"Obìnrin díjà sílẹ̀ láàárín ọ̀rẹ́ méjì, Gafaru àti Tunde n'Ilorin, ni Gafaru bá bínú gún Tunde pa"

Oríṣun àwòrán, Rasheedat Kazeem
Iṣẹlẹ laabi kan ṣẹlẹ niluu Ilorin laarin ọsẹ yii lẹyin ti ''obinrin da ija silẹ'' laarin Gafaru ati Tunde Usman ti wọn jẹ ọrẹ, ti Gafaru Hammed si gun Tunde pa.
Iṣẹlẹ naa to sẹlẹ lagbegbe Ọja gbọrọ ni ilu Ilọrin ba ibẹru-bojo silẹ fawọn eeyan agbegbe naa.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, Balikis Yusuf, sọ pe ọrẹ ni Tunde ati Gafaru fun ọpọlọpọ ọdun.
Yusuf ṣalaye pe obinrin lo dija sile laarin awọn mejeeji lọjọ naa.
O tẹsiwaju pe Gafaru lo lọ ba Tunde ni agbegbe Ọja gbọrọ to si sọ fun un pe oun yoo mu un balẹ.
''Ṣadeedee ni Gafaru yọ ọbẹ si Tunde to si gun un ni igbaaya ti Tunde si ṣubu lulẹ ti ẹjẹ si bo o.''
Ọkan lara mọlebi oloogbe to ba BBC Yoruba sọrọ, Arabinrin Munji, sọ pe ibanujẹ nla ni iku Tunde jẹ fun ẹbi awọn.
O ni iyalẹnu ni iṣẹlẹ naa jẹ fun gbogbo eeyan tori ọrẹ lawọn mọ awọn mejeeji si tipẹ tipẹ.
Arabinrin Munji tun fidi rẹ mulẹ pe Gafaru ati ẹbi rẹ ti sa kuro nile bayii lẹyin iṣẹlẹ naa.
Akọwe agbegbe Soro 2, Ọja gbọrọ, Ọgbẹni Muhammad Abdulrahman, naa sọ pe loootọọ ni pe ọrẹ lawọn mejeeji.
Ọgbẹni Abdulrahman ni kete ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ tan lawọn ti fi to awọn ọlọpaa leti.
O tun fidi rẹ mulẹ pe wọn ti sin oku oloogbe naa si itẹ oku musulumi to wa ni ilu Ilọrin.

Ẹlomiran ti iṣẹlẹ ọhun tun ṣoju rẹ, Arabinrin Rashidat Kazeem, rọ ijọba lati fọwọ ofin mu Gafaru ni kiakia.
Ninu ọrọ tiẹ, alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ-Adeyemi Toun, sọ pe loootọọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Arabunrin Adeyemi fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ alapata ẹran ni Gafaru n ṣe ilu Ilorin.
Alukoro ajọ ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti ija bẹ silẹ laarin awọn mejeeji ni Gafaru gun Tunde ọrẹ rẹ lọbẹ lọrun.
Adeyemi Toun fi kun ọrọ rẹ pe kọmisona ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara Adekimi Ojo ti pasẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
O ni Kọmisọna ọlọpaa tun paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣawari Gafaru to ti salọ bayii, ko le foju bai le ẹjọ.















