"Àwọn èèyàn kan ká mi mọ́lé, wọ́n gé ọwọ́ mi méjèjì fún oògùn nítorí mo jẹ́ àfín"

- Author, Alfred Lasteck
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Northern Tanzania
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Gbogbo igba ti eto idibo ba n waye ni Tanzania ni inu Mariam Staford maa n bajẹ.
Fun ọpọ eeyan, akoko idibo ni wọn maa n kọ orin, ilu pẹlu oniruru ipolongo, amọ fun awọn to jẹ afin, akoko ibẹrubojo lo maa n jẹ fun wọn.
O sọ fun BBC pe "ohun akọkọ ni ibẹru."
"Mo mọ pe wọn maa n pa awọn eeyan ti wọn jẹ afin lasiko eto idibo… idi ree ti mi o ki n kopa ninu ipolongo ibo.
Nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan lo jẹ afin ni Tanzania, eyii to jẹ ohun to maa n din mẹlanin to maa n fun oju, ara ati irun ni awọ ku.
Awọn ọrọ ti awọn eeyan maa n sọ mu ki ọrọ awọn afin naa tubọ buru siwaju si bii awọn to gbagbọ pe eeyan le fi ẹya ara afin ṣe oogun owo.
Awọn ajafẹtọọmọniyan sọ pe asiko ti eto idibo ba n sunmọle ni irufẹ igbagbọọ bẹẹ maa n gbilẹ si.
Fun Mariam, o mọ bi ọrọ naa ṣe buru to gẹgẹ bii ẹni to jẹ afin.
Lọdun 2008 to jẹ ọkan lara awọn ọdun to buru julọ fun awọn afin ni Tanzania, ọdun naa ni awọn gende ọkunrin ti wọn ko ada lọwọ ya bo yara rẹ niluu Kagera.
O ṣalaye fun wa pe "ọganjọ oru ni wọn wa, wọn fi ada ge ọwọ mi ọtun, wọn tun ge ọwọ mi osi, wọn si ko awọn ọwọ naa lọ.
"Lọjọ keji ni wọn gbe mi lọ sile iwosan lasiko ti mo daku rọgbọndan, nigba ti dokita yoo ri mi, o ni eleyii ti ku, ẹ gbe lọ sile ki ẹ lọ sin oku rẹ."
Lẹyinorẹyin, Mariam moribọ, oyun ti wa lara rẹ ṣaaju ikọlu naa ṣugbọn ọmọ inu rẹ ko ru iṣelẹ naa la.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Yatọ si pe o padanu ọwọ rẹ mejeji, iṣẹlẹ naa mu ko fi ilu Kagera silẹ.
Ilu naa jẹ ọkan gboogi lara awọn ilu ti iṣekupa awọn afin ti pọju julọ ni Tanzania.
Lẹyin to fi ilu naa silẹ lo lọ si agbegbe Kilimanjaro nibi ti ẹgbẹ ajafẹtọọ awọn afin, Under the Same Sun, wa.
Awọn eeyan naa lo kọ ile abẹrẹwọ kan fun nibẹ ti wọn si kọ bi yoo ṣe maa hun aṣọ.
Ọdun mẹtadinlogun lẹyin iṣẹlẹ ọhun, ko tii gbagbe ohun ti oju rẹ ri lọjọ naa.
O ni "titi di asiko yii, mo ṣi maa n fi alẹ ọjọ naa la ala, ti mo ba ti ji, mo maa n gbiyanu lati Iati fi ọwọ kan ọwọ naa nitori mo ti gbagbe pe wọn ti ge lọ."
Ohun to ṣẹlẹ si Maria yii jẹ ọkan lara ohun to n ṣẹlẹ si ọpọ awọn afin bii tirẹ ti wọn n fi ẹya ara wọn joogun.
Ajọ Under The Same Sun ni eeyan bii 211 ni wọn ti ge ẹya ara wọn lọ bẹẹ lati ọdun 2008 titi di asiko yii.
Ninu awọn ikọlu wọnyin, afin 79 lo padanu ẹmi wọn, ọgọrun eeyan mii moribọ amọ wọn padanu ẹya ara wọn sọwọ awọn kọlọrọsi ẹda naa.
Titi di asiko yii, awọn afin kan ti di awati nigba ti wọn ri iboji 27 ti ẹya ara awọn afin to wa nibẹ ti poora.
Lọdun 2008 nikan ṣoṣo, afin marundinlogoji ni wọn ṣekupa amọ ọpọ iku awọn mii ni iroyin ko gbe.
Wayi o, awọn araalu kan ti bẹrẹ eto itaniji lori ikọlu awọn afin ọhun.
Kaakiri agbaye lawọn alẹnulọrọ ti n bu ẹnu atẹ lu awọn ifẹmiṣofo naa, eyii to mu ki ijọba bẹrẹ si n fi panpẹ ofin mu awọn afurasi olukọlu naa.
Tanzania ti bẹrẹ iwadii to peye lori ọrọ oogun owo ṣiṣe paapaa bo ṣe kan awọn afin, bẹẹ lo ṣe ofin ti yoo fiya jẹ ẹnikẹni to ba ṣe idẹyẹsi awọn afin.
Wọn ti mọ awọn ere kan lati lati ṣe apọnle awọn ti ọrọ naa pa lara, lara wọn ni Mariam wa ati Mariamu Emmanuel, to jẹ afin ti wọn gbẹmi rẹ lẹni ọdun marun un lọdun 2008.
I was eight years old, and saw her legs, hands and tongue removed by the attackers"
Nigba ti aburo rẹ, Manyashi Emmannuel , n sọrọ, o ni "ọmọ ọdun mẹjọ pere ni mi lasiko naa, mo si ri bi wọn ṣe gẹ ahọn, ọwọ ati ẹsẹ rẹ lọ lọjọ naa.
"Lati igba naa ni ẹru ti n maa n ba mi lasiko ti eto idibo ba sumọ etile.
Ninu oṣu Kẹfa ọdun yii, wọn ṣi kọlu afin kan niluu Simuyu amọ ko ko frapa pupọ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ n sọ pe ijọba ṣi ni ọpọ iṣẹ lati ṣe, awọn aṣeyọri kan ti n waye.
Lara awọn ohun ti wọn n ṣe ni itaniji lawọn ile ẹkọ atawọn ori ẹrọ asọrọmagbesi.
Awọn araalu ti n ni woye pe awọn afin kii ṣe abami, bẹẹ ni wọn kii ṣe ohun elo oogun owo.
Amọ ṣa, iku Asimwe Novath, ọmọ ọdun meji ti wọn ji gbe nile rẹ lagbegbe Kagera kẹyin n fihan pe ọpọ iṣẹ lo ṣi wa nilẹ lati ṣe.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ọkunrin meji lo fi tipatikuuku wọ ọmọ kekere naa kuro nile awọn obi rẹ lasiko ti oun ati iya rẹ n ṣere.
Ọjọ mẹtadinlogun lẹyin naa ni wọn ri oku rẹ ninu apo kan ti awọn ẹya ara rẹ mii ko si si nibẹ mọ.
Eeyan mẹsan an lo n jẹjọ lori ẹsun iku ọmọ naa bayii amọ ẹjọ ọhun ko tii pari.
Igbẹjọ iku ọmọ naa mu Maria ranti ọjọ ti wọn kọlu oun naa lọdun 2008 ti wọn si ge ọwọ rẹ mejeji lọ eyii to ni "iya ọmọ naa ko ni gbagbe lailai.
Lọwọ yii, o maa n lọra fun agbegbe ti ero ba pọ ju si, bẹẹ ni kii danikan kuro nile lai ni ẹni ti yoo wa pẹlu rẹ.
Pẹlu eto idibo ti yoo waye ni Tanzania yii, Mariam ni kaka ki oun jade lọ dibo, niṣe loun yoo joko jẹjẹ sinu ile oun ni Kilimanjaro.














