Kí ló mú Nnamdi Kanu, olórí ẹgbẹ́ Ipob da àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ nù lẹ́yìn tó dárúkọ Sanwo-Olu, Malami àtàwọn míì gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí rẹ̀ nílé ẹjọ́?

Nnamdi Kanu nile ẹjọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olori ẹgbẹ Ipob to n jijagbara fun ominira ilẹ Biafra, Nnamdi Kanu ti jawe ẹ lọ gbele fun gbogbo awọn agbẹjọro rẹ, o si ti kede pe oun funra oun ni yoo ṣoju ara oun niwaju adajọ.

Kanu lo sọrọ naa nile ẹjoọ lasiko igbẹjọ ẹsun igbesunmọmi ti ijọba apapọ Naijiria fi kan an.

Bi igbẹjọ rẹ ṣe n bẹrẹ ni pẹrẹwu lonii, olori awọn agbẹjọro rẹ, Kanu Agabi (SAN) kede pe oun ko ni ṣoju rẹ mọ.

Agabi ni yatọ si oun, awọn agbeọjẹ agbẹjọro mii bii Onyechi Ikpeazu, Emeka Etiaba, Nunghe Mela Audu, Paul Erokoro, Uchenna Njoku atawọn mii lo n dẹyin lẹyin Kanu.

Adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, James Omotosho ni oun ti gba ẹbẹ awọn agbẹjọro naa wọle.

Nigba ti adajọ bere lọwọ rẹ pe "ta ni agbẹjọro rẹ bayii" Kanu da lohun pe "emi funra mi ni mo maa ṣe agbẹjọro ara mi.

Lẹyin naa ni adajọ ọhun paṣẹ fun gbogbo awọn agbẹjọro rẹ, yatọ si awọn ti wọn jẹ SAN ki wọn fi yara ile ẹjọ naa silẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni ijọba Naijiria ti kọkọ pe ẹlẹrii marun un lati tako Kanu ti gbogbo wọn si jẹ oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.

Lara wọn lawọn to kọkọ fi pampẹ ofin mu lọdun 2015, to fi mọ awọn to ṣewadii ipa to ko ninu iwọde EndSARS to waye lọdun 2020.

Kanu pe Sanwo-Olu, Malami, Buratai atawọn mii gẹgẹ bii ẹlẹrii

Kanu atawón agbẹjọro rẹ nile ẹjọ Abuja
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, iroyin ti a n gbọ ni pe Kanu ti pe awọn oloṣelu atawọn olori kan ni Naijiria gẹgẹ bii ẹlẹrii oun ninu igbẹjọ rẹ to n lọ lọwọ.

Lara awọn ti Kanu ni wọn yoo wa rojọ gẹgẹ bii ẹlẹrii niwaju adajọ ni adajọ agba Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami; olori ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria tẹlẹ, Tukur Buratai, minisita eto abo tẹlẹ, Theophilus Danjuma, gomina ipinlẹ Eko ati Imo; Babajide Sanwo-Olu ati Hope Uzodinma, yatọ si awọn mii.

Nigba ti akọroyin wa bere lọwọ agbẹjọro rẹ eredi to fi darukọ awọn eeyan wọnyii gẹgẹ bii ẹlẹrii, o ni Kanu ṣe bẹẹ nitori ẹjọ naa kan awọn eeyan ọhun, orukọ wọn si ti jade lasiko ti ẹjọ naa bẹrẹ.

Fun apẹrẹ, agbẹjoro naa ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe Abubakar Malami ti fi akoko igba kan kọwe si DSS ri pe ki wọn ṣe ọfintoto Kanu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Buratai ni olori ileeṣẹ ọmọ ogun lọdun 2017 ti awọn sọja kan ya bo ile Kanu to wa ni Afaraukwu, niluu Umuahia, ipinlẹ Abia, eyii to mu ko na papa bora lẹyin beeli ti ile ẹjọ fun ṣaaju asiko naa.