Tírélà tó kó símẹ́ntì ṣekú pa aláboyún àtàwọn méje míì l'Akungba ní ìpínlẹ̀ Ondo

Tirela to ko simẹnti to ṣubu niluu Akungba Akoko

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ti eeyan ba jori ahun yoo bomi loju niluu Akungba Akoko nipinlẹ Ọndo, lẹyin ti ọkọ tirela to ko simenti ṣeku pa eniyan mẹjọ ti alaboyun kan wa ninu wọn ni irọlẹ ana Ọjọru.

Ọkọ ajagbe ọhun ni a gbọ pe o sọ ijanu rẹ nu, to si kọlu ọpọlọpọ ile itaja ni opopona Marose Owo-Akungba si Ikare, to si pa ọpọlọpọ eniyan niluu Akungba.

Awọn olugbe ilu naa sọ pe ọkọ ileeṣẹ simẹnti Dangote ti ẹru wa ninu rẹ ni tirela naa.

Ọkan lara awọn osojumikoro to wa nibi iṣẹlẹ naa sọ fun BBC Yoruba pe ọkọ naa n bọ lati oke, o si kọlu irin kan ko to morile ibi ti ile itaja wa.

Osojumikoro naa fikun ọrọ rẹ pe ọmọ inu alaboyun to wa lara awọn eniyan to ku nibi iṣẹlẹ ọhun jade lati inu obinrin naa nibi ijamba ọhun.

A gbọ pe awọn esọ eleto abo oju popo tete di ibi iṣẹlẹ naa, wọn si ko oku awọn to ku nibẹ kuro loju popo.

Ki ni ẹṣọ oju popo sọ lori ijamba ọkọ naa?

Ẹwẹ, ọga agba ajọ esọ oju popo nipinlẹ Ondo, Samuel Ibitoye salaye pe kii se ọkọ Dangote lo fa Ijamba naa.

O ni ọkọ tó fà ijamba naa, kò ko simenti rara sugbọn yeepẹ olukta ni ọkọ naa ko eyi to tako awọn iroyin to n jẹyọ kaakiri.

Ogbeni Ibitoye sọ pe ọkọ naa kọlu irin ti wọn se lati dena awọn ọkọ nla lati ma le gba ọna naa, eyi ti wọn se siwaju fasiti Adekunle Ajasin.

Ọga agba ẹṣọ oju popo ni eyi lo mu ki ọkọ naa sọ ijanu rẹ nu, to si yọri si ijamba ọkọ naa.

O fidi rẹ mulẹ pe o kere tan eniyan mẹjọ lo jẹ Ọlọrun nipe ninu ijamba naa, eyi ti okunrin marun, obinrin meji ati odomokunrin kan wa ninu wọn.

Oga agba ajọ naa wa rọ awọn awakọ lati ri daju pe gbogbo ẹya ara ọkọ wọn n ṣiṣẹ dara dára ki wọn to gbe e soju popo.

Bakan naa ni o si se ikilọ pe kawọn awakọ maa rii pe wọn bọwọ fun gbogbo ofin irina.

Awọn olugbe Akungba ni eeyan to ku ninu ijamba ọhun ju mẹjọ lọ

Ọpọ olugbe ilu Akungba lo yari wi pe awọn eeyan to ku ninu ijamba ọkọ tirela to ko simẹnti niluu ju mẹjọ ti ajọ ẹṣọ oju popo kede lọ.

Ọkan lara awọn olugbe ilu naa, God'spower Olorunsaanu, sọ pe irọ to jina si ootọ ni ohun ti ajọ FRSC sọ, o sọ pe awọn eniyan ti ohun mọ to ku ju mẹjọ lọ.

O salaye pe awọn kan si wa labẹ ọkọ naa ti wọn ko tii gbe wọn jade titi di asiko yii.

Olorunsaanu wa rọ awọn to n doola ẹmi lati ji giri si isẹ wọn lati ri daju pe wọn yọ awọn to si ha sabẹ ọkọ tirela naa k