Iléẹjọ́ pàṣẹ káwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí Tik-Tok méjì ṣe ìgbéyàwò, ó ní 'wọ́n ń dínjú' sí ara wọn lórí afẹ́fẹ́

Ashiru Idris Maiwushirya ati Basira Ƴargudaliya

Oríṣun àwòrán, FB/Maiwushirya

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ agbofinro Hisba nipinlẹ Kano ni awọn ti bẹrẹ igbaradi igbeyawo gbajumọ osere ori ayelujara Tiktok nipinlẹ naa, Ashiru Idris, ẹni ti ọpọ mọ si Maiwushirya ati Basira, ti wọn n pe ni Arguda, lẹyin idajọ ile ẹjọ.

Lọjọ Aje ni ile ẹjọ Magistrate niluu Kano paṣẹ fun Hisbah pe ki wọn seto igbeyawo laarin awọn ọdọ meji naa, lẹyin ti wọn gbe fidio igbeyawo awọn mejeeji sori ayelujara, ti wọn fi ṣe awada.

Idajọ yii waye lẹyin ti Hisbah wọ awọn ọdọ meji naa lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn be fidio to lodi si ofin si ori ayelujara.

Adajọ Halima Wali ni pe ti ojulowo igbeyawo ko ba waye laarin awọn ọdọ mejeeji ni asiko ti ile ẹjọ ni ko waye, o tumọ si pe wọn ti tapa si ofin.

Ninu ọrọ to fi ranṣe si ileeṣẹ iroyin BBC, igbakeji alaga Hisbah nipinlẹ Kano, Aminudeen Mujahideen, ni Hisbah tẹwọgba idajọ ile ẹjọ, ti wọn si ti bẹrẹ gbaradi fun igbeyawo naa.

"Maiwushirya fi ifẹ han si arabinrin Basira, ti Basira naa si fihan pe oun naa fẹ fi ọkunrin ṣe ade ori, ile ẹjọ si ti se amin si ibeere wọn," Mujahideen sọ.

Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti awọn alaṣẹ ijọb Kano yoo gbe igbese tako ohun ti awọn ọdọ n ṣe lori ayelujara, paapa ori opo Tiktok.

Ile ẹjọ kankan ko fi tipatipa sọ pe ki eeyan meji fẹ ara wọn- Ajọ NBA

Ajọ NBA sọrọ lori idajọ ile ẹjọ Margistrate ilu Kano to paṣẹ pe ki ilumọka ori ayelujara Tiktok meji, Idris Mai Wushirya ati Basira Yar Guda, fẹ ara wọn gẹgẹ bii ọkọ ati iyawo laarin ọgọta ọjọ lẹyin ti wọn gbe fọnran igbeyawo wọn sori ayelujara.

NBA, ninu atẹjade ti aarẹ ẹgbẹ naa, Mazi Afam Osigwe, SAN fi sita fun awọn akọroyin ni ile ẹjọ kankan lorilẹede Naijiria ko ni aṣẹ lati gbe idajọ naa kalẹ pe ki eeyan meji fẹ ara wọn tabi fi tipatipa sọ pe wọn gbọdọ se igbeyawo

"Eyi ko si ninu ilana ofin, ti ile ẹjọ kankan ko si lẹtọ lati gbe irufẹ idajọ naa kalẹ.

"Igbeyawo gbọdọ jẹ ohun ti igun mejeeji fọwọ si, ẹ ko le ni dandan pe wọn gbọdọ se iyawo gẹgẹ ijiya fun ẹsun ti wọn."

NBA wa n pe fun atunṣe idajọ, Onidajọ Halima Wali, to si tun kesi awọn ti ọrọ kan ni ẹka idajọ lati gbe igbesẹ lori ki idajọ ma le fi ẹṣẹ mulẹ.