Ṣé lóòótọ́ nìjọba Seyi Makinde bẹ́rẹ́ owó orí gbígbá lórí ayẹyẹ ìsìnkú, ìsọmọlórúkọ, ìgbéyàwó àtàwọn ayẹyẹ míràn l'Oyo?

Aworan Gomina Seyi Makinde to n sọrọ sinu ẹrọ gboungboun ati aworan iwe ti wọn kọ owo naa si

Oríṣun àwòrán, Seyimakinde/x/screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ninu oṣu kẹsan-an ọdun yii ni iroyin kan lu sita wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ bẹrẹ sini gba owo ori lori gbogbo awọn to ba fẹ ṣe ayẹyẹ ati ipejọpọ mii n'ipinlẹ Ọyọ.

Atẹjade kan ti awọn eeyan n pin kaakiri ori ayelujara lorukọ ẹni kan ti wọn pe ni Họnọrebu Adelabu Tunde tọka rẹ wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede agbekalẹ owo ori fun ẹnikẹni to ba fẹ ṣe wẹjẹ-wẹmu ati inawo n'ipinlẹ naa.

Nibi ipejọpọ kan to waye ni gbọngan igbalejo 'Western Hall' to n bẹ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ni wọn ni wọn ti sọ ọrọ naa ki Adelabu Tunde tun to fi si ori ikanni Facebook rẹ lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan-an ọdun yii.

Aworan atẹjade naa to n la iye owo naa kalẹ lọkọọkan

Oríṣun àwòrán, screenshot

Alaye ti Họnọrebu Adelabu ṣe sinu atejade naa ni pe gbogbo ẹni to ba fẹ ṣe inawo bii igbeyawo ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ọrọ owo ori yii kan, awọn alakoso gbọngan ati ibudo ayẹyẹ si gbọdọ maa beere iwe asẹ lọwọ irufẹ awọn eeyan bẹẹ ki wọn to gba wọn laaye lọdọ wọn.

Iroyin mii ti o tun jade lẹyin eleyii ti wọn da orukọ Adelabu Tunde si ni pe awọn to ba fẹ ṣe inawo n'ipinlẹ Ọyọ yoo maa san laarin ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn si ẹgbẹrun marundinlogoji Naira fun ijọba ki wọn to le ṣe ayẹyẹ wọn.

'Wọn fẹ fi ta ẹrẹ si aṣọ ala ijọba Ṣeyi Makinde ni'

Awuyewuye to rọ mọ ikede yii lo mu ki BBC Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ naa, ki a le fi idi otitọ mulẹ.

Akowẹ iroyin fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Sulaimon Olanrewaju lo kọkọ sọ fun akọroyin wa wi pe irọ to jina si otitọ ni ọrọ naa, ko to di pe Kọmisana fun eto iroyin n'ipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Dọtun Oyelade naa fi atẹjade ranṣẹ si awọn oniroyin lori ọrọ naa.

Alaye ti Oyelade ṣe ni pe iroyin ofege ni ọrọ to n ja rainrain pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ maa gba owo ori lori awọn ipejọpọ bii eto isinku, isọmọlorukọ ati igbeyawo.

O tẹsiwaju wi pe ẹni to gbe iru iroyin naa jade fẹ ṣi awọn eeyan ilu lọna, wọn si tun fẹ ta ẹrẹ si aṣọ ala ijọba Ṣeyi Makinde.

Kọmiṣana naa ṣe alaye wi pe aṣẹ ijọba to niiṣe pẹlu owo ori tabi awọn ojuṣe mii gbọdọ ni nọmba idanimọ, alaga ajọ to n pa owo wọle labẹnu fun ijọba ipinlẹ Ọyọ si gbọdọ buwọlu aṣẹ naa, bẹẹ sini adirẹsi ajọ naa gbọdọ wa lori ẹ.

O ni gbogbo awọn nnkan ti oun ka silẹ yii ni ko si ninu iroyin ofege naa.

Oyelade rọ awọn eeyan ilu lati kọ eti ogbọin si ayederu iroyin naa nitori pe o jẹ ọkan lara awọn ọgbọn alumọkọrọi ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako n da saaju eto idibo ọdun 2027 lati tabuku awọn aṣeyọri ti ijọba Makinde lati ọdun meje sẹyin.