Kí ló dé tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gan Omoyele Sowore lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gba bẹ́ẹ̀lì rẹ̀ pẹ̀lú àbúrò Nnamdi Kanu?

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/Facebook
Ileeṣẹ ọlọpaa tun tu nawọ gan ajafẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore lẹyin ti ile ẹjọ gba baali re niluu Abuja.
Ọjọbọ, Ọjọ kẹtadinlogun ni ile ẹjọ gba baali Soworo lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa kọkọ nawọ gan an lasiko iwọde fun itusilẹ Nnamdi Kanu to waye ni Ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2025.
Ile ẹjọ gba baali rẹ pẹlu oniduro meji ati owo toto 500,000 naira ($342). Ile ẹjọ tun ni awọn oniduro rẹ gbọdọ kaadi idanimọ ati lẹta pe wọn san owo ori fun ọdun mẹta.
Awọn yooku ti ile ẹjọ tun gba baali wọn ni awọn mẹtala ni ileeṣẹ ọlọpaa mu lasiko iwọde fun ominira Nnamdi Kanu, to fi mọ aburo Kanu ati agbẹjọro rẹ.
Ẹwẹ, kete ti ile ẹjọ gba baali Sowore ni ileeṣẹ ọlọpaa tun nawọ gan.
Agbẹjọrọ Nnaemeka Ejiofor fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
"Wọn gbe Sowore lọ ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ ni agbala ile ẹjọ."
Bawo ni wọn se nawọ gan Sowore tẹlẹ?
Gẹgẹ bii a ṣe ri gbọ, awọn ọlọpaa ti w ani ayika ile ẹjọ giga ilu Abuja lati nawọ gan Sowore lẹyin idajọ ile ẹjọ to gba pe o pe fun iwọde itusilẹ olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin fidi rẹ mulẹ pe Sowore wa ni ahamọ wọn, ti awọn yoo si tun gbe lọ si ile ẹjọ laipẹ.
O ṣalaye pe idi ti awọn fi nawọ gan Sowore ni pe gbogbo eeyan mẹtala ti wọn mu pe tapa si ofin pe wọn ko gbọ se iwọde de awọn agbegbe kan ti ileẹjọ fofin, Sowore lo lewaju wọn lọ si ilẹ.
"Ko ni da pe ki a gbe awọn kan lọ si ile ẹjọ, ka wa fi eeyan lo lewaju wọn silẹ, to gbe wọn lọ si awọn agbegbe ti ile ẹjọ ni wọn kogbọde de. Idi ree ti a fi gbe Sowore lati ri pe idajọ ododo waye, a mu Sowoe lonni, ti ko si ni lo wakati mẹrinlelogun pẹlu wa, lọwọ ti a ṣe iṣẹ wa tan, a morile lọ ile ẹjọ, Hundeyin ṣalaye.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Ọrọ di boo lọ ya n mi nigba tawọn ẹṣọ eleto abo yin tajutaju sawọn oluwode to n pe fun itusilẹ ajijagbara fun ominira orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu, l'Abuja laaarọ ọjọ Aje.
Ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, lo ṣaaju awọn oluwọde naa bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ikilọ sita ṣaaju ifẹhonuhan ọhun.
''Ẹ fi Nnamdi Kanu silẹ,'' ''ẹtọ wa ni lati ṣe ifẹhonuhan,'' ''ẹ ma yin tajutaju si wa,'' lawọn oluwọde naa n sọ kawọn ọlọpaa to yin tajutaju lati tu wọn ka.
Bawọn ọlọpaa ṣe yin tajutaju ọhun lawọn oluwọde kan n sọ pe ''tajutaju ko le da wa duro'' bi wọn ti n salọ.
Iwọde #FreeNnamdiKanuNow bẹrẹ lẹgbẹẹ ile itura Transcorp Hilton, o si ran lọ de awọn agbegbe mii niluu Abuja.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2











