Ẹkún ojojúmọ́ ni mò ń sun ní ìrètí ikú fún ọdún mẹ́rìnlá – Segun Olowookere tí wọ́n dájọ́ ikú fún lórí ẹ̀sùn jíjí adìyẹ
Segun ati Morakinyo Sunday ni iroyin sọ pe o fipa lọ ja ilẹkun ile ọlọpaa kan ti wọn pe ni Balogun Tope, ẹni to n ṣiṣẹ nileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Okuku.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2010 ni wọn lawọn mejeeji yii wọle Ọgbẹni Tope, ti wọn si ji awọn dukia rẹ ko lọ.
Lẹyin o rẹyin ni wọn sọ pe ọwọ tẹ Segun ati Sunday, ti wọn si fẹsun igbimọ papọ, idigunjale, ati ole jija kan wọn, ni ibamu pẹlu abala kẹfa, ipin keji ati abala kinni, ipin keji ninu iwa ofin iwa idigunjale ati ohun ija oloro lorileede Naijiria ti ọdun 2004, ati abala aadọrunlelọọdunrun, ipin kinni (Section 390(1)) ninu iwa ofin ọdaran tipinlẹ Osun lọdun 2002.
Igbimọ to fẹsun kan awọn mejeeji naa, ti Arabinrin Abiola Adewemimo lewaju wọn, ni wọn lo pe ẹlẹrii mẹfa ọtọọtọ to tako wọn, pẹlu oniruuru ẹri ti wọn ko silẹ.
Bawo lọrọ ṣe jẹ gan?

Oríṣun àwòrán, others
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Ṣẹgun Olowookere sọ pe iwaju ṣọọbu baba oun loun wa lọjọ naa ti oun fi ṣa dede gbọ iro ibọn ki o to di pe awọn ọlọpaa mu oun.
O ni igba ti oun de agọ ọlọpaa ni ilu Okuku ni awọn afurasi kan ti wọn ti kọkọ mu tẹlẹ sọ wi pe awọn mọ oun naa ati pe oun pẹlu ti maa n lọ ji adiyẹ lawọn ile ọsin adiyẹ kan lagbegbe naa.
A ko ṣe ọdun ayọ kankan ni gbogbo asiko ti ọmọ wa fi wa lọgba ẹwọn – Awọn obi Ṣẹgun
Ọgbẹni Ọlanrewaju Olowookere ati arabinrin Fọlashade Olowookere to jẹ baba ati iya Ṣẹgun Olowookere pẹlu ṣalaye fun BBC pe gbogbo ọdun ti ọmọ oun lo ni ọgba ẹwọn ni ireti idajọ iku rẹ lo jẹ ọdun ibanujẹ fun oun.
Arabinrin naa ṣalaye pe Ṣẹgun nikan ni ọmọ ti oun bi ati pe gbogbo ọna lawọn ti gba lati rii pe o jade, ki o to di wi pe gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke daa silẹ.






