Kí nìdí tí ìjọba Adeleke ṣe fi Davido ṣe aláàmójútó àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó àti nǹkan tí yóò ṣe fún àjọ náà?

Oríṣun àwòrán, Instagram/Davido
Ijọba ipinlẹ Osun ti ṣalaye idi ti wọn fi yan David Adeleke, ẹni ti ọpọ mọ si Davido gẹgẹ bii alaamojuto asuwọn ẹdawo ere idaraya nipinlẹ Osun.
Ikede yii jade ni Ọjọ kejidinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2025 nigba ti igbakeji gomina ipinlẹ Osun, Ọmọọba Kola Adewusi, n gba alejo ẹgbẹ awọn akọroyin ere idaraya nipinlẹ Osun.
Nigba to n ba BBC News Yoruba, agbẹnusọ Gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed ni yatọ si pe Davido jẹ ọmọ ẹgbọn gomina ipinlẹ Osun, o tun jẹ eeyan to ajọsepọ nla pẹlu awọn ileeṣẹ nlanla lagbaye ti wọn le pese owo fun idagbasoke ere idaraya nipinlẹ Osun.
Rasheed ni ohun akọkọ ti ijọba ro ti wọn fẹ fi da asuwọn owo naa silẹ ni lati ṣe atunṣe si paapa iṣere ipinlẹ Osun ti yoo fi ba ẹgbẹ pe lawujọ.
"Lati gba ere idaraya larugẹ ki n ṣe ti ijọba nikan le ṣe, nitori owo nla nla lo ma n wa nidi rẹ, lati sise paapa iṣere ati awọn itọju awọn elere idaraya, ti a si nilo awọn aladani lati wa fọwọsowọpọ pẹlu wa.
"Eyi ki n ṣe ẹru ti ijọba nikan le da gba,ṣugbọn bayii awọn aladani le dasi iṣẹ ijọba, to si ran wa lọwọ pupọ."
Rasheed ni ijọba yoo pese ilana ati ofin ti yoo dirọ owo ẹdawo naa lori bi owo yoo ṣe wọlw ati bi yoo ṣe jade pẹlu akọsilẹ.
"Ki n se ẹdawo ti ko ni ofin ni eyi, owo yoo wa, ti yoo si da bobo owo ti awọn ba da ni wọn fi ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.
Davido ko ni gba owo oṣu fun iṣẹ yii, o wa sin ilu ni
Agbẹunusọ Gomina, Olawale Rasheed ni idi pato ti awọn fi kan si Davido ni pe yoo pese ọpọ iranlọwọ lati ri pe ẹdawo wa si imuṣẹ.
Rasheed ni yiyan Davido gẹgẹ bii alaga ni o da bi pe wọn ke si i pe ko ṣe aanu awọn araalu gẹgẹ bii o ti ṣe n ṣe tẹlẹ.
"Ko se eyi nitori owo, olowo ni Davido, to tun jẹ ọmọ baba olowo, ọdọdun ni o fun awọn ọmọ orukan ni owo.
"Ilumọka ni Davido ti yoo si lo ipo rẹ fi pese anfani fun ere idaraya nipinlẹ Osun ati fun awọn ọdọ naa."
Gómìnà Adeleke yan Davido sípò aláàmójútó àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó ìdàgbàsókè eré ìdárayá

Oríṣun àwòrán, Instagram/Osun State Govt
Ijọba ipinlẹ Osun ti kede gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke, ẹni ti ọpọ mọ si Davido gẹgẹ bii alaga àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó ìdàgbàsókè eré ìdárayá, igbesẹ ti wọn ni yoo pese owo fun idagbasoke ẹka ere idaraya ni ipinlẹ naa.
Ijọba tun jẹ ko di mimọ pe igbesẹ n lọ lati pari atunṣe to n lọ lọwọ ni paapa iṣere to wa ni ilu Osogbo, pẹlu erongba lati jẹ ko jẹ lilo fun idije Olympics.
Igbakeji Gomina ipinlẹ Osun, Kola Adewusi, lo sọ eyi di mimọ nigba ti ẹgbẹ awọn akọroyin ere idaraya, ẹka ti ipinlẹ Osun, (SWAN) ṣe abẹwo si ọfisi rẹ, igbakeji gomina, ẹni to tun jẹ Kọmisana fun ere idaraya nipinlẹ naa, tẹnumọ pe iṣejọba Gomina Ademola Adeleke n ṣe akitiyan lati mu atunṣe nla ba papa iṣere ilu Osogbo lati le ba ẹgbẹ pe lagbaye.
Adewusi fi kun pe ijọba ipinlẹ naa ti n ipele aṣekagba lati da ajọ ere idaraya ti yoo wa fun idagbasoke ere idaraya nipinlẹ Osun.
O ni ni awọn se fẹ sẹda ajọ ni yoo pese iranlọwọ fun ere idaraya nipinlẹ Osun ati bii yoo ṣe gboro si.
"Inu mi dun lati sọ fun iyin pe a ti wa ni ipele aṣekagba lati da ajọ ere idaraya ipinlẹ Osun silẹ.
"Idasilẹ àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó ìdàgbàsókè eré ìdárayá yii yoo jẹ ki a ri iranlọwọ gba kaakiri, ti ere idaraya yoo si ma gboro si nipinlẹ Osun.
"Davido ko yi ohun pada lati gba pe ko di alaga ajọ naa, ti yoo si ri pe iranlọwọ wa kaakiri agbaye."
Ta ni David Adeleke ti ọpọ eeyan mọ si Davido?
Ọmọbibi ilu Ede nipinlẹ Osun ni David Adeleke, ta tun mọ si Davido.
Ọjọ Kọkanlelogun osu Kọkanla ọdun 1992 si lo dele aye lati ipasẹ baba rẹ, Adedeji Adeleke amọ iya rẹ ti jade laye.
Isẹ orin kikọ ni lo yan laayo, gbajumọ akọrin takansufe si ni Davido lorilẹede Naijiria ati lawujọ agbaye lapapọ.
Ọdun 2010 si lo bẹrẹ isẹ orin kikọ, eyiun ọdun mejila sẹyin.
Lara awọn orin rẹ to gbajugbaja julọ ni 'Ẹ ma da mi duro, emi lọmọ baba olowo ati orin Assurance to fi sọri Chioma.
Davido ti gba ọpọ ami ẹyẹ nidi isẹ orin kikọ labẹle ati loke okun.















