Ọmọ ọdún 17 yọ ojú àbúrò rẹ̀ obìnrin fi ṣe òògùn owó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti tẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun, Auwalu Muhammad, fun ẹsun pe o yọ oju aburo rẹ obinrin lati fi ṣe ogun owo ni abule Wailo, ni ijọba ibilẹ Ganjuwa.
Iṣẹlẹ ọhun to waye ni ọjọ kẹtadinlogun Oṣu Kẹwaa, sọ Rukayya Muhammad di ẹni ti ko le ri iran mọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Bauchi, CSP Ahmed Wakil, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ṣapejuwe iṣẹlẹ iwa ọdaju.
Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe afurasi naa tan aburo rẹ lọ si ẹgbẹ igbo, nibi to ti kọlu, to si fi tipatipa yọ oju rẹ mejeeji pẹlu ireti lati fi ṣe ogun owo.
"O ṣeni laanu pe dokita ni ile iwosan fidi rẹ mulẹ pe oju ọmọ naa ti fọ pata, ti ko si le rina mọ," Wakil ṣalaye.
O fikun pe afurasi naa jẹwọ ẹsun lasiko ti wọn n ba sọrọ, ti iwadii si n lọ lọwọ lati ṣawari awọn akẹgbẹ rẹ ninu isẹ ibi yii.
Wakil ni ọwọ tun tẹ awọn afurasi mii ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Awọn ni Auwal Dahiru (17) of Bayan Dutse, Wailo; Mohammed Rabiu (19); Saleh Ibrahim (20); Nasiru Muhammad, Hassan Garba, ati Garba Dahiru (43), ti gbogbo wọn wa lati ilu Soro town ni ijọba ibilẹ Ganjuwa
"Gbogbo awọn afurasi wa ni ahamọ bayii, ti iwadii si n lọ lọwọ lati ri pe idajọ ododo waye ," agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye.















