Ọkàn lára ọmọ ìjọ ló fún mi ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ṣùgbọ́n ń kò rántí rẹ̀ - Pásítọ̀ tí ọwọ́ tẹ̀ pé ó ṣekú pa Princewill Igbonaju

Oloogbe ṣaaju iku rẹ

Oríṣun àwòrán, Ernest Onyeka Igbonaju

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Cross River ti ṣeleri idajọ ododo lori iku Princewill Igbonaju lẹyin ti aburo rẹ, Ernest Onyeka Igbonaju ke gbajare lori ayelujara.

Inu oṣu Kẹsan an ọdun yii ni Ernest Ignonaju ke si ijọba ipinlẹ Cross River ati ẹka eto idajọ ipinlẹ naa lẹyin iku ọta ibọn lati ọwọ awọn pasitọ kan lọdun 2022 ti pasitọ ọhun si n yan fanda kiri igboro.

Bi iku Princewill Igbonaju ṣe waye

Nigba ti aburo rẹ n ṣalaye bi iṣẹlẹ iku ẹgbọn rẹ ṣe waye, o ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrin, ọsu Kẹsan an ọdun 2023 ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti ẹgbọn oun, Princewill Igbonaju Ikenna lọ gẹ irun rẹ, eyii to jẹ igba ikẹyin ti oun ri.

Lọjọ Aiku to tẹle ọjọ naa, wọn lọ ile ijọsin amọ oloogbe ko si ni ṣọọṣi eyii to mu ki iya rẹ lọ ile rẹ lati bere rẹ latari pe kii pa ile ijọsin jẹ, amọ awọn alabagbe rẹ ni ko sun ile mọju.

Lẹyin naa ni wọn lọ fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ti ọlọpaa si sọ pe ki wọn duro wakati mẹrinlelogun ki wọn to pada wa.

Nigba ti yoo di nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aje, wọn gba ipe kan pe ki wọn wa si ori papa kan lati ṣayẹwo oku kan.

O ni "nigba ti a maa fi de ibẹ, ẹgbọn mi lo wa nibẹ ninu agbara ẹjẹ pẹlu ọta ibọn mẹta lori rẹ.

"Wọn gba ọkọ ayọkẹlẹ Lexus RX 350 rẹ, ọrọ naa si jẹ kayeefi fun wa."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, lara awọn nọmba iwe ọkọ oloogbe ọhun ni wọn ti tọpinpin ọkọ naa de ilu Eko pẹlu ẹrọ 'tracker."

Nigba ti wọn yoo fi tọpinpin ọkọ naa de ilu Eko, ile ẹni to n ṣe jorinmọrin ọkọ ni wọn ti ba Lexus ọhun ti wọn ti n kun ọda mii si lara.

Eyii lo mu ki wọn fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ni agọ wọn to wa ni Meiran ti ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Inspector Martha si tẹlẹ wọn lọ ọdọ jorinmọrin ọhun.

"Ẹ ṣe mi jẹjẹ, pasitọ lo gbe iṣẹ fun mi"

Videod ti Ernest Onyeka Igbonaju lati bere idajọ ododo lori iku ẹgbọn rẹ

Oríṣun àwòrán, Ernest Onyeka Igbonaju

Nigba ti ọlọpaa mu jorinmọrin naa, o ni pasitọ kan, Peter Uchenna, lo gbe iṣẹ fun oun, ọlọpaa tun mu pasitọ naa.

Pasitọ sọ fun ọlọpaa pe ọkan lara awọn ọmọ ijọ lo fun oun ni ọkọ naa gẹgẹ bii ẹbun ṣugbọn o ni oun ko ranti ẹni to fun oun ni ọkọ ọhun mọ nitori ọpọlọpọ ẹbun loun maa n gba lọwọ oniruru eeyan.

Ọlọpaa sọ fun pe "bo o ba tilẹ jẹ Aarẹ gan, yoo ṣoro lati gbagbe ẹni to fun ọ ni odidi ọkọ ayọkẹlẹ."

Lẹyin naa ni wọn sọ fun pe wọn ti yinbọn pa ẹni to ni ọkọ niluu Ikom, to wa ni Cross River, amọ pasitọ ọhun ni oun ko tii fi ẹsẹ tẹ ilu naa ri nile aye oun.

Nigba ti ọlọpaa maa fi ọrọ wa iyawo pasitọ lẹnu wo, iyawo pasitọ sọ pe ọkọ oun lọ waasu niluu Ikom lọjọ gan ti iṣẹlẹ naa waye.

Lẹyinorẹyin, ọlọpaa tare ọrọ naa lọ si agọ rẹ to wa ni Panti nibi ti wọn ti maa n ṣewadii iwa ọdaran.

"A maa ri daju pe idajọ ododo waye"

Wayi o, ẹni to ṣoju adajọ agba ipinlẹ Rivers, Anthony Okon Effiom, ti ṣeleri pe ijọba ipinlẹ naa yoo ri daju pe ọrọ naa ko ku regbe ku regbe.

O ni iwaadi oun ti fi han pe wọn ti gbe ọrọ naa lọ si kootu kan nile ẹjọ giga ipinlẹ ọhun.

O pari ọrọ rẹ pe gbogbo awọn to ba lọwọ ninu iku oloogbe naa ni ko ni lọ lai foju wina ofin ijọba.