-an.

Oju ọna Abuja-Nyanya-Keffi ni tanka epo ti gbina, lori afara Karu gangan ni lọjọ naa.

Ọwọ irọlẹ ti awọn oṣiṣẹ n lọ sile ni ijamba yii waye, eyi jẹ ki ọkọ to le ni ọgbọn (30) jona, ti awọn eeyan to n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi wọn si tun ba a lọ.

  • Eko: Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta 2025:

Ọkọ tanka kan to gbe afẹfẹ gaasi gbina lori afara Otedola, nitosi CMD, ti ko jinna si Ketu.

Ọpọ ẹmi lo ba iṣẹlẹ yii naa lọ, pẹlu bi akọsilẹ iye eeyan to ku ko ṣe jọra wọn.

Ọpọ dukia lo tun bajẹ, awon to kan si rawọ ẹbẹ sijọba lati ṣaanu awọn.

  • Jigawa :Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024:

Tanka epo danu lagbegbe Majiya, ipinle Jigawa. Eeyan 206 lo jona ku, awọn 124 si fara kona gidi.