Ààrẹ Tinubu pààrọ̀ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò, kéde àwọn tuntun

Aworan Aarẹ Bola Tinubu ati Ọga tuntun fun ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria, Olufemi Oluyede

Oríṣun àwòrán, HQ Nigeria Army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti kede awọn atunṣe si ipo awọn olori ẹṣọ alabo ninu wọn igbiyanju lati popin si kudiẹkudiẹ eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Tinubu, ninu atẹjade ti olubadamọran aarẹ, Sunday Dare fi sita fun awọn akọroyin, kede Ọgagun Olufemi Oluyede gẹgẹ ẹni ti yoo rọpo Ọgagun Christopher Musa gẹgẹ bii olori ileeṣẹ ọmọ ologun.

Olori ikọ ologun ori ilẹ bayii ni Ọgagun W. Shaibu. Olori ikọ ologun ori ofurufu, Marshall S.K Aneke, olori ikọ ologun ori si jẹ, Rear Admiral I. Abbas. Ọgagun E.A.P Undiendeye di si di ipo rẹ mu gẹgẹ bii olori ologun ọtẹlẹmuyẹ.

Aarẹ, olori fun gbogbo ikọ ọmọ ologun, dupẹ lọwọ olori ologun to gba wọle ati awọn yooku rẹ fun ipa ti wọn ko ninu pipese aabo fun orilẹede Naijiria.

Bakan naa, aarẹ tun rọ awọn olori tuntun pe ki wọn ri daju pe wọn nifẹ aaralu lọkan, ki wọn si jẹ ki aabo ilu jẹ wọn logun pupọ.

Lẹsẹkẹsẹ ni iṣẹ bẹrẹ fun awọn olori ologun tuntun naa.

Ṣaaju ni Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kede iyansipo adele ọga agba ileeṣẹ ologun Naijiria.

Ni Ọdun to kọja ni aarẹ kede Major General Olufemi Olatubosun Oluyede, gẹgẹ bi ẹni ti yoo dele, lẹyin ipapoda Ọgagun Taoreed Lagbaja.

Taa ni Olufemi Oluyede ti Tinubu kede?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni Major General Olufemi Oluyede.

O ti fi igba kan jẹ olori ikọ ologun

Elite Infantry Corps ti ileeṣẹ ologun to wa ni Jaji, Kaduna.

Oluyede gba igbega sipo 2nd lieutenant lọdun 1992.

O de ipo Major-General ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020.

O ti ṣiṣẹ gẹgẹ Platoon Commander ati adjutant ni ikọ ologun 65 Battalion, company commander ni 177 Guards Battalion, Staff Officer Guards Brigade, Commandant ni ile-ẹkọ Amphibious Training School.

Ọga agba ologun ti kopa ninu awọn ogun jija bi Economic Community of West African States Monitoring Group (ECOMOG) Mission ni Liberia, Operation HARMONY IV ni Bakassi, ati Operation HADIN KAI ni ila-oorun Ariwa Naijiria gẹgẹ bi Balogun command 27 Task Force Brigade.

Oriṣiriṣi ami ẹyẹ ni Oluyede ti gba, fun iṣẹ takuntakun to n ṣe gẹgẹ bi ologun.

Lara awọn ami ẹyẹ naa ni Corps Medal of Honour, Grand Service Star, Passing Staff Course, Field Command Medal, Field Command Medal of Honour, ati Field Training Medal.

Ṣaaju iyansipo yii, Oluyede ti gba ami ẹyẹ Chief of Army Staff Commendation Award.