Ìwà àjẹbánu rápálá wọ àjọ EFCC, òṣìṣẹ́ 27 gba ìwé ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, efcc
Ko din ni oṣiṣẹ mẹtadinlọgbọn (27) ti ajọ to n ri si iwa ajẹbanu lorilẹede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) sọ pe awọn le danu lẹnu iṣẹ ni 2024, fun ẹsun ajẹbanu.
Atẹjade ti EFCC fi sita lọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, ti Dele Oyewale to jẹ olori ẹka ipolongo ajọ naa fi sita lo fidi eyi mulẹ.
Yatọ si iwa ajẹbanu, atẹjade EFCC naa ṣalaye pe awọn aṣemaṣe kan tun wa ti awọn oṣiṣẹ ti wọn le lẹnu iṣẹ naa ṣe.
Lẹyin ti igbimọ oluwadii ti fidi ẹ mulẹ, pe awọn oṣiṣẹ ọhun jẹbi, ni Alaga EFCC, Ola Olukoyede, buwọ lu iyọniṣẹ wọn bi atẹjade naa ṣe sọ.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu naa fi kun un pe awọn ko ni i fọwọ bo aṣemaṣe yoowu mọlẹ.
Wọn tẹpẹlẹ mọ ọn pe ko si oṣiṣẹ to kọja ibawi.
EFCC sọ pe iṣẹ afọmọ ilu Naijiria ko mọ ni ẹka ijọba abi ọdọ araalu nikan, bi ko ṣe pe ile la ti n ko ẹṣọ rode.
"Ìwádìí ṣí ń lọ lọ́wọ́ nípa $400,000 tí wọ́n ní òṣìṣẹ́ EFCC kan gbà''

Oríṣun àwòrán, EFCC/X
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe tẹsiwaju, EFCC sọ pe iwadii n lọ lọwọ nipa oṣiṣẹ ajọ naa kan ti wọn ko ti i mọ orukọ rẹ, ẹni ti wọn lo gba $400,000 lọwọ olori ibi kan.
Ajọ naa ṣalaye pe otitọ ti EFCC duro fun ko yipada, ko si ẹnikan ti awọn yoo ti ori rẹ yii otitọ pada bo ti wu ki ẹni ọhun jẹ.
Bakan naa ni ajọ naa kilọ fun araalu, lati ṣọra fun awọn ti wọn n fi orukọ ọga agba ajọ naa, Ola Olukoyede, lu jibiti.
"EFCC n fi asiko yii kilọ fun araalu, lati ṣọra fun awọn ti wọn n beere owo lorukọ Ola Olukoyede.
''Aipẹ yii ni awọn meji ninu ikọ onijibiti kan foju bale ẹjọ l'Abuja, orukọ wọn ni Joshua Ojobo ati Aliyu Hashim.
"Wọn fẹsun kan wọn pe wọn beere miliọnu kan dọla lọwọ ọga ileeṣẹ ọlọkọ ofufrufu ilẹ wa nigba kan, Mohammed Bello-Kaka.
"Wọn sọ fun un pe awọn yoo lo owo naa lati jẹ ki Olukoyede ṣiju aanu wo o. Iwadii ofege ni wọn fẹẹ ṣe.
"Olukoyede ki i ṣe ẹni ti ẹnikẹni le fi owo tan, ẹni to n ko akoyawọ ninu gbogbo iṣe rẹ ni.''
Bẹẹ ni atẹjade EFCC yii ṣalaye.














