Òfin tuntun tí CBN gbé kalẹ̀ nípa àìrówó gbà lẹ́yìn tí o lo ẹ̀rọ ATM, àtàwọn ìlànà míràn tó kàn ọ́

Obinrin to wọ aṣọ pupa to n lo ẹrọ ATM

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ tọ n ṣe itaniji faraalu ni Naijiria, National Orientation Agency, NOA, ti kede awọn alakalẹ tuntun ti banki apapọ Naijiria, CBN ṣe nipa bi awọn ẹrọ ATM yoo ṣe maa ṣiṣẹ.

Gegẹ bo ṣe sọ, aṣẹ CBN tuntun yii bori gbogbo awọn aṣẹ ti banki naa ti pa ṣaaju asiko yii lori bi ATM yoo ṣe maa ṣiṣẹ ni Naijiria ati bi araalu yoo ṣe maa lo o.

Lara awọn alakalẹ naa ni iye akoko ti banki kọọkan gbọdọ da owo araalu ti ẹrọ ATM wọn ba gbemi pada, atawọn nnkan mii.

Ọrọ naa tun kan iye ẹrọ ATM ti banki gbọdọ ni, eto abo ẹrọ ATM, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iwọnyi ni awọn alakalẹ tuntun ọhun gẹgẹ bii NOA ṣe fi sita loju opo X rẹ.

Iye ẹrọ ATM ti banki gbọdọ ni

Àwọn alakalẹ tuntun nipa ti CBN gbe jade

Oríṣun àwòrán, NOA

CBN ti paṣẹ fun awọn banki lati ni o kere tan, ẹrọ ATM kan fun kaadi ATM ẹgbẹrun marun un ti wọn ba pin, wọn si gbọdọ ṣe eyii laarin ọdun mẹta pere.

Awọn banki gbọdọ gbe ẹrọ ATM si ibi ti ko ni si ewu fun araalu ati ibi ti aabo yoo ti wa fun owo wọn.

CBN ni ẹrọ ATM ko gbọdọ wa niwaju ile kankan ayafi ti wọn ba de ẹrọn ATM naa mọlẹ sibẹ.

Banki kankan ko gbọdọ lọ ri ẹrọ ATM mọ ibikankan lai kọkọ gba aṣẹ lọwọ CBN.

Gbogbo igba ti ATM gba gbe owo onibara jẹ

Ti onibara ba lo ATM to jẹ ti banki rẹ, banki naa gbọdọ da owo onibara ọhun pada lẹsẹkẹsẹ ti wọn ja owo rẹ amọ ti ẹrọ ATM ko si pọ owo naa jade.

Ti banki ko ba le da owo naa pada lẹsẹkẹ nitori oju ọjọ ti ko ṣe dede, wọn gbọdọ da owo ọhun pada laarin wakati mẹrinlelogun pere.

Ti iṣẹlẹ naa ba waye ni ATM ti kii ṣe ti banki onibara, banki ọhun gbọdọ da owo naa pada o pẹ ju, laarin wakati mejidinlaadọta. Amọ ṣa wọn gbọdọ gbiyanju lati maa da owo onibara ti ẹrọ wọn ba gbe jẹ pada lẹsẹkẹsẹ.

Imọ ẹrọ igbalode

Gbogbo ẹrọ ATM lo gbọdọ ni kamẹra ti yoo maa ka gbogbo ohun ti eeyan ba n ṣe niwaju rẹ silẹ, eyii kan fifi owo ranṣe, gbigba owo ati bẹẹ lọ.

Ẹrọ naa gbọdọ maa ya aworan ati fidio ẹni to ba n lo ATM.

Awọn banki gbọdọ maa paarọ awọn kọkọrọ ẹrọ ATM wọn lọdọdun, wọn ko si gbọdọ lo kọkọrọ kan ṣoṣo fun oniruru ẹrọ ATM.

Gbogbo ẹrọ ATM lo tun gbọdọ ni imọ ẹrọ 'anti-skimming devices' ti yoo maa dena jibiti ṣiṣe lori ẹrọ ọhun.

Titẹle ofin CBN

NOA sọ pe gbogbo igba ni CBN yoo maa ṣayẹwo awọn ẹrọ ATM naa lati ri daju pe awọn banki n tẹle aṣẹ to pa.

O fi kun pe awọn banki gbọdọ maa jabọ fun CBN loṣoṣu nipa bi iṣẹ ṣe n lọ lori ẹrọ ATM wọn ko to di ọjọ karun un oṣoṣu.

Eyikeyi banki to ba tapa si aṣẹ tuntun yii yoo foju wina ofin CBN.