Bó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn fífipá bọ́mọdé lò pọ̀, gbére lẹ̀wọ̀n rẹ! Àwọn ìjìyà tuntun tí ilé aṣòfin àgbà buwọ́lù rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile igbimọ aṣofin agba orilẹede Naijiria ti buwọlu ijiya ẹwọn gbere ti ko ni sisan owo itanran ninu fun ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun fifi ipa ba ọmọde lo pọ.
Igbesẹ naa waye lati gbogun ti iwa ifipa ba ọmọde lo pọ to ti n wọpọ bayii ni Naijiria.
Ikede yii waye lasiko ijokoo ile nibi ti Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Godswill Akpabio, ti ṣalaye pe iyato wa laaarin iwa fifi ipa ba obinrin lo pọ ati fifipa ba ọmọde lo pọ.
Igbesẹ yii wa lara awọn atunṣe ti ile igbimọ aṣofin agba n ṣe sawọn ofin lori iwa ọdaran, eyi ti ile aṣoju-ṣofin naa n ṣiṣẹ le lori bakan naa.
Sẹnẹtọ Opeyemi Bamidele to lewaju nibi ijiroro naa sọ pe atunṣe ofin yii yoo fopin si iwa idẹyẹsi ninu igbẹjọ ifipabanilopọ.
Ẹni to ba fipa ja abale eeyan ti wọn maa n dajọ ẹwọn ọdun marun un fun un tẹlẹ, yoo maa gba idajọ ẹwọn gbere bayii.
Aarẹ ile ni ẹsun to ba ti jẹ mọ ọmọde nilo ijiya nla.
"Fifi pa ba ọmọde lopọ yẹ ko yatọ si fifi ipa ba obinrin lopọ, awọn to ba se iru eyi nilo ijiya nla."
Nigba ti Akpabio ni ki gbogbo ile da si ọrọ naa, Sẹnẹtọ Adamu Aliero, mu imọran wa pe o kere ju ogun ọdun ni ẹnikẹni ti o ba jẹbi ẹsun ifipa bọmọde lo pọ maa lo lẹwọn, ti iru ẹni bẹẹ ko si gbọdọ ni anfani si owo itanran sisan.
Sẹnẹtọ Sunday Adeleke ni tiẹ pe fun ẹgbẹ gbere, to si ṣe apẹẹrẹ awọn orilẹede bii India ati Pakistan ti wọn ẹsun pẹlu ọwọ nla.
Lẹyin ọpọ ijiroro, ile igbimọ aṣofin agba gba aba naa wọle, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe eyikeyi obinrin tabi ọkunrin ti wọn ba ka pẹlu ẹsun fifi ipa ba ọmọde lo pọ ni ijiya rẹ yoo maa jẹ ẹwọn gbere, ti ko si ni si anfani sisan faini.
Awọn aṣofin ni awọn n gbe igbesẹ yii lati daabo bo ẹtọ awọn ọmọde lorilẹede Naijiria ati lati fi opin si iwa fifi ipa ba awọn ọmọde lo pọ to wọpọ ni awujọ.
Aarẹ Ile igbimọ aṣofin ṣapejuwe igbesẹ yii gẹgẹ bi ọna lati da idajọ ododo pada si orilẹede Naijiria.















