Ìdí tí Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat kò fí kúrò ní àtìmọ́lé ọgbà ẹ̀wọ̀n Agodi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun

Aworan olori Naomi ati Oriyomi Hamzat.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oriyomi hamzat/Naomi Silekunola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ keje oṣu kinni ọdun 2025, ireti ọpọ awọn ololufẹ olori tẹlẹ laafin Oodua nilu Ileifẹ, Naomi Shilẹkunọla ati gbajumọ sọrọsọrọ lori redio, Oriyọmi Hamzat ni pe bi-o-ti-wu-o-ri, wọn yoo lọ sile lọ gba atẹgun alaafia kuro lọwọ ahamọ ti wọn ti wa lati oṣu kejila ọdun to kọ.

Bakan naa lawọn mọlẹbi ọga ile ẹkọ girama Islamic High School ti oun pẹlu wa pẹlu wọn ni ahamọ pẹlu n fi ọkan gbadura ti wọn si n wo orere boya ẹni wọn n bọ wa sile.

Ohun to sọ awọn eeyan mẹta yii di ero atimọle ni ọgba ẹwọn to wa ni Agodi nilu Ibadan, bi ẹ ko ba gbagbe ni ọrọ eto ẹlẹyinjuaanu ti ajọ ẹlẹyinjuaanu kan ti Olori tẹlẹ Naomi Silẹkunọla gbe kalẹ pẹlu ifọwọsowọpọ Oriyọmi Hamzat ti wọn ti fẹ pin ẹgbẹrun marun un Naira fun awọn ọmọde.

Wọlu-kọlu to waye ni ibudo ti wọn ti fẹ ṣe eto naa lo fa iku awọn ọmọde marundinlogoji ti wọn si tibẹ de ahamọ ọlọpaa de ile ẹjọ Majisireeti ni iyaganku nibi ti adajọ ti ni ki wọn lọ fi wọn si inu ahamọ.

Ni ọjọ Iṣẹgun lawọn agbẹjọro fun awọn mẹtẹẹta pada siwaju ile ẹjọ lati bẹrẹ igbesẹ ati gba beeli awọn afurasi naa ki wọn to bẹrẹ ẹjọ gan an ti ijọba n pe wọn.

Amọṣa bi awọn ololufẹ wọn ṣe fẹ ko ri kọ lọrọ ri o. Gbogbo awọn to ti lọ duro si ọgba ẹwọn Agodi lati pade wọn ni ireti pe didun lọsan yoo so ni ile ẹjọ ni wọn fi ẹdun ọkan pada sile wọn.

Ki gan lo ṣẹlẹ ni ile ẹjọ ?

Lọjọ naa ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ ni wọn gbe ẹjọ lọ. Ijọba ipinlẹ Ọyọ̀ ni tirẹ n rọ ile ẹjọ lati maṣe gba beeli Naomi, Oriyọmi ati Fasasi Abdullahi to jẹ ọga ile ẹkọ girama naa.

Amọṣa, awọn agbẹjọro fun olujẹjọ rọ ile ẹjọ fun beeli, ṣugbọn kọmiṣọna fun eto idajọ to tun jẹ amofin agba fun ipinlẹ Ọyọ, Abiọdun Aikọmọ tako ẹbẹ naa, o ni awọn olujẹjọ naa ko tii idi to daju mulẹ fun ati tu wọn silẹ.

O ni ahesọ ọrọ ti ko lẹsẹ nlẹ ni gbogbo atotonu awọn agbẹjọro fun olujẹjọ n wi.

Aworan olori Naomi ati Oriyomi Hamzat.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oriyomi hamzat/Naomi Silekunola

Ilana ti wọn fi fi awọn afurasi si ahamọ ṣe ajeji si ofin Naijiria – Awọn agbẹjọro Naomi, Oriyọmi

Ṣaaju ninu ọrọ rẹ awọn agbẹjọro fun olujẹjọ ni ọna ti wọn gba fi awọn afurasi naa si atimọle ọgba ẹwọn ko ba ofin mu rara, ti wọn si ni ile ẹjọ to paṣẹ ki wọn fi wọn si ahamọ ko lẹtọ lati ṣe bẹẹ labẹ ofin.

Wn fi kun un pe ilana ẹ fi pamọ ki ọrọ fi yanju, iyẹn "holding Charge' ti wọn fi gbe awọn eeyan naa si ahamọ lati fun awọn agbofinro ati ileeṣẹ eto idajọ lanfani lati ṣe aayan iwe ẹsun wọn ko boju mu labẹ ilana ofin iṣedajọ iwa ọdaran ni Naijiria iyẹn Administration of Criminal Justice Act.

Waheed Olajide to jẹ agbẹjọro fun Fasasi Abdullahi ọga agba ile ẹkọ girama Islamic High School ni ko ti si ẹsun kankan ti wọn ka si ọrun onibara oun.

Bakan naa lo ni ilera Fasasi "ti n mẹhẹ bi a ṣe n sọrọ yii o si nilo itọju to peye."

Musibau Adetunmbi (SAN) to jẹ agbẹjọro fun Naomi Silẹkunọla ati Adekunle Sobaloju (SAN) to n gbẹjọro fun Oriyọmi Hamzat ni fifi olori tẹlẹ naa ati gbajumọ ori redio naa si ahamọ ko ba ofin mu rara.

Wọn ni ilana ẹ fi pamọ na ti wọn fi gbe awọn afurasi yooku si ahamọ ṣe ajeji si iwe ofin idajọ ati pe iwa aibofinmu ni ijọba ipinlẹ Ọyọ hu nipa fifi awọn eeyan naa si ahamọ.

Ki ni Adajọ wa sọ?

Onidajọ K.B. Ọlawọyin to gbọ ẹjọ naa, gbọ gbogbo atotonu awọn igun mejeeji ki o to sun ijoko ile ẹjọ naa di ọjọ Aje ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun 2025 lati gbe idajọ kalẹ boya anfani beeli yoo wa fun awọn eeyan yii tabi ko ni si.

Ki lo kan bayii?

Bi ọrọ ṣe ri yii, ireti ko tii sọnu lori gbigba beeli Olori Naomi, Oriyọmi Hamzat ati ọga agba ile ẹkọ girama naa nitori pe ijoko ile ẹjọ naa ti yoo waye gan ni yoo sọ ibi ti ọna ọrọ yoo gba lori beeli naa.

Bi ile ẹjọ ba ti le yanju ọrọ lori boya ile ẹjọ ti wọn gbe ẹjọ naa lọ lẹtọ lati gbọ ẹyọ naa, oju opo yoo tubọ tọ lori ọrọ ẹbẹ fun beeli awọn eeyan mẹtẹẹta naa.

Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ Olorì Naomi, Oriyomi Hamzat àti àwọn yòókù ṣe lọ nílé ẹjọ́
Aworan olori Naomi ati Oriyomi Hamzat.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oriyomi hamzat/Naomi Silekunola

Ile-ẹjọ giga Ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Ring-Road niluu Ibadan, ti sun igbejọ lori gbigba beeli Oriyomi Hamzat, Olori Naomi Silekunola, ati ọga ile-ẹkọ Islamic High, Abdullahi Fasasi si iwaju di ọjọ kẹtala, osu Kinni, ọdun 2025.

Yara Ile ẹjọ kẹjọ ti adajọ Kamarudeen Olawoyin n dari lo sun igbejọ naa.

Ṣaaju ni ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku, ti fi awọn afurasi mẹta ọhun si ọgba ẹwọn Agodi, lẹyin ti ọmọde marundinlogoji ku nibi apejẹ opin ọdun ti Olori Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Silekunola, ṣe agbatẹru rẹ.

Ninu ọrọ rẹ Abiodun Aikiomo, aṣoju ijọba Ipinlẹ Oyo to tun jẹ agbejọrọ agba fun Ipinlẹ Oyo, ni gbogbo ẹjọ awọn ti wọn fẹsun kan ti wọn gbe wa si ile-ẹjọ ni aṣoju ijọba Ipinlẹ Oyo tako.

Nibi igbẹjọ naa, ni awọn agbẹjọro àwọn afurasi ti sọ pe, ile-ẹjọ Majisireeti to fi wọn si ẹwọn ko ni ẹtọ tabi aṣẹ lati ṣe bẹẹ.

Ṣugbọn ninu ọrọ ti ẹ, agbẹjọro Agba fun ipinlẹ Oyo sọ pe, ile-ẹjọ ni yoo sọ boya lootọ ni eyi tabi bẹẹkọọ.

Kinni eyi tumọ si?

Ibeere tuntun awọn agbẹjọro awọn olujẹjọ lo si faa ti adajọ fi sun igbẹjọ wọn si ọjọ mii.

Lori ọrọ wọn pe ile-ẹjọ Majisireeti to kọ́kọ́ gbọ ẹjọ wọn ko ni aṣẹ, eyi tumọ si pe gbogbo awọn afurasi ni yoo ṣi wa ni ẹwọn, nitori pe o di igba ti ile-ẹjọ ba sọ pato ibi ti wọn o ti maa jẹjọ, ki ijiroro to le waye lori gbigba beeli wọn.

Agbẹjọro fun Oriyomi Hamzat, Adekunle Shobaloju ninu ọrọ rẹ ni, idajọ lori gbigba beeli Oriyomi Hamzat yoo waye ni ọjọ kẹtala, oṣu Kinni ọdun yii.

Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn
Aworan olori Naomi ati Oriyomi Hamzat.

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ile ẹjọ sọ awọn mejeeji yii si ahamọ ọgba ẹwọn fun ẹjọ ti wọn n jẹ lẹyin ti ọmọde marundinlogoji ku nibi eto ti wọn wgbe kalẹ lati ṣe iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.

Awọn eeyan naa ku lasiko ti wọlukọlu fi waye nibi eto naa nigba ti awọn ọmọde n sa ipa lati wọ ibudo eto naa.

Oṣu kejila ọdun 2024 ni wọn kọkọ gbe awọn eeyan naa lọ si iwaju ile ẹjọ Majisireeti kan ni agbegbe Iyaganku ni ilu Ibadan nibi ti adajọ ti ni ki wọn gbe wọn ju si ahamọ ọgba ẹwọn titi di igba ti ẹka olupẹjọ nileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ọyọ yoo fi yanju ọrọ nipa igbẹjọ wọn..

Lana ni Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde, ti tenumo pe awọn to lọwọ ninu ijamba naa gbodo foju baa ile ẹjọ lati fọ ara wọn mọ ninu ẹsun náà.